Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 2: On perspicaciousness (good judgment, perceptiveness), reasonableness, sagacity, savoir-faire, wisdom, and worldly wisdomE
Ebi ńpa mí ọlọ́ṣẹ ńkiri; ìgbà tí ng ò wẹnú ng ó ṣe wẹ̀de?
Ebi ò pàJèṣà ó lóun ò jẹ̀kọ Ọ̀yọ́; ebí pa ọmọ Obòkun ó jẹ ori.
Ebi ò pàmọ̀le ó ní òun ò jẹ àáyá; ebí pa Súlè ó jọ̀bọ.
Eégún Ẹ̀gbá, Ẹ̀gbá ní ńfọ̀.
Eégún tí yó gbeni là ńdáṣọ fún; òrìṣà tí yó gbeni là ńsìn; bi igí bá gbè mí mà kó obì mà bọ igi.
Eégún tí yó ṣe bíi Lébé, Lébé ni yó dà; èyí tí yó tàkìtì bí Olúfolé, òfurugbàdà ni yó ta á.
Ejò-ó rí ihò tó há ó kó wọ̀ ọ́; ìyá-a rẹ̀-ẹ́ lọ́wọ́ àti fà á yọ?
Elékuru kì í kiri lóko.
Èló là ńra adìẹ òkókó, tí à ńgba ọmọ-ọ rẹ̀ sìn?
Èmi-ò-níí-fẹ́-obìnrin-tẹ́nìkan-ńfẹ́, olúwarẹ̀ ò níí fẹ́ obìnrin ni.
Èmi-ò-níí-ṣu-imí-le-imí, olúwarẹ̀ ó rìn jìnnà ààtàn.
Èpè la fi ńwo èpè sàn.
Epo ló ṣeé jẹṣu; àkàsọ̀ ló ṣeé gun àká; obìnrín dùn-ún bá sùn ju ọkùnrin lọ.
Epo lojú ọbẹ̀.
Eré là ńfọmọ ayò ṣe.
Èrò kì í mọ ibùsọ̀ kọ́rùn ó wọ̀ ọ́.
Ète lẹ̀gbọ́n; ìmọ̀ràn làbúrò; bí-a-ó-ti-ṣe lẹ̀kẹta wọn.
Ètò lòfin kìn-ín-ní lóde ọ̀run.
Ewúrẹ́ ò ṣe-e fiṣu ṣọ́.
Èyí tó yẹ ará iwájú, èrò ẹ̀hìn fiyè sílẹ̀.
|
|||||||