Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 3: On cageyness, caution, moderation, patience, and prudence

M

Má bà á loògùn ẹ̀tẹ̀.

Má bàá mi ṣeré tí kèrègbè-é fi gba okùn lọ́rùn.

Má fi iyán ewùrà gbọ́n mi lọ́bẹ̀ lọ sóko ẹgàn.

“Má fi okoò mi dá ọ̀nà,” ọjọ́ kan là ńkọ̀ ọ́.

“Má fi tìrẹ kọ́ mi lọ́rùn” là ńdá fún apèna àti òwú.

Má fìkánjú jayé, awo ilé Alárá; má fi wàà-wàà joyè, awo Òkè Ìjerò; ayé kan ḿbẹ lẹ́hìn, ó dùn bí ẹní ńlá oyin.

Màá jẹ iṣu, màá jẹ èrú, ibi ayo ló mọ.

Má ṣe jáfara: àfara fírí ló pa Bíálà; ara yíyá ló pa Abídogun.

Mábàjẹ́ ò jẹ́ fi aṣọ-ọ ẹ̀ fún ọ̀lẹ bora.

Méjì-i gbẹ̀du ò ṣé-é so kọ́.

“Méè-wáyé-ẹjọ́” fọmọ ẹ̀ fọ́kọ mẹ́fà. Méèwáyéẹjọ́

.
PreviousContentsNext