Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 3: On cageyness, caution, moderation, patience, and prudence

O

O bá ẹfọ̀n lábàtà o yọ̀bẹ sí i; o mọ ibi ẹfọ̀n-ọ́n ti wa?

Ó dé ọwọ́ aláròóbọ̀ ó di níná.

Ó dé orí akáhín àkàràá deegun.

O kò rí àkàṣù ò ńpata sẹ́fọ̀ọ́.

O lọ sÍjẹ̀bú ẹ̀ẹ̀kan, o ru igbá àṣẹ bọ̀ wálé.

Ò ḿbá obínrin ẹ jà ò ńkanrí mọ́nú; o máa nà á lóògùn ni?

“Ó ḿbọ̀, ó ḿbọ̀!” ẹ̀wọ̀n là ńso sílẹ̀ dè é.

Ó ní ibi tí tanpẹ́pẹ́ ńgbèjà ẹyìn mọ.

Ó ní ohun tí àgbà-á jẹ tẹ́lẹ̀ ikùn kó tó sọ pé èyí yó òun.

Ó ní ohun tí àgbà-á jẹ tẹ́lẹ̀ ikùn kó tó sọ pé ìyà-á yó òun.

Ó ní ohun tí ìbòsí ràn nínú ìjà.

Ó pẹ́ títí aboyún, oṣù mẹ́sàn-án.

O rí àgbébọ̀ adìẹ lọ́jà ò ńta geere sí i; ìba ṣe rere olúwa rẹ̀ ò jẹ́ tà á.

O só pa mí mo pọ́nnu lá, o bojúwẹ̀hìn mo dọ̀bálẹ̀, o tiwọ́ bọ̀gbẹ́; o fẹ́ dè mí ni?

O ṣíwó nílé o kò san, o dóko o ńṣí ìkòkò ọ̀gẹ̀dẹ̀ wò, o bímọ o sọ ọ́ ní Adéṣínà; bí ṣíṣí ò bá sìn lẹ́hìn rẹ, o kì í sìn lẹ́hìn-in ṣíṣí?

O wà lọ́rùn ọ̀pẹ ò ḿbá Ọlọ́run ṣèlérí.

Obìnrin bẹẹrẹ òṣì bẹẹrẹ.

Obìnrin tó gégi nígbó Orò, ó gé àgémọ.

Òbò-ó ní ìtìjú ló mú òun sápamọ́ sábẹ́ inú, ṣùgbọ́n bí okó bá dé, òun á sínà fún un.

Odídẹrẹ ní wọn ò lè tí ojú òun yan òun mọ́ ẹbọ; bí wọ́n bá ńdÍfá, òun a sá wọlé.

Odídẹrẹ́ ńwolé hóró-hóró bí ẹnipé yó kòó sílé; àgbìgbò nọ̀wọ̀ràn ńwohò igi bí ẹnipé kò tibẹ̀ jáde.

Òfèèrèfé ò ṣé-é fẹ̀hín tì.

Ogun àgbọ́tẹ́lẹ̀ kì í pa arọ.

Ohun à ńjẹ là ńtà; bí epo òyìnbó kọ́.

Ohun gbogbo, ìwọn ló dùn mọ.

Ohun gbogbo kì í pẹ́ jọ olóhun lójú.

Ohun gbogbo kì í tó olè.

Ohun gbogbo là ńdiyelé; ṣùgbọ́n kò sẹ́ni tó moye ara-a ẹ̀; ẹ̀jẹ̀ ò fojú rere jáde.

Ohun tí a bá máa jẹ a kì í fi runmú.

Ohun tí à bá ṣe pẹ̀sẹ̀, ká má fi ṣe ìkánjú; bó pẹ́ títí ohun gbogbo a tó ọwọ́ ẹni.

Ohun tí a bá tẹjúmọ́ kì í jóná.

Ohun tí a fi ẹ̀sọ̀ mú kì í bàjẹ́; ohun tí a fagbára mú ní ńnini lára.

Ohun tí a fún ẹlẹ́mọ̀ṣọ́ ní ńṣọ́.

Ohun tí a ò pé yó dẹrù ní ńdiṣẹ́.

Ohun tí a rí la fi ḿbọ párá ẹni; bí igi tíná ḿbẹ lẹ́nu-u ẹ̀ kọ́.

Ohun tí ajá rí tó fi ńgbó ò tó èyí tí àgùntàn-án fi ńṣèran wò.

Ohun tó bá wu olókùnrùn ní ńpa á.

Ohun tó bá wu ọmọ-ọ́ jẹ kì í run ọmọ nínú.

Òjijì là ńrọ́mọ lọ́wọ́ alákẹdun.

Òjò kan kì í báni lábà ká jìjàdù ọ̀rọ̀-ọ́ sọ; bí ẹgbọ́n bá sọ tán, àbúrò á sọ.

Òjò ńrọ̀, orò ńké; atọ́kùn àlùgbè tí ò láṣọ méjì a ṣe ògèdèm̀gbé sùn.

Ojú abẹ ò ṣé-é pọ́nlá.

Ojú àwòdì kọ́ ladìẹ ńre àpáta.

Ojú ìmàle ò kúrò lọ́tí, ó bímọ ẹ̀ ó sọ ọ́ ní Ìmórù-máhá-wá.

Ojú ìmàle ò kúrò lọ́tí, ó bímọ ẹ̀ ó sọ ọ́ ní Lèmámù.

Ojú kan làdá ńní.

Ojú kan náà lèwe ńbágbà.

Ojú là ńgbó re ọ̀nà Ìbàdàn: ó fi ogún ọ̀kẹ́ gbàdí.

Ojú ní ńkán ọkọlóbìnrin; àlè méjì á jà dandan.

“Ojú ò fẹ́rakù” tó ta ajá-a ẹ̀ lókòó; ó ní bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ńtà á wọn a máa tún araa wọn rí.

Ojú ológbò lèkúté ò gbọdọ̀ yan.

Ojú tí kì í wo iná, tí kì í wo òòrùn; ojú tí ḿbáni dalẹ́ kọ́.

Ojú tí yóò bani kalẹ̀ kì í tàárọ̀ ṣepin.

Ojúkòkòrò baba ọ̀kánjúà.

Ojúlé ló bá wá; ẹ̀bùrú ló gbà lọ́; ó dÍfá fún àlejò tí ńfẹ obìnrin onílé.

Oókan ni wọ́n ńta ẹṣin lọ́run; ẹni tí yó lọ ò wọ́n; ṣùgbọ́n ẹni tí yó bọ̀ ló kù.

Oókan-án sọni dahuń eéjì-í sọni dàpà.

Òkèlè gbò-ǹ-gbò-ó fẹ ọmọ lójú toto.

Òkèlè kan ní ńpa àgbà.

Òkété tó bọ́ ìrù-ú mọ̀ pé ìpéjú ọjà ọrún òun ló sún.

Òketè baba ogun; bí a ṣígun, olúkúlùkù n í ńdi òketè-e ẹ̀ lọ́wọ́.

Òkìpa ajá la fi ḿbọ Ògún.

Òkò àbínújù kì í pẹyẹ.

Oko ni gbégbé ńgbé.

Òkò tí ẹyẹ́ bá rí kì í pẹyẹ.

Òkóbó ò lè fi alátọ̀sí ṣẹ̀sín.

Òkù àjànàkú là ńyọ ogbó sí; ta ní jẹ́ yọ agada séerin?

Okùn àgbò kì í gbèé dorí ìwo.

Olè kì í gbé gbẹ̀du.

Olóògbé ò jẹ́wọ́; atannijẹ bí orun.

Olójútì logun ńpa.

Olóòlà kì í kọ àfín.

Olórìṣà-á gbé ààjà sókè, wọ́n ní ire ni; bí ire ni, bí ibi ni, wọn ò mọ̀.

Omi là ńkọ́-ọ́ tẹ̀ ká tó tẹ iyanrìn.

Òní, adìẹẹ̀ mí ṣìwọ̀; ọ̀la, adìẹẹ̀ mí ṣìwọ̀; ọjọ́ kan la óò fẹ́ àìwọlé adìẹ kù.

Òní, baba-á dákú; ọ̀la, baba-á dákú; ọjọ́ kan ni ikú yóò dá baba.

Òní, ẹṣin-ín dá baba; ọ̀la, ẹṣin-ín dá baba; bí baba ò bá yé ẹṣin-ín gùn, ọjọ́ kan lẹṣin óò dá baba pa.

Onígbàjámọ̀ ńfárí fún ọ, ò ńfọwọ́ kàn án wò; èwo ló máa kù fún ọ níbẹ̀.

Onílé ńrelé wọ́n ní oǹdè ńsá; oǹdè ò sá, ilé ẹ̀ ló lọ.

Ònímónìí, ẹtu-ú jìnfìń ọ̀lamọ́la, ẹtu-ú jìnfìn; ẹran miìíràn ò sí nígbó ni?

Onínúfùfù ní ńwá oúnjẹ fún onínúwẹ́rẹ́wẹ́rẹ́.

Onísùúrù ní ńṣe ọkọ ọmọ Aláhúsá.

Oníṣu ní ḿmọ ibi iṣú gbé ta sí.

Ooré di ẹrẹ̀ lAwẹ́; àwọn igúnnugún ṣoore wọ́n pá lórí.

Oore ọ̀fẹ́ gùn jùwàásù.

Oore tí Agbe-é ṣe lỌ́fà, ó dagbe.

Oore tí igúnnugún ṣe tó fi pá lórí, tí àkàlá ṣe tó fi yọ gẹ̀gẹ̀, a kì í ṣe irú ẹ̀.

Oore-é pọ̀, a fìkà san án.

Òòrẹ̀ ní ńṣẹ́gi tí a ó fi wì í.

Orí ejò ò ṣé-é họ imú.

Orin ní ńṣíwájú ọ̀tẹ̀.

Orin tí a kọ lánàá, tí a ò sùn, tí a ò wo, a kì í tún jí kọ ọ́ láàárọ̀.

Òrìṣà kékeré ò ṣé-é há ní párá.

Òròmọ-adìẹ ò màwòdì; ìyá ẹ̀ ló màṣá.

Òṣé ní ńṣíwájú ẹkún; àbámọ̀ ní ńgbẹ̀hìn ọ̀ràn; gbogbo àgbà ìlú pé, wọn ò rí oògùn àbàmọ̀ ṣe.

Oúnjẹ tí a ó jẹ pẹ́, a kì í bu òkèlè-e ẹ̀ tóbi.

Owó ò bá olè gbé.

Òwúyẹ́; a-ṣòro-ó-sọ bí ọ̀rọ̀.

Oyún inú: a kì í kà á kún ọmọ-ọ tilẹ̀.

.
PreviousContentsNext