Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 3: On cageyness, caution, moderation, patience, and prudence

A

A bu omi lámù a rí eégún; kí ni ẹni tó lọ sódò lọ pọnmi yó rìí?

A fún ọ níṣu lỌ́yọ̀ọ́ ò ńdúpẹ́; o rígi sè é ná?

A ki ẹsẹ̀ kan bọ odò omi fà á; bí a bá wá ti mejèèjì bọ́ ọ́ ńkọ́?

A kì í bá ẹlẹ́nu jìjà òru.

A kì í bú ọba onígẹ̀gẹ̀ lójú àwọn èèyàn-án ẹ̀.

A kì í du orí olórí kí àwòdì gbé tẹni lọ.

A kì í fi ìkánjú lá ọbẹ̀ gbígbóná.

A kì í gbélé gba ọfá láìlọ ogun.

A kì í kánjú tu olú-ọrán; igba ẹ̀ ò tó-ó sebẹ̀.

A kì í rídìí òkun; a kì í rídìí ọsà; ọmọ-oní-gele-gele kì í jẹ́ kí wọ́n rídìí òun.

A kì í rójú ẹni purọ́ mọ́ni.

A kì í sọ̀rọ̀ orí bíbẹ́ lójú ọmọdé; lọ́rùnlọ́rùn ni yó máa wo olúwa-a ẹ̀.

À ńgba òròmọ adìẹ lọ́wọ́ ikú, ó ní wọn ò jẹ́ kí òun jẹ̀ láàtàn.

A níṣẹ́ iṣẹ́ ẹ, o ní ò ńlọ sóko; bó o bá lọ sóko ò ḿbọ̀ wá bá a nílé.

À ńṣa kẹ́kẹ́, aájò ẹwà ni; à ḿbàbàjà, aájò ẹwà ni.

A sìnkú tán, alugba ò lọ; ó fẹ́ ṣúpó ni?

Abẹ ní ḿbẹ orí; oníṣẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ ní ḿbẹ ọ̀nà; bèbè ìdí ní ḿbẹ kíjìpá; bí a dáwọ́-ọ bíbẹni, a tán nínú ẹni.

Abẹ́rẹ́ bọ́ sómi táló; Ọ̀dọ̀fín ní òun-ún gbọ́ “jàbú!”

Abiyamọ, kàgbo wàrà; ọjọ́ ńlọ.

Àbùlẹ̀ ní ḿmú aṣọ tọ́; ẹni tí kò tọ́jú àbùlẹ̀ yó ṣe ara-a ẹ̀ lófò aṣọ.

Àdàbà ńpògèdè, ó rò pé ẹyẹlé ò gbọ́; ẹyẹlé gbọ́, títiiri ló tiiri.

Adìẹ́ ńjẹkà, ó ḿmumi, ó ńgbé òkúta pẹ́-pẹ̀-pẹ́ mì, ó ní òun ò léhín; ìdérègbè tó léhín ńgbé irin mì bí?

Àdó gba ara ẹ̀ tẹ́lẹ̀, ká tó fi oògùn sí?

Àdóìṣí loògùn ọrọ̀.

Afẹ́fẹ́ tó wọlé tó kó aṣọ iyàrá, ìkìlọ̀ ni fún ẹni tó wọ tiẹ̀ sọrùn.

Àfojúdi ìlẹ̀kẹ̀ ní ńjẹ́ “Ẹrú-kò-ní.”

Àgékù ejò, tí ńṣoro bí agbọ́n.

Àgúnbàjẹ́ ni tolódó.

Àgùntàn bọ̀lọ̀jọ̀ ò gbàgbé eléèrí bọ̀rọ̀.

Àgùntàn ńwò sùn-ùn; ọgbọ́n inú pé egbèje.

Àgùntàn ò jí ní kùtùkùyù ṣe ẹnu bọbọ.

Àgbà òṣìkà ńgbin ìyà sílẹ̀ de ọmọ-ọ rẹ̀.

Àgbẹ̀ ò dáṣọ lóṣù, àfọdún.

Àgbẹ̀ tó bá pẹ́ nílé ò níí kọ oko ọ̀sán.

À-gbẹ́rù-àì-wẹ̀hìn lọ̀pálábá fi gbàgbé ìyá ẹ̀ sílẹ̀.

Agbójúlógún fi ara-a rẹ̀ fóṣì ta.

Àgbọ́ká etí ọlọ́ràn á di.

Àgbọ́kànlé ò pani lébi.

Àìfẹ̀sọ̀ké ìbòsí ni kò ṣéé gbè.

Àìgbọ́ràn, baba àfojúdi.

Àìlèfọhùn ní ńṣáájú orí burúkú.

Àìrọ́rọ̀sọ ìyàwó tó wí pé èkúté-ilé yó jẹ idẹ; bẹ́ẹ̀ni Mọ́jidẹ nìyálé-e rẹ̀ ńjẹ́.

Àìsàn là ńwò, a kì í wo ikú.

Àìtètèmólè, olèé mólóko.

Ajá ilé ò mọdẹẹ́ ṣe.

Ajá kì í dán-nu “Kò séwu” lókò ẹkùn.

Ajá tí yó sọnù kì í gbọ́ fèrè ọdẹ.

Ajá tó rí mọ́tò tó dúró fi ara-a ẹ̀ bọ Ògún.

Àjànàkú tí a gbẹ́ ọ̀fìn sílẹ̀ dè, erin-ín mojú; erin ò bá ibẹ̀ lọ.

Àjẹ́ ńké, òkùnrùn ò paradà; ó lówó ẹbọ nílé.

Ajẹnifẹ́ni, èkúté ilé.

Aaka ò gbé ọ̀dàn; igbó ní ńgbé.

Àkàlàmàgbò-ó ṣoore ó yọ gẹ̀gẹ̀ lọ́rùn.

Akánjú jayé, ọ̀run wọn ò pẹ́.

Àáké tí ńgégi-í kọsẹ̀, gbẹ́nàgbẹ́nà-á bu ètù sórí.

Àkèekèé ò ṣé-é dì níbò.

Àkèekèé rìn tapótapó.

Àkèekèé ta Kindo lẹpọ̀n, ará ilée Labata ńrojú; kí ló kàn án níbẹ̀?

Akóbáni lèkúté-ilé; ejò kì í jàgbàdo.

Àkọ̀ tó bá bá ọ̀bẹ dìtẹ̀ á gbọgbẹ́ láti inú.

Àlá tí ajá bá lá, inú ajá ní ńgbé.

Alágbàró ò yege; aláṣọ á gbà á bó dọ̀la.

Aláǹgbá tó fojú di erè, ikùn ejò ni yó bàá ara-a ẹ̀.

Alápàáǹdẹ̀dẹ̀ ńjayé lébé-lébé.

Alára ò lè wí pé kò dun òun, ká ní ó kú àìsùn, ó kú àìwo.

Alárìnjó tí yó jòó, kó ti ìwòyí mú ẹsẹ̀ kó le kó kó kó.

Aláàárù kì í sọ pé kí ajé ṣe òun pa; ẹlẹ́rù ńkọ́?

Aláwàdà ló lè ṣọkọ òṣónú; ẹni tí kò lẹ́nu mímú tete ò lè ṣọkọ alápẹpẹ.

Àlejò tó wọ̀ nílé-e Pọ́ngilá, Pọ́ngilá ní, “Ìwọ ta ni?” Àlejò-ó ní òun Bugijẹ; Pọ́ngilá ni, “Tòò, lọ́ dájú igi-i tìrẹ lọ́tọ̀.”

Àlọ ti alábaun; àbọ̀ ti àna-a rẹ̀.

Àlùkẹrẹsẹ ò mọ̀ pé olóko-ó ládàá.

Àmọ̀jù là ḿmọ ẹkùn-un Sàárẹ́.

Àpáàdì ló tó ko iná lójú.

Apatapara-á pa ara-a rẹ̀ lájùbà; ẹni tí yó ko là ńwòye.

Àpò tí a kò fi ọwọ́ ẹni dá ṣòro-ó kiwọ́ bọ̀.

Ará Ìbàdàn kì í ságun; à ó rìn sẹ́hìn ni wọ́n ńwí.

À-rí-ì-gbọdọ̀-wí, à-rí-ì-gbọdọ̀-fọ̀ ni ikú awo.

Àrísá iná, àkòtagìrì ejò; àgbà tó réjò tí kò sá, ara ikú ló ńyá a.

Àròkàn ní ḿmú à-sun-ùn-dá wá; ẹlẹ́kún sunkún ẹ̀ ó lọ.

Arọ ò nasẹ̀ kan dí ọ̀nà.

Arọ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀-ẹ́ lọ́gbọ́n nínú.

Arọ́basá ò ṣojo.

Arúgbó ṣoge rí; àkísà-á lògbà rí.

Àrùn là ńwó a kì í wokú.

Asárétete ní ńkọjá ilé; arìngbẹ̀rẹ̀ ni yóò rí oyè jẹ.

Àṣá ḿbá ẹyẹlé ṣeré, ẹyẹlé ńyọ̀; ẹyẹlé ńfikú ṣeré.

Àṣàyá kì í jẹ́ kí ọmọ ọ̀yà ó gbọ́n.

Àṣesílẹ̀ làbọ̀wábá; ẹni tó da omi síwájú á tẹlẹ̀ tútù.

Àṣẹ̀ṣẹ̀wọ́n ológbò ní ńjìyà; bó bá pẹ́ títí a tó eku-ú pa.

Aṣòroówọ̀ bí ẹ̀wù àṣejù.

Ata-á kéré; ìjá jù ú.

Atàkò fọ́ ẹyin àparò; ohun ojú ńwá lojú ńrí.

Ataare-é rẹ́ni tún ìdí-i rẹ̀ ṣe ó ńfi òbùró ṣẹ̀sín; òbùró ìbá rẹ́ni tún ìdí-i rẹ̀ ṣe a sunwọ̀n jú ataare lọ.

Atẹ̀hìnrọ́gbọ́n agétí ajá; a gé e létí tán ó fabẹ pamọ́.

Àtẹ́lẹwọ́ ẹni kì í tanni.

1e Atọrọohungbogbolọ́wọ́Ọlọ́run kì í kánjú.

Àwòfín ní ḿmú ọ̀rẹ́ bàjẹ́; fírí là ńwo ẹni tí ńwoni.

Àáyá kan-án bẹ̀ ọ́ wò; igba wọ́n ti rí ọ.

Ayáraròhìn, aya ọdẹ, ó ní ọkọ òun-ún pa èkínní, ó pa ẹ̀kẹfà.

Àyé gba ògùnmọ̀ ó ránṣẹ́ sí òdú; àyé gba Tápà ó kọ́lé ìgunnu.

Ayé ò ṣéé fipá jẹ.

.
ContentsNext