Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 3: On cageyness, caution, moderation, patience, and prudence

Edot

Ẹ pa Ayéjẹ́nkú, ẹ pa Ìyálóde Aníwúrà; ìgbà tí ẹ pa Ìyápọ̀ ẹ gbàgbé ogun.

Ẹ̀bi alábaun kì í gbèé dẹ̀bi àna-a rẹ̀.

Ẹ̀bìtì ò peèrà tó ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́; ẹnu ẹni níńpani.

Ẹ̀bìtì tí ò kún ẹmọ́ lójú, òun ní ńyí i lẹ́pọ̀n sẹ́hìn.

Ẹ̀gbá mọ̀dí Ọbà; ẹni tó gbéniṣánlẹ̀-ẹ́ lè pani.

Ẹgbẹ́ ẹja lẹja ńwẹ̀ tọ̀; ẹgbẹ́ ẹyẹ lẹyẹ ńwọ́ lé.

Ẹ̀hìn àjànàkú là ńyọ ogbó; ta ní jẹ́ yọ agada lójú erin?

Ẹ̀hìn ní ńdun ol-ókùú-àdá sí.

Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọmọ ńsín tí à ńní “à-sín-gbó, à-sín-tọ́.”

Ẹ̀kọ tí kò bá léwé làgbà ńgbà.

Ẹkùn kì í yan kí ajá yan.

Ẹlẹ́dẹ̀ tó kú légbodò ló ní ká fòun jẹyán.

Ẹlẹ́jọ́ kú sílé, aláròyé kú síta gbangba.

Ẹlẹ́kún sunkún ó bá tirẹ̀ lọ; aláròpa ìbá sunkún kò dákẹ́.

Ẹlẹ́rù ní ńgbé ẹrù ká tó ba ké ọfẹ.

Ẹ̀lúlùú, ìwọ ló fòjò pa ara-à rẹ.

Ẹni àjò ò pé kó múra ilé.

Ẹní bá rọra pa eèrà á rí ìfun inú-u rẹ̀.

Ẹní bá fẹ́ abuké ni yó ru ọmọ-ọ rẹ̀ dàgbà.

Ẹní bá fẹ́ arúgbó gbẹ̀hìn ni yó sìnkú-u rẹ̀.

Ẹní bá mọ ayé-é jẹ kì í gun àgbọn.

Ẹní bá mọ ayé-é jẹ kì í jà.

Ẹní bá mọ iṣin-ín jẹ a mọ ikú ojú-u rẹ̀-ẹ́ yọ̀.

Ẹní bá na Ọ̀yẹ̀kú á ríjà Ogbè.

Ẹní bá sọ púpọ̀ á ṣìsọ.

Ẹní bá pé kí àkàlà má jòkú, ojú-u rẹ̀ lẹyẹ ńkọ́kọ́ yọ jẹ.

Ẹní bẹni-í tẹ́ni.

Ẹní dáríjiní ṣẹ̀tẹ́ ẹjọ́.

Ẹní dúró de erín dúró dekú; ẹní dúró dẹfọ̀n-ọ́n dúró dèjà; ẹní dúró de eégún alágangan, ọ̀run ló fẹ́-ẹ́ lọ.

Ẹní fi ìpọ́njú kọ ẹyìn á kọ àbọ̀n; ẹní fi ìpọ́njú rojọ́ á jẹ̀bi ọba; ẹní fi ìpọ́njú lọ gbẹ́ ìhò á gbẹ́ ihò awọ́nrínwọ́n.

Ẹní gúnyán kalẹ̀ yóò júbà ọbẹ̀.

Ẹní gbé adíẹ òtòṣì-í gbé ti aláròyé.

Ẹní kánjú jayé á kánjú lọ sọ́run.

Ẹni méjì kì í bínú egbinrin.

Ẹni òyìnbó fẹ́ràn ní ńtì mọ́lé.

Ẹní ṣe ọ̀ràn Ìjẹ̀bú: etí ẹ̀ á gbọ́ ìbọn.

Ẹni tí a bá ḿbá ṣiṣẹ́ kì í ṣọ̀lẹ; bórí bá túnni ṣe a kì í tẹ́ bọ̀rọ̀.

Ẹni tí a bá ḿmú ìyàwó bọ̀ wá fún kì í garùn.

Ẹni tí a bá ti rí kì í tún ba mọ́lẹ̀ mọ́.

Ẹni tí a fẹ́-ẹ́ sunjẹ kì í fepo para lọ jókòó sídìí iná.

Ẹni tí a lù lógbòó mẹ́fà, tí a ní kó fiyèdénú: ìgbà tí kò fiyèdénú ńkọ́?

Ẹni tí a ò lè mú, a kì í gọ dè é.

Ẹni tí a ò lè mú, Ọlọ́run là ńfi lé lọ́wọ́.

Ẹni tí ńsáré kiri nínú-u pápá ńwá ọ̀nà àti jìn sí kòtò.

Ẹni tí ó bá wọ odò ni àyà ńkò, àyà ò fo odò.

Ẹni tí ó jìn sí kòtò-ó kọ́ ará ìyókù lọ́gbọ́n.

Ẹni tí ó tọ odò tí kò dẹ̀hìn yò bàá Olúwẹri pàdé.

Ẹni tí ó bá mu ọtí ogójì á sọ̀rọ̀ okòó.

Ẹni tí ó yá ẹgbàafà tí kò san án, ó bẹ́gi dí ọ̀nà egbèje.

Ẹni tí ó ba ogún-un baba rẹ̀ jẹ́, ó ja òkú ọ̀run lólè, yó sì di ẹni ìfibú.

Ẹni tí ó mú u lórí ní ó kú, ìwọ tí o mú u lẹ́sẹ̀-ẹ́ ní ó ńjòwèrè.

Ẹni tí ó bá obìnrin kó lọ sílé-e rẹ̀ yó sùn nínú ẹ̀rù.

Ẹni tí ò fẹ́-ẹ́ wọ àkísà kì í bá ajá ṣe eré-e géle.

Ẹni tí ò tóni-í nà ò gbọdọ̀ ṣe kọ́-ń-dú síni.

Ẹni tí Orò-ó máa mú ḿba wọn ṣe àìsùn orò.

Ẹnìkan kì í fi ọ̀bẹ tó nù jẹṣu.

Ẹnu ẹyẹ ní ńpẹyẹ; ẹnu òrofó ní ńpòrofó; òrofó bímọ mẹ́fà, ó ní ilé òun-ún kún ṣọ́ṣọ́ṣọ́.

Ẹnu iná ní ńpa iná; ẹnu èrò ní ńpa èrò..

Ẹnu ni àparò-ó fi ńpe ọ̀rá; a ní “Kìkì ọ̀rá, kìkì ọ̀rá!”

Ẹnu òfòrò ní ńpa òfòrò; òfòrò-ó bímọ méjì, ó kó wọn wá sẹ́bàá ọ̀nà, ó ní “Ọmọ-ọ̀ mí yè koro-koro.”

Ẹnu tí ìgbín fi bú òrìṣà ní ńfi-í lọlẹ̀ lọ bá a.

Ẹnu-ù mi kọ́ ni wọ́n ti máa gbọ́ pé ìyá ọba-á lájẹ̀ẹ́.

Ẹrẹ̀ òkèọ̀dàn ni yó kìlọ̀ fún a-l-áròó-gbálẹ̀ aṣọ.

Ẹ̀rù kọ́ ní ḿba ọ̀pẹ tó ní ká dá òun sí, nítorí ẹmu ọ̀la ni.

Ẹṣin iwájú ni ti ẹ̀hìn ńwò sáré.

Ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀ la fi ńlá ọbẹ̀ tó gbóná.

Ẹ̀tẹ́ ní ńgbẹ̀hìn aláṣejù.

Ẹyẹ kí lo máa pa tí ò ńfi àkùkọ ṣe oògùn àtè?

Ẹyin lọ̀rọ̀; bó bá balẹ̀ fífọ́ ní ńfọ́.

Ẹyin adìẹ ò gbọdọ̀ forí sọ àpáta.

.
PreviousContentsNext