![]() |
|||||||
Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 4: On perseverance, industry, resilience, self-confidence, self-reliance, resourcefulness, daring, fortitude, and invulnerabilityO
Ò báà kúrú, ò báà párí, gbèsè ò sí, ẹ̀sín ò sí; onígbèsè ló lè fini ṣẹ̀sín.
Ó di ọjọ́ tí àkàrà ìyá kùtà ká tó mọ ọmọ tó lè jẹ̀kọ.
Ó gbọ́ tiyán sògìrì mọ́dìí; o gbọ́ toko sọ àdá nù.
O kò gun ẹṣin lọ́sàn-án, o ò gun èèyàn lóru, o ò du nǹkan kàrà-kàrà; báwo lo ṣe lè ní káyé má fọ̀ọ́?
O kò ṣá igi lọ́gbẹ́, o ò sọ ògùrọ̀ lọ́fà, o dédìí ọ̀pẹ o gbẹ́nu sókè ò ńretí; ọ̀fẹ́ ní ńro?
“Ó kù díẹ̀ kí nwí”: ojo ní ńsọni da.
Ó ní ibi tí ó ńdé, itọ́-dídámì nínú ààwẹ̀.
O ní kí o gbó ogbó Olúàṣo; o lè jìyà bí Olúàṣo?
Ó pa obì, ó yọ abidún-un rẹ̀.
Obìnrin tí yó fẹ̀ẹ́ alágbára, ọkàn kan ní ḿmú.
Obìnrin tẹ́ẹ́rẹ́ yẹ ọkọ ẹ̀ níjọ́ ijó, obìnrin gìdìgbà-á yẹ ọkọ ẹ̀ níjọ́ èbù; bó bá ru ọgọ́rùnún èbù tán a kó kébé-kébé níwájú ọkọ.
Òbúrẹ́wà ẹni, tòrìṣà ni; àìraṣọlò, tolúwarẹ̀ ni.
Odídẹrẹ́ kì í kú sóko ìwájẹ.
Odò kì í kún bo ẹja lójú.
Odò tí a bá mọ orísun ẹ̀ kì í gbéni lọ.
Odó tó bá tojú ẹni kún kì í gbéni lọ.
Oògùn kì í gbé inú àdó jẹ́.
Ogun kì í jà kó wọlé Asẹ́yín.
Ogun kì í rí ẹ̀hìn ogun.
Ogún ọdún tí ebí ti ńpa ọ̀gà, ìrìn-in fàájì ò padà lẹ́sẹ̀-ẹ rẹ̀.
Ògbógbó àwọ̀n ní ḿbi ajáko.
Ohun kan ladìẹ ńjẹ kágbàdo tó dé.
Ohun tí a bá gbìn la ó kàá.
Ohun tí a bá gbìn sẹ́hìn la ó padà bá.
Ohun tí a fún ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ ni ẹ̀ṣọ́ ńṣọ́.
Ohun tó ṣe ìjímèrè tó fi gungi ẹ̀gẹ̀: bí kò bá rí ohun tó jù bẹ́ẹ̀ lọ kò ní sọ̀kalẹ̀.
Ohun tó ṣe ìwọ̀fà tí kò fi wá sóko olówó, bójú bá kan ojú yó sọ fún olówó-o rẹ̀.
Ohun títán lọdún eégún.
Òjìji ò bẹ̀rù ọ̀fìn.
Òjìji; ṣe lẹ́gẹ́-lẹ́gẹ́ má wòó.
Òjò ìbá rọ̀, kí ladẹ́tẹ̀ ìbá gbìn? Ọwọ́ adẹ́tẹ̀ ò ká ẹyọ àgbàdo mẹ́wàá.
Òjò pamí, òjò pa ère-è mi; òjò ò pa ẹwà ara-à mi dànù.
Òjò-ó pọnmi fún ọ̀lẹ, kò ṣẹ́gi fún ọ̀lẹ.
Òjò-ó pa alágùnúndì, àgúndìí domi; ìyàwó ńretí àgúndì, ọkọ́ sùn sóko.
Òjó jìyà gbé; alágbára-á bú u, ó gun àjà; a tọ̀ ọ́.
Òjò-ó pa odídẹ àlùkò ńyọ̀, àlùkò-ó rò pé ìkó bàjẹ́; òjó mú ìkó wọṣọ.
Òjòjò ọ̀lẹ ò tán bọ̀rọ̀; ọ̀lẹ́ bà á tì ó dáná orí.
Ojú abanijẹ́ pọ́n, kò lè tan fìtílà.
“Ojú àna-à mi ò sunwọ̀n”; kò ju kó gba ọmọ ẹ̀ lọ.
Ojú kì í pọ́n iṣin ká má bàá wóró nínú ẹ̀.
Ojú kì í pọ́n iṣin kó má là.
Ojú là ńrọ́; ògó ṣòro-ó ṣe.
Ojú lakàn-án fi ńṣọ́ orí.
Ojú mẹ́wàá kò jọ ojú ẹni.
“Ojú ò fẹ́rakù” tí ńta ajá ẹ lókòó; ó fowó ṣíyán jẹ.
Ojú olójú kì í gba ọ̀ràn fúnni wò.
Ojú olójú ò jọ ojú ẹni; a-ṣọ́ràn-deni ò wọ́pọ̀.
Ojú pọ́n koko má fọ̀ọ́; ọ̀gẹ̀dẹ̀ pọ́n koko má rọ̀; ọ̀rán fini dùgbẹ̀-dùgbẹ̀ yunni nù; ọ̀ràn tí ńfinni ò leè pani.
Ojú rẹ́gbin kò fọ́: a-jọ̀pọ̀-ìyà-má-rù.
Ojú ti kókó, ojú ti eéwo; ojú ti aáràgbá ìdí pẹ̀lú.
Ojú tí ńpọ́n awo àpọ́nkú kọ́; ìyà tí ńjẹ awo àjẹlà; ìṣẹ́ tí ńṣẹ́ awo à-ṣẹ́-ṣẹ́-obì-jẹ ni.
Ojú tó ti rí gbẹ̀lẹ̀dẹ́ ti rópin ìran.
Ojú tó ti rókun ò ní rọ́sà kó bẹ̀rù.
Ojúmọ́ kì í mọ́ kí ọwọ́ má yùn-ún ẹnu.
Ojúoró ní ńlékè omi; òṣíbàtà ní ńlékè odò.
Òkè lẹyẹ ńfọhùn.
Òkè méjì kì í bínú ẹni; bí a bá gun ọ̀kan, à sì máa rọ ọ̀kan.
Òkété fìjà sẹ́hìn; ó dọ́jà tán ó káwọ́ lérí.
Òkìkí ajá kì í pa oṣù.
Òkìkí ò poṣù; ariwo ò pagún; ibi ẹ rí ẹ kíbòsí-ì mi lọ.
Oko etílé ladìẹ́ lè ro.
Òkò kan igi; òkò padà sẹ́hìn kí o rebi o ti wá.
Òkú ò moye à ńràgọ̀.
Òkú ọdún mẹ́ta-á kúrò ní àlejò-o sàréè.
Òkú ọ̀lẹ ò ní pósí.
Olójú kì í fojú ẹ̀ sílẹ̀ kí tàlùbọ́ kó wọ̀ ọ́.
Olówó kì í fi owó ẹ̀ fún abòṣì na.
Olówó mọ òwò.
Olúmọ Ẹ̀gbá ò ṣéé gbé.
Omi adágún ò lè gbé màlúù lọ.
Omi ló dànù, agbè ò fọ́.
Omi ḿbẹ látọ́.
Omi ṣẹ́lẹ̀rú ò mu akèrègbè.
Omí wọ́ yanrìn gbẹrẹrẹ, bẹ́ẹ̀ni omi ò lọ́wọ́, omi ò lẹ́sẹ̀.
“Oní ló ḿmọ,” ìjà ọ̀lẹ.
Òní, “Mò ńlọ”; ọ̀la, “Mò ńlọ,” kò jẹ́ kí àlejò gbin awùsá.
Òní ọ̀wẹ̀, ọ̀la àro; iṣẹ́ oníṣẹ́ ò jẹ́ ká ráàyè ṣe tẹni.
Oníbàjẹ́ ò lódó; ẹnu gbogbo lodó-o wọn.
Oníbànà ní ńtọ́jú òrom̀bó; onídẹ ní ńtọ́jú awẹdẹ.
Onígbèsè èèyàn-án ti kú; a ò tíì sìnkú ẹ̀ ni.
OníṢàngó ò mẹni tí òún ńwà lóògì dànù.
Oníṣe kì í fiṣe ẹ̀ sílẹ̀ re ibi; ó ńre àjò ó mú iṣe ẹ̀ lọ́wọ́ gírígírí.
Oníṣòwó wà lóòrùn; náwónáwó wà níbòji.
Oníṣú fiṣu ẹ se ẹ̀bẹ; ojú ti atèèpojẹ.
Orí adẹ́tù ńpète àrán; orí adáràn-án ńpète àtijọba.
Orí iṣẹ́ laago ńkú lé.
Orí kì í tóbi kólórí má lè gbé e.
Orí ńlá kì í pá tán.
Orí olórí kì í báni gbẹ́rù.
Òrìṣà tí ńgbọ̀lẹ ò sí; apá ẹni ní ńgbeni.
Oríta mẹ́ta ò kọnnú ẹbọ.
Òru ni ìnàhìn àgbẹ̀.
Oòrùn ò kan àtàrí, ọwọ́ ò dá.
Oòrùn ò pa ọ́, òjò ò pa ọ́, o ní ò ńṣiṣẹ́ ajé.
Òṣìṣẹ́ lọ̀tá ọ̀lẹ.
Òṣìṣẹ́ wà lóòrùn; ẹní máa jẹ́ wà níbòji.
Oṣù mẹ́ta lebi ńpàgbẹ̀.
Òwò àdà kì í pa àdá; òwò ọkọ́ kì í yọ ọkọ́ lẹ́nu.
Owó ò mọ ẹ̀gbọ́n, ó sọ àbúrò dàgbà.
Owó ò níran; àfi ẹni tí kò bá ṣiṣẹ́.
Òwò tí a bá máa ṣe àṣelà, a kì í rí àpá ẹ̀ lára ẹni.
Òwò tí a fowó rà, owó la fi ńpa.
Òwò tí a ó ṣe là ńtọ́jú; Òjí fabẹ họra.
Owó olówó leégún ńná.
Òyìnbó baba ọ̀nájà; ajé baba téní-téní.
Òyìnbó ta ọjà ta orúkẹ; Ègún tajà ta èdìdì.
|
|||||||
![]() |