Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 4: On perseverance, industry, resilience, self-confidence, self-reliance, resourcefulness, daring, fortitude, and invulnerability

Odot

Ọba tó fi iyùn bọlẹ̀, ọba tó wú u, àwọn méjèèjì la ó máa sọ orúkọ-ọ wọn.

Ọba tó sọ ẹgàn di erùfù; ọba tó sọ erùfù dẹgàn, àwọn méjèèjì la ó máa sọ orúkọ-ọ wọn.

Ọbẹ̀ tó dùn, owó ló pa á.

Ọbẹ̀-ẹ́ tutù tán, a dawọ́ bù ú lá.

Ọ̀dájú ló bí owó; ìtìjú ló bí gbèsè.

Ọdọọdún làgbẹ̀ ńníyì.

Ọdúnnìí ọdẹ́ pa erin; ẹ̀ẹ̀míràn ọdẹ́ pa ẹfọ̀n; ọdún mẹ́fà ọdẹ́ pa òló; ọlá ńrewájú, tàbí ọlá ńrẹ̀hìn?

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú ò ṣéé bùṣán; ọmọ burúkú ò ṣéé lù pa.

Ọgbọ́n òyìnbó ti ojú òkun là wá; aṣọ kí ni o borí akẹsẹ?

Ọjà tí a fowó rà, owó la fi ńpa.

Ọ̀-jẹ-wọ̀mù-wọ̀mù-kú-wọ̀mù-wọ̀mù lorúkọ tí àpà ńjẹ́.

Ọjọ́ a bá kọ́ ọ̀lẹ là ńkọ́ inú rírọ́.

Ọjọ́ a bá rí ìbí nìbí ńwọlẹ̀.

Ọjọ́ eré lọ̀ràn ńdun ọ̀lẹ.

Ọjọ́ tí a dóko là ńjìjà ilẹ̀.

Ọjọ́ tí a ńkọ́ṣẹ́ là ńkọ́ ìyára.

Ọ̀kàràkàrà ńké, ẹnu ẹ̀ ḿbẹ́jẹ̀; ó ní bí ẹnu òún ya dé ìpàkọ́, òun ó sàáà máa wí tòun.

Ọ̀lẹ́ bà á tì, ó kó sílé Ifá.

Ọ̀lẹ́ bà á tì, ó kó sílé-e kéú.

Ọ̀lẹ, baba àrùn.

Ọ̀lẹ èèyàn ò rí ayé wá.

Ọ̀lẹ́ fẹ́ àrùn kù, ó bú pùrù sẹ́kún.

Ọ̀lẹ́ fi ọ̀ràn gbogbo ṣe “hòo.”

Ọ̀lẹ́ jogún ìbànújẹ́, ó ní òún jogún ìran òun.

Ọ̀lẹ́ jogún ìbáwí.

Ọ̀lẹ́ kákò, ó di òjòjò.

Ọ̀lẹ́ kún àárẹ̀ lọ́wọ́.

Ọ̀lẹ́ mọ èèwọ̀ ìjà: ó ní bàbá òún ní kóun má jà lọ́nà oko.

Ọ̀lẹ́ ní ọjọ́ tí ikú bá pa òun, inú òhun á dùn. Ikú ní òun ó jẹ̀ẹ́ kí ojú ẹ̀ rí màbo.

Ọ̀lẹ́ ní ọjọ́ tí òún bá kú òun ó yọ̀; ohun tí ojú ọ̀lẹ́ máa rí kó tó kú ńkọ́?

Ọ̀lẹ ò yẹẹ́ ní lọ́mọ.

Ọ̀lẹ́ wáṣẹ́ rírọ̀ ṣe.

Ọlọgbọ́n kì í kú sóko ọ̀lẹ; bí ọlọgbọ́n bá kú sóko ọ̀lẹ, ọ̀ràn náà-á nídìí.

Ọlọ́mú dá ọmú ìyá ẹ̀ gbé.

Ọlọ́run yó pèsè; kì í ṣe bí èsè oríta.

Ọmọ tí yó jẹ̀ẹ́ àṣàmú, kékeré ní ńtií nṣẹnu ṣámú-ṣámú.

Ọmọ tó káwọ́ sókè ló fẹ́ ká gbé òun.

Ọmọ tó ṣípá fúnni là ńgbé jó.

Ọmọdé ò mọ ibi tí à ńpọn òun rè.

Ọ̀mu ní ńgbe ọ̀mu mì.

Ọ̀nà kì í dí mọ́ aládàá.

Ọ̀ràn búburú kì í bá ikún nílé.

Ọ̀ràn fini dùgbẹ̀-dùgbẹ̀ yinni nù; ọ̀ràn fini dùgbẹ̀-dùgbẹ̀ bí ẹnipé kò ní í tán; ọ̀ràn ḿbọ̀ wá tán; ojú á tẹlẹ́gàn, a sì ti ẹni tí ńyọnusọ.

Ọrùn kì í wọ òṣùká; ẹlẹ́rù lọrùn ńwọ̀.

Ọwọ́ atẹ́gùn ò ká gẹdú.

Ọwọ́ ẹni la fi ńtú ìwà ara ẹni ṣe.

Ọwọ́ ẹni ni yó yòóni.

Ọwọ́ ní ńtún ara ṣe.

Ọwọ́ tó dilẹ̀ là ńfi lérán.

Ọyẹ́ ni yó kìlọ̀ fún onítòbí.

.
PreviousContentsNext