Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 3: On cageyness, caution, moderation, patience, and prudenceP
Pala-pálà kì í ṣe ẹran àjẹgbé; ẹ ṣáà máa mu àgúnmu.
Pápá tó ní òun ó jòó wọ odò, ọ̀rọ̀ ló fẹ́ẹ́ gbọ́.
Paramọ́lẹ̀-ẹ́ kọ ọ̀ràn àfojúdi.
Pẹ̀lẹ́-pẹ̀lẹ́ lejò-ó fi ńgun àgbọn.
Pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ ọ̀rọ̀, a-ta-síni-lára-má-wọ̀n-ọ́n.
Pípẹ́ ni yó pẹ̀ẹ́, agbọ̀n á bo adìẹ.
Pípẹ́ ni yó pẹ̀ẹ́, akólòlòá pe baba.
Pípẹ́ ni yó pẹ̀ẹ́, akọ̀pẹ yó wàá sílẹ̀.
Pípẹ́ ni yó pẹ̀ẹ́, amòòkùn yó jàáde nínú odò.
Pípẹ́ ni yó pẹ̀ẹ́, èké ò mú rá.
Pípẹ́ ni yó pẹ̀ẹ́, ẹní lọ sódò á bọ̀ wálé.
Pípẹ́ ni yó pẹ̀ẹ́, Ọ̀rúnmìlà yó jẹ àgbàdo dandan.
|
|||||||