Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 4: On perseverance, industry, resilience, self-confidence, self-reliance, resourcefulness, daring, fortitude, and invulnerability

Edot

Ẹbọ jíjẹ kì í pa igún.

Ẹgbẹ̀rún eèrà ò lè gbé ṣúgà; wọ́n ó kàn tò yí i ká lásán ni.

Ẹgbẹ̀rún ẹja ò lè dẹ́rù pa odò.

Ẹ̀hìn ológbò kì í balẹ̀.

Ẹjọ́ ẹlẹ́jọ́, lọ́yà ńrò ó, áḿbọ̀ǹtorí ẹjọ́ ara-a rẹ̀.

Ẹlẹ́mùn-ún ò mú eégún.

Ẹ̀lúlùú ní kàkà kí òun má dun ọbẹ̀, òun á rúnwọ rúnsẹ̀ sí i.

Ẹ̀lukú tí kò ní èlè lẹgbẹ́-ẹ rẹ̀ ńṣá pa.

Ẹní bá ńṣiṣẹ́ kì í ṣọ̀lẹ; bórí bá túnniṣe a kì í tẹ́ bọ̀rọ̀.

Ẹní bá ńjẹ òbúkọ tó gbójú, yó jẹ àgùtàn tó yọ̀wo.

Ẹní bá yẹ ọ̀nà Ìjẹ̀bú tì ni yó yẹ̀ ẹ́ tán.

Ẹní gbani láya ò ní kírú ẹni má rà.

Ẹní máa jẹun kunkun a tìlẹ̀kùn kunkun.

Ẹní máa rí àtisùn akàn á pẹ́ létí isà.

Ẹní máa jẹ oyin inú àpáta kìí wo ẹnu àáké.

Ẹní máa rí àtisùn-un pẹ́pẹ́yẹ á jẹ gbèsè àdín.

Ẹní yára lÒgún ńgbè.

Ẹni èèyàn ò kí kó yọ̀; ẹni Ọlọ́run ò kí kó ṣọ́ra.

Ẹni ọ̀lẹ́ pa-á re ọ̀run òṣì; ẹni iṣẹ́ pa-á re ọ̀run ẹ̀yẹ.

Ẹni tí ó gbin ọrún èbù tó pè é nígba, tó bá jẹ ọgọ́rùn-ún òtítọ́ tán, á wá jẹ ọgọ́rùn-ún irọ́.

Ẹni tí ó gbálẹ̀ ni ilẹ̀ ḿmọ́ fún.

Ẹni tí ó bá ní ìtara ló ní àtètèbá.

Ẹni tí eégún ńlé kó máa rọ́jú; bó ti ńrẹ ará ayé, bẹ́ẹ̀ ní ńrẹ ará ọ̀run.

Ẹni tí ó forí sọlẹ̀-ẹ́ gbìyànjú ikú.

Ẹni tí à ḿbọ́ ò mọ̀ pé ìyàn-án mú.

Ẹni tí ó fò sókè-é bẹ́ ijó lórí.

Ẹni tí iṣẹ́ ńpa-á yá ju ẹni tí ìṣẹ́ ńpa.

Ẹni tí ó bá pẹ́ lẹ́hìn ni à ńyọ́ omi ọbẹ̀ dè.

Ẹni tí ó pa mẹ́fà lógun Ọ̀la: wọ́n ní “Háà, hà, háà!” Ó ní kí wọ́n gbé ọpọ́n ayò wá, ó tún pa mẹ́fà; ó ní bí ojú kò tó tẹ̀gi, ojú kò tó tilé?

Ẹni tí ńgbẹ́lẹ̀ ní ńsìnkú; ẹni tí ńsunkún ariwo ló ńpa.

Ẹni tí ó bá wo ojú ìyàwó ní ńmọ̀ pé ìyàwó ńsunkún.

Ẹni tí ọ̀ṣọ́ bá wù kó ṣòwò; ẹni ajé yalé-e rẹ̀ ló gbọ́n.

Ẹni tí ó bá ńjẹ lábẹ́-ẹ Jẹ́gẹ́dẹ́ ní ńpè é nígi àràbà.

Ẹni tí ó bẹ Ìgè Àdùbí níṣẹ́, ara-a rẹ̀ ló bẹ̀; Ìgè Àdùbí ò níí jẹ́, bẹ́ẹ̀ni kò níí kọ̀.

Ẹni tí kíkí-i rẹ̀ ò yóni, àìkí-i rẹ̀ ò lè pani lébi.

Ẹnu iṣẹ́ ẹni ni a ti ḿmọ ẹni lọ́lẹ.

Ẹnu òfìfo kì í dún yànmù-yànmù.

Ẹnú dùn-ún ròfọ́; agada ọwọ́ dùn-ún ṣánko.

Ẹ̀rù kì í ba igbó, bẹ́ẹ̀ni kì í ba odò; ẹ̀rù kì í ba ọlọ lójú ata.

Ẹ̀rù kì í ba orí kó sá wọnú.

Ẹ̀rù ogun kì í ba jagun-jagun.

Ẹsẹ̀ kì í wúwo kí ẹlésẹ̀ má lè gbé e.

Ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀ ni ìgbín fi ńgbà gun igi.

Ẹṣin kì í dani kí á má tún gùn ún.

Ẹṣin kì í já kó já èkejì-i rẹ̀.

Ẹ̀tẹ́ bá ọ̀lẹ.

Ẹyẹ ò sọ fún ẹyẹ pé òkò ḿbọ̀.

.
PreviousContentsNext