Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 3: On cageyness, caution, moderation, patience, and prudence

Odot

Ọ̀bánijà ní ḿmọ ìjagun ẹni.

Ọ̀bàrà gba kùm̀mọ̀; ó dÍfá fún a-láwìí-ì-gbọ́.

Ọ̀bàyéjẹ́, tí ńru gángan wọ̀lú.

“Ọbẹ̀ lọmú àgbà” ló pa onígbaǹso Ògòdò.

Ọbẹ ṣìlò-ó ḿbáni ṣeré a ní kò mú; bí eré bí eré ó ńpani lọ́wọ́.

Ọbẹ̀ tóo sè tílé fi jóná wàá sọ ọ́.

Ọ̀bẹlẹ̀wò bẹlẹ̀wò; bí ewúrẹ́ yó bàá dùbúlẹ̀ a bẹ ilẹ̀ ibẹ̀ wò.

Ọ̀bọ ni yo para ẹ̀.

Ọ̀dárayá tí ńfi ẹ̀gbẹ́ na igi.

Ọ̀daràn ẹyẹ tí ńmusàn.

Ọdẹ a-fi-fìlà-pa-erin, ọjọ́ kan ni òkìkí-i ẹ̀ ḿmọ.

Ọ̀gá-a má fi ẹsẹ̀ yí ẹrẹ̀, gbogbo ara ní ńfi yí i.

Ọ̀gán ìmàdò ò ṣé-é kò lójú.

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ ḿbàjẹ́, a ní ó ńpọ́n.

Ọ̀gọ̀ ńgbé ọ̀gọ rù.

Ọ̀gbágbá wọlẹ̀, ó ku àtiyọ.

Ọgbọ́n àgbọ́njù ní ńpa òdù ọ̀yà.

Ọgbọ́n àgbọ́njù ní ńsọ ẹni diwin; bí oògún bá pọ̀ lápọ̀jù a sọni di wèrè; bóbìnrín bá gbọ́n àgbọ́njù, péńpé laṣọ ọkọ-ọ ẹ̀ ḿmọ.

Ọgbọ́n ọdúnnìí, wèrè ẹ̀míì.

Ọgbọ́n pẹ̀lú-u sùúrù la fi ḿmú erin wọ̀lú.

Ọjọ́ tí a ó bàá nù, gágá lara ńyáni.

Ọjọ́ tí a to ọkà a ò to ti èkúté mọ́ ọ.

Ọjọ́ tí àgbẹ̀ ṣíṣe-é bá di kíyèsílẹ̀, ká ṣíwọ́ oko ríro.

Ọjọ́ tí elétutu-ú bá máa fò, ìjàm̀pere kì í rìn.

Ọ̀kánjúwà àgbẹ̀ tí ńgbin òwú sóko àkùrọ̀.

Ọ̀kánjúwà baba àrùn.

Ọ̀kánjúwà baba olè; àwòròǹṣoṣò-ó wo ohun olóhun má ṣèẹ́jú.

Ọ̀kánjúwà-á bu òkèlè, ojù ẹ̀-ẹ́ lami.

Ọ̀kánjúwà èèyàn-án dé àwùjọ, ó wòkè yàn-yàn-àn-yàn.

Ọ̀kánjúwà kì í mu ẹ̀jẹ̀ ẹlòmíràn; ẹ̀jẹ̀ ara ẹ̀ náà ní ḿmu.

Ọ̀kánjúwà ò ṣé-é fi wá nǹkan.

Ọ̀kánjúwà ológbò tó jókòó sẹ́nu ọ̀nà; ṣé eku eléku ló fẹ́ pa jẹ?

Ọ̀kánjúwà Oníṣàngó ní ńsọ ọmọ rẹ̀ ní Bámgbóṣé; ìwọ̀n oṣé tí a lè gbé là ńgbé.

Ọ̀kánjúwà pẹ̀lú olè, déédé ni wọ́n jẹ́.

Ọ̀kánjúwà-á pín ẹgbàafà nínú ẹgbàaje; ó ní kí wọ́n pín ẹgbàá kan tó kù, bóyá igbiwó tún lè kan òun.

Ọ̀kẹ́rẹ́ gorí ìrókò, ojú ọdẹ-ẹ́ dá.

Ọkọ̀ ńjò, ọkọ̀ ńjò! Ìgbà tó bá rì, kò parí ná?

Ọ̀kọ̀ọ̀kan lọwọ̀ ńyọ.

Ọ̀kùn-ún mọ̀nà tẹ́lẹ̀ kójú ẹ̀ tó fọ́.

Ọkùnrin tó fẹ́ òjòwú méjì sílé ò rẹ́ni fi ṣọ́lé.

“Ọla ni mò ńlọ,” tí ńfi koto ṣe àmù.

“Ọlá ò jẹ́ kí nríran”; ọmọ Èwí Adó tí ńtanná rìn lọ́sàn-án.

Ọ̀làjà ní ńfi orí gbọgbẹ́.

Ọlọ́dẹ kì í torí atẹ́gùn yìnbọn.

Ọlọ́gbọ́n bẹẹrẹ-ẹ́ pète ìgárá.

Ọmọ adìẹ-ẹ́ fò, a ní “Ẹrán lọ àkẹ́ẹ̀!”

Ọmọ inú ayò ò ṣé-é bá bínú.

Ọmọ orogún ẹ-ẹ́ kú, o ní ẹní rí ẹ lọ́run ò purọ́; bí tìẹ́ bá kú ńkọ́?

Ọmọdé bú ìrókò, ó bojú wẹ̀hìn; òòjọ́ ní ńjà?

Ọmọdé jí ti ojú orun wá, ó ní “Àkàrà kéjìkéjì”; wọ́n ti ḿmú u kẹ́ẹ̀ kó tó jí, ì ká ká níkẹ̀?

Ọmọrí odó pani lọ́tọ̀, ká tó wí pé ká kùn ún lóògùn.

Ọ̀mùtí ò mu agbè já.

Ọ̀nà ẹ̀bùrú dá ọwọ́ olúwa-a ẹ̀ tẹlẹ̀.

Ọ̀nà ìgbàlẹ̀ a máa já sọ́run.

Ọ̀nà là ńṣì mọ̀nà; bí a ò bá ṣubú, a kì í mọ ẹrù-ú dì.

Ọ̀nà ni yó mùú olè; ahéré ni yó mùú olóko.

Ọ̀nà ọ̀fun, ọ̀nà ọ̀run: méjèèjì bákannáà ni wọ́n rí.

Ọ̀pá àgbéléjìká, a-tẹ̀hìn-lójú.

Ọ̀pọ̀ oògùn ní ńru ọmọ gàle-gàle.

Ọ̀pọ̀lọ́ lejò ḿbùjẹ, tí à ńwí pé ilẹ̀-ẹ́ rorò?

Ọ̀ràn kì í yẹ̀ lórí alábaun.

Ọ̀ràn ńlá-ńlá ní ḿbá àpá; ọ̀ràn ṣẹ́kú-ṣẹ́kú ní ḿbá oṣè.

Ọ̀ràn ò dun gbọ̀ọ̀rọ̀; a dá a láàárọ̀, ó yọ lálẹ́.

Ọ̀ràn ọ̀gẹ̀dẹ̀ ò tó ohun tí à ńyọ àdá sí.

Ọ̀rọ̀ lọmọ etí ńjẹ.

Ọ̀rọ̀ ò pọ̀, àkàwé-e ẹ̀ ló pọ̀.

Ọ̀ràn ọkà-á ní ìba; ayé ní òṣùwọ̀n.

Ọ̀rọ̀ púpọ̀ ò kún agbọ̀n; irọ́ ní ḿmú wá.

Ọ̀rọ̀ tí a dì ní gbòdògì: bo déwée kókò yó fàya.

Ọ̀rọ̀ tí ò ní ohùn fífọ̀, dídákẹ́ ló yẹ ẹ́.

Ọ̀ṣọ́ oníbùjé ò pé isán; ọ̀ṣọ́ onínàbì ò ju ọdún lọ.

Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ là ńtẹ ẹrẹ̀; ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ là ńtẹ eruku.

Ọwọ́-ọ baba lẹ wò, ẹ ò wo ẹsẹ̀-ẹ baba.

Ọ̀wọ́n yúnlé, ọ̀pọ̀-ọ́ yúnjà.

.
PreviousContentsNext