Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 3: On cageyness, caution, moderation, patience, and prudence

K

Kàkà kí ó sàn lára ìyá àjẹ́, ó fi gbogbo ọmọ bí obìnrin; ẹye ńgorí ẹyẹ.

Kàkà kí ọmọ ó bẹ̀bẹ̀ ọ̀ràn, òmíràn ni kò ní-í ṣe mọ́.

Kànìké tìtorí oókan kùngbẹ́.

Kékeré ejò, má foore ṣe é.

Kékeré la ti ńpa ẹkàn ìrókò; bó bá dàgbà ọwọ́ kì í ká a mọ́.

Kékerè nìmàle-é ti ńkọ ọmọ-ọ ẹ̀ lóṣòó.

Kèrègbè tí kò lọ́rùn ni yóò júwe bí àgbẹ̀ ó ti so òun kọ́.

Kèrègbè tó fọ́ a padà lẹ́hìn odò.

Kí a baà lè mọ̀ pé Wòrú pa awó, wọ́n ní “Káàbọ̀”; ó ní “Kẹnkẹn làpò.”

Kí a baà lè mọ̀ pé àjàpá ṣe ògbóni, wọ́n ní “Káàbọ̀”; ó ní “Awo àbí ọ̀gbẹ̀rì?”

Kí a máa re tábà ká máa wòkè, kọ́jọ́ tó kanrí ká wo oye ìka tí yó kù.

Kí á fọn fèrè, ká jámú sí-i, ọ̀kan yóò gbélẹ̀.

Kí á jìnnà séjò tí a ò bẹ́ lórí; ikú tí yó panni a jìnnà síni.

Kí á lé akátá jìnnà ká tó bá adìẹ wí.

Kí á siṣẹ́ ká lówó lọ́wọ́ ò dàbí-i ká mọ̀-ọ ná.

Kí á ta sílẹ̀ ká ta sẹ́nu, ká má jẹ̀ẹ́ kí tilẹ̀ pọ̀ ju ti inú igbá lọ.

Kí á tan iná pa agbọ́nrán, ká fọ̀pá gbọọrọ pejò, ká dìtùfù ká fi gbọ̀wẹ̀ lọ́wọ́-ọ Ṣàngó; ní ìṣojú-u Mádiyàn lagara-á ṣe ńdáni.

Kí á tó mọ̀ pé kíjìpá kì í ṣe awọ, ó di ọdún mẹ́ta.

Kì í bọ́ lọ́wọ́ èèyàn kó bọ́ sílẹ̀; ọwọ́ ẹlòmíràn ní ḿbọ́ sí.

Kì í ṣe ojú-u kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ladìẹ́ ti ńjẹ̀.

Kì í tán nígbá osùn kó má ba àlà jẹ́.

Kì í tètè yé oníbúrẹ́dì; ó dìgbà tó bá di mẹ́ta kọ́bọ̀.

Kì í tètè yéni: òwe ńlá ni.

Kí ni ó yá apárí lórí tó ńmòòkùn lódò?

Kí ni ológìní ńwá tó fi jóna mọ́le? Ṣòkòtò ló fẹ́ẹ́ mú ni, tàbí ẹrù ní ńdì?

Kí oníkálùkù rọra ṣe é; ìfẹjú òbò ò lè fa aṣọ ya.

Kìtì ò mọ́là; ká siṣẹ́ bí ẹrú ò da nǹkan.

Kò sí ajá tí kì í gbó; àgbójù ajá là ńpè ní dìgbòlugi.

Kò sí ìgbà tí a dá aṣọ tí a ó rílẹ̀ fi wọ́.

Kò sí ohun tí ńle tí kì í rọ̀.

Kò sí ohun tí sùúrù-ú sè tí kò jinná.

Kò sí ohun tó lọ sókè tí kò ní padà wá sílẹ̀.

Kò sí ohun tó yára pa ẹni bí ọ̀rọ̀ àsọjù.

Kòkòrò tó jẹ̀fọ́ jàre ẹ̀fọ́; ìwọ̀n lewéko ńdára mọ.

Kọ́kọ́rọ́ àṣejù, ilẹ̀kùn ẹ̀tẹ́ la fi ńṣí.

Kọkọ-kọkọ ò jẹ́ ká mọ ẹni tí ọ̀ràn ńdùn.

Kùkùté kan kì í fọ́ni lépo lẹ́ẹ̀mejì.

Kùn yún, kùn wá bí ikọ̀ eèrà.

.
PreviousContentsNext