Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 3: On cageyness, caution, moderation, patience, and prudence

E

Èké tan-ni síjà ẹkùn, ó fi ọrán ṣíṣẹ́ sápó ẹni.

Eku tí yó pa ológìnní ò níí dúró láyé.

Eku ò gbọdọ̀ ná ọjà tí ológìnní dá.

Èmi ló lòní, èmi ló lọ̀la” lọmọdé fi ńdígbèsè.

Èmi ò wá ikún inú agbè fi jiyán; ṣùgbọ́n bíkún bá yí sínú agbè mi mo lè fi jiyán.

Èpè-é pọ̀ ju ohun tó nù lọ; abẹ́rẹ́ sọnù a gbé ṣẹ́ẹ́rẹ́ síta.

Èpè-é pọ̀ ju ohun tó nù; abẹ́rẹ́ sọnù wọ́n lọ gbé Ṣàǹgó.

Eré-e kí lajá ḿbá ẹkùn ṣe?

Èrò kì í; jẹ́wọ́-ọ “Mo tà tán.”

Eṣinṣin ò mọkú; jíjẹ ni tirẹ̀.

Èṣù ò ṣejò; ẹni tó tẹ ejò mọ́lẹ̀ lẹ̀bá ḿbá.

Etí mẹta ò yẹ orí; èèyàn mẹ́ta ò dúró ní méjì-méjì.

Ewú logbó; irùngbọ̀n làgbà; máamú làfojúdi.

Ewúrẹ́ jẹ ó relé; àgùntán jẹ ó relé; à-jẹ-ì-wálé ló ba ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́.

Ewúrẹ́ kì í wọlé tọ ìkokò.

Èèyan má-jẹ̀ẹ́-kí-èèyàn-kú ḿbẹ níbòmíràn; bó-le-kú-ó-kú m̀bẹ nílé-e wa.

Èèyàn-án ní òun ó bà ọ́ jẹ́ o ní kò tó bẹ́ẹ̀; bí ó bá ní o ò nùdí, ẹni mélòó lo máa fẹ fùrọ̀ hàn?

Èyí ayé ńṣe ng kà ṣàì ṣe; bádìẹ-ẹ́ máa wọ ọ̀ọ̀dẹ̀ a bẹ̀rẹ̀.

Èyí ò tófò, èyí ò tófò; fìlà ìmàle-é kù pẹ́tẹ́kí.

.
PreviousContentsNext