Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 4: On perseverance, industry, resilience, self-confidence, self-reliance, resourcefulness, daring, fortitude, and invulnerability

E

Ebè kan ṣoṣo àkùrọ́ kúrò ní “Mo fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣíwọ́.”

Ebi ni yó kọ̀ọ́ wèrè lọ́gbọ́n.

Ebí ńpa ejò, ahún ńyan.

Ebi ò jẹ́ ká pa ọwọ́ mọ́; ebí ṣenú papala.

Èébú kì í so.

Èdì kì í mú ọjọ́ kó má là.

Eégún tí ńjẹ orí ẹṣin, orí àgbò ò lè kò ó láyà.

Èkó ilá gba ara ẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀bẹ.

Èminrin ńjẹni, kò tó ìyà.

Èpè ìbínú ò pa odì.

Èpè ìlasa kì í ja àgbọ̀nrín.

Èpò ìbúlẹ̀ kì í pa irẹ́.

Erín jẹ̀ jẹ̀ jẹ̀ kò fọwọ́ kọ́ aṣá; ẹfọ̀nọ́n jẹ̀ jẹ̀ jẹ̀ kò ki ẹsẹ̀ wọ pòòlò; ẹyẹ kékèké ńfò lókè wọn ò forí gbági.

Èṣì ò rọ́ba dádé; Ògúnṣọṣẹ́ ò róòrùn wẹ̀wù ẹ̀jẹ̀; òdòdó ò róòrùn pọ́n; ilé ọmọ lọmọ́ ti pọ́n wá.

Eṣinṣín ńpọntí; ekòló ńṣú ọ̀lẹ̀lẹ̀; kantí-kantí ní ká wá ǹkan dí agbè lẹ́nu kí ǹkankan má kòó sí i.

Eṣú jẹ oko tán eṣù lọ; eṣú lọ Wata, ilé-e rẹ̀.

Èèwọ̀ ni tọwọ̀; a kì í figi ọwọ̀ dáná.

Ewu iná kì í pa àwòdì.

Ewúrẹ́ ńṣọdún, àgùtán gbàlù sẹ́hìn, òbúkọ-ọ́ ní ká sin òun lọ sílé àna òun.

Ewúrẹ́ ò lè rí ewé ọdán òkè fi ṣe nǹkan.

Ewúro ò fi tojo korò.

Èèyàn ìbáà kúrú, ìbáà búrẹ́wà, gbèsè ò sí, ìtìjú ò sí.

.
PreviousContentsNext