Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 3: On cageyness, caution, moderation, patience, and prudence

B

“Bá mi mádìẹ” kì í fi orúnkún bó.

Baálé ilé kú, wọ́n fi olókùnrùn rọ́lé; ẹkún ńgorí ẹkún.

“Baálé pè mí nkò wá”, ọ̀hànhàn ní ńpa wọ́n.

Bánú sọ, má bàá èèyàn sọ; èèyàn ò sí; ayé ti dèké.

Bí a bá bu ìrẹ̀ jẹ, ká bu ìrẹ̀ sápò.

Bí a bá bu ọba tí a sẹ́, ọba a fini sílẹ.

Bí a bá bú ọba, à sẹ́; bí a bá bú ọ̀ṣọ̀run, à sẹ́.

Bí a bá dákẹ́, tara ẹni a báni dákẹ́.

Bí a bá fa àgbò féégún, à fi okùn-un rẹ̀ sílẹ̀.

Bí a bá fẹ́ràn ọ̀rẹ́ ẹni láfẹ̀ẹ́jù, bó bá forígbún, ìjà níńdà.

Bí a bá fi dídùn họ ifàn, a ó họra dé egun.

Bí a bá fi ojú igi gbígbẹ wo tútù, tútù-ú lè wó pani.

Bí a bá fi ọdún mẹ́ta pilẹ̀ṣẹ̀-ẹ wèrè, ọjọ́ wo la ó bunijẹ?

Bí a bá fi ọdún mẹ́ta ṣánpá, ọdún mélòó la ó fi fò?

Bí a bá fi ọwọ́ kan fọmọ fọ́kọ, ọwọ́ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá kì í ṣeé gbà á mọ́.

Bí a bá lé ẹni, tí a kò bá ẹni, ìwọ̀n là ḿbá ẹni-í ṣọ̀tá mọ.

Bí a bá ní ká bẹ́ igi, a ó bẹ̀ẹ́ èèyàn.

Bí a bá ní ká jẹ èkuru kó tán, a kì í gbọn ọwọ́-ọ rẹ̀ sáwo.

Bí a bá ńjà, bí í kákú là ńwí?

Bí a bá ńretí òfò, ká fi ohun tọrẹ.

Bí a bá perí ajá, ká perí ìkòkò tí a ó fi sè é.

Bí a bá róbìnrin à lérí ogun; bí a bá róbìnrin à sọ̀rọ̀ ìjà; bí a dé ojú ogun à ba búbú.

Bí a bá sọ́ pé ẹyẹ ni yó jẹ ojú ẹni, bí a rí tí-ń-tín, a ó máa sá lọ.

Bí a bá sọ̀kò sí àárín ọjà, ará ilé ẹni ní ḿbà.

Bí a bá sọ̀rọ̀ fún olófòófó, ajádìí agbọ̀n la sọ ọ́ sí.

Bí a bá ṣí ìdí ẹni sókè, ọmọ aráyé á rọ omi gbígbóná sí i.

Bí a bá wí a dàbí òwe; bí a ò bá wí a dàbí ìjà.

Bí a kò bá láyà-a rìndọ̀rìndọ̀, a kì í jẹ aáyán.

Bí a kò bá lè kú, ìpẹ̀ là ńgbà.

Bí a kò bá lè mú ọkọ, a kì í na obìnrin-in rẹ.

Bí a kò bá lówó aládìn-ín, à jẹun lójúmọmọ, à gbálẹ̀ sùn wàrà.

Bí a kò bá ní èsè ẹ̀fà, a kì í kó iṣu òje.

Bí a kò bá rí wọlé-wọ̀de a ò gbọdọ̀ wọlé ọba.

Bí a kò bá rígún, à fàkàlà ṣẹbọ.

Bí a kò bá ṣe fún ilẹ̀, a kì í fi ọwọ́ sọ ọ́.

Bí a kò rówó ra ẹrú, à sọ adìẹ ẹni lórúkọ.

Bí a ó ti ṣe é ní ńfi ara-a rẹ̀ hàn.

Bí adìẹ́ bá gbélẹ̀ a ya òpìpì.

Bí àjànàkú ò bá gbẹ́kẹ̀lé fùrọ̀, kì í mi òdù àgbọn.

Bí àjẹ́ bá mupo, ojú-u rẹ̀ a rọ̀.

Bí alágbára-á bá jẹ ọ́ níyà, fẹ̀rín sí i.

Bí alágẹmọ-ọ́ bá fẹ́ kọjá, ìjàm̀pere ò ní-í jà.

Bí alẹ́ bá lẹ́, adẹ́tẹ̀ a rìn, a yan.

Bí àṣá bá ḿbínú, sùúrù ló yẹ ọlọ́jà.

Bí aáṣẹ́ bá ti ńfò, bẹ́ẹ̀ la ti ńsọ̀kò sí i.

Bí awó ti ńlù lawó ti ńjó.

Bí bàtá bá ró àrójù, yíya ní ńya.

Bí ekòló bá kọ ebè, ara-a rẹ̀ ni yó gbìn sí i.

Bí èṣù ikú bá ńṣe ìgbín nìgbín ńyẹ́yin.

Bí ẹjá bá sùn, ẹja á fi ẹja jẹ.

Bí ẹlẹ́hìnkùlé ò sùn, à pẹ́ lẹ́hìnkùlé-e rẹ̀ títí; bó pẹ́ títí orun a gbé onílé lọ.

Bí ẹlẹ́jọ́ bá mọ ẹjọ́-ọ rẹ̀ lẹ́bi, kì í pẹ́ níkùnúnlẹ̀.

Bí ẹnìkán bá fojú di Orò, Orò a gbé e.

Bí ẹnìkán ṣe ohun tí ẹnìkan ò ṣe rí, ojú-u rẹ̀ á rí ohun tí ẹnìkan ò rí rí.

Bí ìdí ìkokò kò bá dá a lójú, kì í gbé egungun mì.

Bí ìfà bí ìfà lọmọdé fi ńdáràn wọlé.

Bí ilé bá dá, adẹ́tẹ̀ a rìn, a yan. When the house is deserted, the leper will walk and strut.

Bí ìlùú bá dún àdúnjù, yó fàya.

Bí iná bá jóni, tó jó ọmọ ẹni, tara ẹni là ńkọ́ gbọ̀n.

Bí iṣu ẹní bá funfun, à fọwọ́ bò ó jẹ.

Bí kò bá sí oníṣẹ́ iṣẹ́ ò leè lọ; bí kò bá sí ọlọ́wẹ̀ a kì í ṣọ̀wẹ̀; àkẹ̀hìnsí ọlọ́wẹ̀ là ńṣípá.

Bí o máa ra ilá ra ilá, bí o máa gba ènì gba ènì; ọmọdé kì í wá sọ́ja Agbó-mẹ́kùn kó wá mú eku.

Bí obìnrín bá wọgbó orò, a ò lè rí àbọ̀-ọ ẹ̀ mọ́.

Bí ògbó ẹni ò bá dánilójú, a kì í fi gbárí wò.

Bí ojú alákẹdun ò dá igi, kì í gùn ún.

Bí ojú onísó ò bá sunwọ̀n, a kì í lọ̀ ọ́.

Bí ológbò-ó bá pa eku, a fi ìrù-u rẹ̀ dẹlé.

Bí ológbò-ó bá ṣẹ̀ ńpa ẹmọ́, à mọ̀ pé ó máa lọ.

Bí olówe-é bá mọ òwe-e rẹ̀, tí kò já a, ẹ̀rù ìjà ḿbà á ni.

Bí òní ti rí, ọ̀la ò rí bẹ́ẹ̀, ni babaláwo-ó fi ńdÍfá lọ́rọọrún.

Bí oníṣú bá fi iṣu-u rẹ̀ se ẹ̀bẹ, ọgbọ́n a tán nínú a-tu-èèpo-jẹ.

Bí ooré bá pọ̀ lápọ̀jù, ibi ní ńdà.

Bí òwe ò bá jọ òwe, a kì í pa á.

Bí ọmọ ẹní bá dára, ká sọ pé ó dára; bí-i ká fi ṣaya ẹni kọ́.

Bí ọmọdé bá dárí sọ apá, apá á pá; bó bá dárí sọ ìrókò, ìrókò a kò ó lọ́nà.

Bí ọmọdé ò rí àjẹkù-u kìnìún nínú igbo, a ní kí ẹran bí ẹkùn ó pa òun.

Bí ọ̀nà-á dé orí àpáta, níṣe ní ńpin.

Bí ọ̀ràn-án bá ṣú òkùnkùn, à bẹ̀ ẹ́ wò lábẹ́.

Bí ọ̀ràn ò tán, ibì kan là ńgbé; arékété lohun ńṣe.

Bí ọtí bá kún inú, ọtí á pọmọ; bí oòrùn-ún bá pọ̀ lápọ̀jù a sọ ọmọ di wèrè; bí a bá lọ́ba lánìíjù a sínni níwín; tẹ̀tẹ̀ ẹ̀gún pọ̀ lódò o di olú eri.

Bí ọwọ́ ò bá tẹ èkù idà, a kì í bèrè ikú tó pa baba ẹni.

Bíbi là ḿbi odò wò ká tó wọ̀ ọ́.

Bọ̀rọ̀kìnní àṣejù, oko olówó ni ḿmúni lọ.

Bọ̀rọ̀kìnnín lọ̀tá ìlú; afínjú lọba ńpa.

.
PreviousContentsNext