![]() |
|||||||
Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 4: On perseverance, industry, resilience, self-confidence, self-reliance, resourcefulness, daring, fortitude, and invulnerabilityA
A hán ìkokò lọ́wọ́ ọ̀tún, a hán ìkokò lẹ́sẹ̀ òsì; ó ku ẹni tí yó kò ó lójú.
A kì í dá ẹ̀rù okó ńlá ba arúgbó.
A kì í dùbúlẹ̀ ṣubú.
A kì í fi ojoojúmọ́ rí olè jà kó dà bí-i tọwọ́ ẹni.
A kì í fi ojú olójú ṣòwò ká jèrè.
A kì í fi ojúbọ́rọ́ gba ọmọ lọ́wọ́ èkùrọ́.
A kì í gbọ́ “gbì” ìràwé.
A kì í mọ ibi tí à ńlọ kí ọrùn ó wọ ẹni.
A kì í sọ pé ọjà-á nígbà; bó bá nígbà, kíníṣe tí wọ́n tún ńná a?
A kì í ṣe ọ̀jẹ̀ ṣe ojú tì mí; konko lojú alágbe.
A kì í ṣe ọ̀tẹ̀ eranko gán-ń-gán; bí a bá he ìgbín àdá là ńnà á.
A kì í walẹ̀ fún adìẹ jẹ.
À ńpa ẹ̀kukù, ẹ̀kukù ńrúwé; à ńyan nínú aṣẹro, aṣẹro ńdàgbà; à ńkébòsí Ògún, ara Ògún ńle.
À ńpòyì ká apá, apá ò ká apá; à ńpòyì ká oṣè, apá ò ká oṣè; à ńpòyì ká kànga, kò ṣé bínú kó sí.
“A ò mọ̀yí Ọlọ́run yó ṣe” kò jẹ́ ká bínú kú.
A pa ẹmọ́ lóko ilá, a jù ú sí ọ̀kẹ́ ìlasa; ilé ẹmọ́ lẹmọ́ lọ.
Abẹ́rẹ́ á lọ kí ọ̀nà okùn tó dí.
Abẹ̀wẹ̀ ńwá ọ̀tá fúnra ẹ̀.
Abiyamọ ọ̀tá àgàn; ẹní ńṣiṣẹ́ ọ̀tá ọ̀lẹ.
Aboyún bí, ìhá tù ú.
Àdán tó sùn sídìí ọsàn ò rí he, áḿbọ̀sì oódẹ tó ní òún jí dé.
Adékànḿbí ò du oyè; ó bèèrè ni.
Adùn ní ńgbẹ̀hìn ewúro.
Adùn-ún tán lára aṣọ ogóje; a nà án han ẹni méje; a bẹ̀ ẹ́ wò a rí iná méje; ó di ọjọ́ keje ó fàya.
A-fàkàrà-jẹ̀kọ́ ò mọ iyì ọbẹ̀.
Afẹ́fẹ́ kì í fẹ́ kí omi inú àgbọn dànù.
Àfẹjútoto ò mọ ọkùnrin.
Àfẹ́ká là ńfẹ́ iná.
Agẹmọ ò ṣé-é jẹ lẹ́nu.
Àgùdà ò jẹ lábẹ̀-ẹ Gẹ̀ẹ́sì.
Àgbà tí kò tó ọmọdé-é rán níṣẹ́ ní ńsọ pé kó bu omi wá ká jo mú.
Àgbàbọ́ ò di tẹni.
Àgbàbọ̀-ọ ṣòkòtò, bí kò fúnni lẹ́sẹ̀ a ṣoni; rẹ́mú-rẹ́mú ni ohun ẹni ḿbani mu.
Àgbàká lèéfí ńgba igbó.
Àgbàká lẹsẹ̀ ńgba ọ̀na.
Àgbaǹgbá ṣe bẹ́ẹ̀, ó làwo lórí san-san.
Àgbàrá kọ́ ni yó gbèé omi lọ.
Àgbàtán ni gẹ̀gẹ̀ńgba ọ̀fun.
Àgbẹ̀ gbóko róṣù.
Àgbinsínú legbin ńgbin; àkùnsínú lẹkùn ńkùn; hùn hùn hùn ẹlẹ́dẹ̀ inú ẹlẹ́dẹ̀ ní ńgbé.
Agbójúlógún fi ara-a rẹ̀ fóṣì ta.
Àgbólà ni tàgbọ̀nrín; ọjọ́ tí àgbọ̀nrín bá gbó ni ọjọ́ ikú-u rẹ̀ ńyẹ̀.
Àìdúró là ńpè níjó.
Àìtó ehín-ín ká ni à ńfọwọ́ bò ó.
Ajá ilé ò mọdẹ-ẹ́ ṣe.
Àjà kì í jìn mọ́ ológbò lẹ́sẹ̀.
Ajá tó máa rún ọkà á láyà; ológbò to máa jẹ àkèré á ki ojú bọ omi.
Ajá wéré-wéré ní ńpa ikún.
Ajá wo ẹyẹ láwòmọ́jú.
Ajé sọ ọmọ nù bí òkò.
Àjẹgbé nigún ńjẹbọ.
Ajìnfìn, má ta ojú ilé; ọ̀pọ̀lọ́ jìnfìn má ta ojú àtijáde.
A-jókò-ó-kunkun ò jẹ́ kí a-jókòó-jẹ́jẹ́ ó jókòo.
Àjùmọ̀bí ò kan ti àrùn;kí alápá mú apá-a rẹ̀ kó le.
A-ká-ìgbá-tà-á náwó ikú.
Àkànṣe lọfà ìmàdò; jagan oró ò ran èse.
Àkèekèé ní òún kúrò ní kòkòrò-o kí nìyí?
Àkèekèé rìn tapó-tapó.
Akíkanjú-kankan, ogun ní ńlọ;abùwàwà, ọjà ní ńná; àkànní òbúkọ, bó bá tòṣì a máa rí jẹ.
Àkótán ni gẹ̀gẹ̀ ńkó ọ̀fun.
Àkùkọ-ọ́ kọ, ọ̀lẹ-ẹ́ pòṣé.
Alágẹmọ-ọ́ ti bímọ-ọ rẹ̀ ná; àìmọ̀-ọ́jó kù sọ́wọ́-ọ rẹ̀.
Alágbàró ò yege; aláṣọ á gbà á bó dọ̀la.
Alákatam̀pò ojú ò lè ta ẹran pa.
Aláǹgbá tó já látorí ìrókò tí kò fẹsẹ̀ ṣẹ́, ó ní bẹ́nìkan ò yìn un òun ó yinra òun.
Alára ní ńgbára-á ga;bádíẹ́ bá máa wọ̀ọ̀dẹ̀ a bẹ̀rẹ̀.
A-lèjà-má-lè-jà-pẹ́, ẹlẹgbẹ́ ojo.
Àlejò orí ni kókó.
Apá lará; ìgbọ̀nwọ́ niyèkan.
Àpáàdì-í gbóko kò rà.
Àpagbé lOrò ńpagi.
Apárí ní ńfojú di abẹ.
Apẹ́ẹ́jẹ kì í jẹ ìbàjẹ́.
Àpọntán kò wí pé kí odò má sun.
Ara kì í wúwo kí alára má lè gbe.
Ara-à mí gba òtútù, ó gba ọ̀nini.
Àràbà ńlá fojú di àáké.
Ààrẹ àgòrò tó bá gbójú, tòun tolúwa rẹ̀ lẹgbẹ́ra.
Àríṣe làríkà.
Ariwo àjìjà ní ńdọ́run.
Àro-ó pẹ́ lóko, kò tún mọ ìlù-ú lù.
Asúrétete ní ńwojú ọjọ́.
Àṣá ò gbádìẹ níkọ̀kọ̀; gbangba làṣá ńgbádìẹ.
Àṣá ò lè balẹ̀ kó gbéwúrẹ́.
Àṣá wo ahun títí; àwòdí wo ahun títí; idì baba àṣá, kí ló lè fi ahun ṣe?
Àṣá wo ìgbín kọ̀rọ̀; ìkaraun-un rẹ̀ ò jẹ́ kó gbé e.
Àṣá wọ̀bọ kò rọ́wọ́ gbé e.
Àṣírí ìkokò, ajá kọ́ ni yó tùú u.
Àtẹ́lẹwọ́ ẹni kì í tanni.
Àyè kì í há adìẹ kó má dèé ìdí àba-a rẹ̀.
|
|||||||
![]() |