![]() |
|||||||
Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 4: On perseverance, industry, resilience, self-confidence, self-reliance, resourcefulness, daring, fortitude, and invulnerabilityB
Bí a bá ńpa èpo oṣè, ṣe ní ḿmáaá sanra sí i.
Bí a kò bá jìyà tó kún agbọ̀n; a ò lè jẹ oore tó kún ahá.
Bí a kò bá ṣe bí ẹlẹ́dẹ̀ lọ́nà Ìkòròdú, a ò lè ṣe bí Adégbọrọ̀ lọ́jà ọba.
Bí ebí bá ńpa ọ̀lẹ, à jẹ́ kó kú.
Bí ẹkẹ́-ẹ tálákà ò tó lówùúrọ̀, á tó lálẹ́.
Bí ẹnìkan ò kíni “Kú-ù-jokòó,” kíkí Ọlọ́run-ún ju ti igba èèyàn lọ.
Bí ẹrú yó bàá jẹ ìfun, ibi ẹ̀dọ̀ ní-í tí ḿbẹ̀rẹ̀.
Bí ẹ̀yá bá dẹkùn, ẹran ní ńpajẹ.
Bí ìbí bá tẹ̀, bí ìbí bá wọ́, oníkálukú a máa ṣe baba nílé ara-a rẹ̀.
Bí ilẹ̀-ẹ́ bá mọ́, ojú orun lọ̀lẹ ńwà.
Bí iná kò bá tán láṣọ, ẹ̀jẹ̀ kì í tán léèékánná.
Bí ìṣẹ́ bá ńṣẹ́ ọ̀dọ́ láṣẹ̀ẹ́jù, kó lọ sígbó erin; bó bá pa erin ìṣẹ́-ẹ rẹ̀ a tán; bí erín bá pá a, ìṣẹ́-ẹ rẹ̀ a tán.
Bí iwájú ò bá ṣeé lọ sí, ẹ̀hìn a ṣeé padà sí.
Bí màlúù-ú tó màlúù, ọ̀pá kan ni Fúlàní fi ńdà wọ́n.
“Bí mo lè kú ma kú” lọmọkùrín fi ńlágbárá “Ng ò lè wáá kú” lọmọkùnrín fi ńlẹ.
Bí ó pẹ́ títí, akólòlò á pe baba.
Bí ó pẹ́ títí, àlejò á di onílé.
Bí ó ti wuni là ńṣe ìmàle ẹni; bó wu Lèmámù a fẹlẹ́dẹ̀ jẹ sààrì.
Bí Ògún ẹní bá dánilójú, à fi gbárí.
Bí ojú kò pọ́nni bí osùn, a kì í he ohun pupa bí idẹ.
Bí ojú owó ẹni ò yóni, ènì ò lè yóni.
Bí ojúmọ́ mọ́ lékèélékèé a yalé ẹlẹ́fun, agbe a yalé aláró, àlùkò a yalé olósùn.
Bí ọwọ́ kò sin ilẹ̀, tí kò sin ẹnu, ayo ní ńjẹ́.
Bí Ṣàǹgó bá ńpa àràbà, tó ńpa ìrókò, bíi tigi ńlá kọ́.
|
|||||||
![]() |