![]() |
|||||||
Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 5: On consistency; honesty, openness, plain speaking, reliabilityO
“Ó fò sókè ó pẹ́ títí,” irọ́ ló ńpa.
Ó jọ gàtè, kò jọ gàtè, ó fẹsẹ̀ méjèèjì tiro rìn.
O kò pọ̀ ọ́, bẹ́ẹ̀ni o ò gbé e mì.
“Ó mọ́ mi lọ́wọ́” ní ńdi olè.
O mú oori lọ́wọ́ ọ̀tún, o mú kùùmọ̀ lọ́wọ́ òsì, o ní kí Orímáfọ̀ọ́ wá gba oúnjẹ.
Ó ńṣe apá kúlú-kúlú bí ẹni ká gbé e jó, ó sì ńṣẹnu hàmù-hàmù bí èyí tí yó gbèéni mì.
Ó pẹ́ títí ni “A-bẹnu-bí-ẹnu-ọ̀bọ”; ká ṣá sọ pé, “Ìwọ Lámọnrín, ọ̀bọ ni ọ́.”
Ó ta ọfà sókè, ó ṣí odó borí.
Obì-í bọ́ lọ́wọ́ alákẹdun ó ní òún fún ará ilẹ̀; bí kò fún ará ilẹ̀, yó sọ̀kalẹ̀ wá mú u?
Obìnrin abàlèmẹ́fà: àlè mẹ́fà ò mọ ara wọn.
Obìnrin-ín bímọ fúnni kò pé kó má pani; obìnrin ò bímọ fúnni kò pé kó má pani.
Obìnrin-ín pẹ́ lọ́jà ó fìgbójú wọlé.
Obìnrin-ín re ilé àlè, ó fi ilé ìyá ẹ̀ tan ọkọ jẹ.
Odídẹrẹ́ ẹyẹ òkun, àlùkò ẹyẹ ọ̀sà; bí a bá jẹun gbé, ká má jẹ̀ẹ́ùn gbé.
Òfìífìí là ńrí, a ò rí òkodoro; òkodoro ḿbọ̀, baba gba-n-gba.
Ògèdèm̀gbé irọ́ kì í dáni síyẹ̀wù; gba-n-gba ní ńdáni sí.
Ohun tí a ò fẹ́ kéèyàn ó mọ̀ là ńṣe lábẹ́lẹ̀.
Ojo díẹ̀, akin díẹ̀; ìyà ní ńkó jẹni.
Òjò ọ̀gànjọ́ ò pa ẹni rere; bí kò pa jalè-jalè a pa yíde-yíde.
Ojú gba-n-gba là ńta awọ gbà-ǹ-gbà.
Ojú kì í fẹ́nikù kó hu ibi.
Ojú lobìnrin-ín mọ̀.
Ojú lọ̀rọ̀-ọ́ wà.
Ojú olóbì la ti ńjèrè obì.
Ojú tó ti mọni rí kì í wípe òun ò mọni mọ́.
Òkété, báyìí nìwà ẹ; o báFá mulẹ̀ o daFá.
Òkété ní ọjọ́ gbogbo lòún mọ̀, òun ò mọ ọjọ́ mìíràn.
Òkóbó kì í bímọ sítòsí.
Olòfòófó ò gbẹ́gbàá; ibi ọpẹ́ ní ḿmọ.
Olóòótọ́ ìlú nìkà ìlú.
Olóòótọ́ kì í sùn sípò ìkà.
Òǹrorò lẹ̀gbọ́n òfófó.
“Orí jẹ́ kí mpé méjì” obìnrin ò dénú.
Òtítọ́ dọ́jà ó kùtà; owó lọ́wọ́ là ńra èké.
Òtítọ́ kì í kú ká fi irọ́ jọba.
Òtítọ́ kì í ṣìnà; irọ́ ní ńforí gbọgbẹ́.
Òtítọ́ korò; bí omi tooro nirọ́ rí.
Òtítọ́ lolórí ìwà.
Òtítọ́ ní ńtú ẹrù ìkà palẹ̀.
Owó lobìnrin-ín mọ̀.
|
|||||||
![]() |