Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 3: On cageyness, caution, moderation, patience, and prudenceN
“Ng óò wọ́ ọ kágbó,” ẹ̀hìn-in rẹ̀ ni yó fi lànà.
Nítorí ara ilé la ṣe ńdá ṣòkòtò ará oko dára.
Nítorí-i ká lè simi la ṣe ńṣe àì-simi.
Nítorí-i ká má jìyà la ṣe ńyá Májìyà lọ́fà.
Nítorí ọjọ́ tí ó bá máa dáràn la ṣe ńsọmọ lórúkọ.
Nítorí ọ̀la la ṣe ńṣòní lóore.
Nítorí ọlọgbọ́n la ṣe ńdá ẹ̀wù-u aṣiwèrè kanlẹ̀.
Nǹkan mẹ́ta la kì í pè ní kékeré: a kì í pe iná ní kékeré; a kì í pe ìjà ní kékeré; a kì í pe àìsàn ní kékeré.
|
|||||||