Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 2: On perspicaciousness (good judgment, perceptiveness), reasonableness, sagacity, savoir-faire, wisdom, and worldly wisdom

Edot

Ẹ̀bẹ̀ là ḿbẹ òṣìkà pé kó tún ìlú-u rẹ̀ ṣe.

Ẹbọ díẹ̀, oògùn díẹ̀, ní ńgba aláìkú là.

Ẹbọ ẹnìkan là ńfi ẹnìkan rú.

Ẹ̀fẹ̀-ẹ́ dẹ̀fẹ̀ iyán; a paláwẹ́ ẹ̀kọ baálé ilé ní ẹ̀ ńpèun bí?

Ẹ̀fẹ̀-ẹ́ dẹ̀fẹ̀ iyán; ò báà gbémi lulẹ̀ ng ó bàá ọ jẹun.

Ẹgbẹ́ ẹni kì í wọ́n láyé ká wá a lọ sọ́run.

Ẹjọ́ a-fẹ́ni-lóbìnrin là ńwí; a kì í wíjọ́ a-fẹ́ni-lọ́mọ.

Ẹ̀ẹ̀kan lejò ńyánni.

Ẹlẹ́nu-ú tóó rí sá.

Ẹlẹ́dẹ̀ẹ́ ní ọjọ́ tí òún ti jágbọ́n-ọn hùn, ọjọ́ náà ni ọ̀rọ̀ ò ti nìun lára mọ́.

Ẹlẹ́jọ́ ṣa èyí tó wù ú wí.

Ẹni a óò gbé òkú-u rẹ̀ sin, a kì í sọ pé ó ńrùn pani.

Ẹni a pé kó wáá wo kọ̀bì: ó ní kí nìyí kọ́bi-kọ̀bi?

Ẹni à ńwò kì í wòran.

Ẹni a wí fún ko gbọ́; ẹni a fọ̀ fún kó gbà; èyí tí ò gbọ́ yó filẹ̀ bora.

Ẹni àìgbọ́n pa ló pọ̀; ẹni ọgbọ́n pa ò tó ǹkan.

Ẹní bá ríkun nímú ọlọ́jà ní ńfọn ọ́n.

Ẹní bá tó ẹni-í gbà là ńké pè.

Ẹní du ara-a rẹ̀ lóyè Apènà: kó tó jẹ ẹran ọ̀fẹ́, ó dọ̀run.

Ẹní gbọ́n juni lọ ní ńtẹni nÍfá.

Ẹní léku méjì á pòfo.

Ẹní máa ké ìbòsí á pa baba rẹ̀ jẹ.

Ẹní rúbọ òrìṣà-á gbọ́dọ̀ rú ti èèyàn kí ẹbọ-ọ́ tó gbà.

Ẹni tí a bá fi orí-i rẹ̀ fọ́ àgbọn ò níí jẹ níbẹ̀.

Ẹni tí a bá ḿbá nájà là ńwò, a kì í wo ariwo ọjà.

Ẹni tí a wífún kó gbọ́; ẹni tí kò gbọ́, tara-a rẹ̀ ni yó dà.

Ẹni tí ẹ̀gún gún lẹ́sẹ̀ ní ńṣe lákáǹláká tẹ̀lé alábẹ́rẹ́.

Ẹni tí kò gbọ́n lààwẹ̀ ńgbò.

Ẹni tí kò mọ iṣẹ́-ẹ́ jẹ́ ní ńpààrà lẹ́ẹ̀mejì.

Ẹni tí kò mọ ọba ní ńfọba ṣeré.

Ẹni tí ó lè jà ni yóò kúnlẹ̀ kalẹ́.

Ẹni tí yó bọ Ògún, yó ra ọjà-a tirẹ̀ lọ́tọ̀.

Ẹni tí yó fò yó bẹ̀rẹ̀.

Ẹni tí yó mu ẹ̀kọ fòrò, yó bàá ọmọ ẹlẹ́kọ ṣeré.

Ẹni tí yó mu ẹ̀kọ ọ̀fẹ́ yó bàá ọmọ ẹlẹ́kọ ṣeré.

Ẹni tí yó ṣòwò àlè, ẹní-i rẹ̀ ní ńká; ẹni tí yó ṣòwò-o Ṣàngó, ààjà-a rẹ̀ ní ńrà.

Ẹni tí yó yàáni lówó, tí kò níí sinni, ohùn ẹnu-u rẹ̀ la ti ḿmọ̀.

Ẹni tó bá da omi síwájú á tẹ ilẹ̀ tútù.

Ẹni tó bá fi ojù àná wòkú, ẹbọra a bọ́ ọ láṣọ.

Ẹni tó bá máa jẹ ọ̀pọ̀lọ́ a jẹ èyí tó lẹ́yin.

Ẹni tó bá máa lu òṣùgbó a lu ńlá; kékeré ẹgbẹ̀fà, ńlá ẹgbẹ̀fà.

Ẹni tó bá máa mú ọ̀bọ a ṣe bí ọ̀bọ.

Ẹni tó bá mọ ìdí ọ̀ràn tẹ́lẹ̀ ní ḿbu àbùjá èké.

Ẹni tó bá ní igbà-á lò, bí igbà-á bá já, kó dúró so ó.

Ẹni tó bá pẹ́ lórí imí, eṣinṣin kéṣinṣin yó ò bá a níbẹ̀.

Ẹni tó bá rántí Efuji, kó má fi ore ṣe ẹṣin.

Ẹni tó bá rántí ọjọ́ ní ńṣe ọmọ òkú pẹ̀lẹ́; ta ní jẹ́ ṣe ọmọ eégún lóore?

Ẹni tó bá sọ pé ẹsẹ̀ eégún ńhàn ní ńwá abẹ́rẹ́ lọ.

Ẹni tó bá yá ìwọ̀fà ẹgbàá, tòun tirẹ̀ ní ńlọ ata kúnná.

Ẹni tó dùbúlẹ̀-ẹ́ ṣe oògùn ìjàkadì tán.

Ẹni tó fi irun dúdú ṣeré, yó fi funfun sin ẹniẹlẹ́ni.

Ẹni tó fi owó-o rẹ̀ ra ẹṣin, kò níí jẹ́ kó ṣe àrìnjẹ́.

Ẹni tó gbajúmọ̀ tí kò mọ èèyàn-án kí, òun òbúrẹ́wà ẹgbẹ́ra.

Ẹni tó máa tẹ́ òkú ọ̀pọ̀lọ́, yó nìí ilé ògbóni tirẹ̀ lọ́tọ̀.

Ẹni tó máa yáni lẹ́wù, ti ọrùn-un rẹ̀ là ńwò.

Ẹni tó mi kùkùté, araa rẹ̀ ní ńmì.

Ẹni tó mọ ẹtu ní ńkì í ní “òbèjé, ẹlẹ́sẹ̀ ọwọ̀.”

Ẹni tó ńṣápẹ́ fún wèrè jó, òun àti wèrè ọ̀kan-ùn.

Ẹni tó pa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yó ru káyá ẹrù.

Ẹni tó ránṣẹ́ sí orò-ó bẹ̀wẹ̀ fún àìsùn.

Ẹni tó re Ìbàdán tí kò dé ilé Olúyọ̀lé, oko igi ló lọ.

Ẹni tó rúbọ tí kò gba èèwọ̀, bí ẹni tó fi owó ẹbọ ṣòfò ni.

Ẹni tó sọ ẹlẹ́dẹ̀ lékùrọ́, oúnjẹ ló fún un.

Ẹni tó torí òtútù fi ọmọrí odó yáná ò gbọdọ̀ retí a-ti-jẹyán.

Ẹnu àìmẹ́nu, ètè àìmétè, ní ḿmú ọ̀ràn bá ẹ̀rẹ̀kẹ́.

Ẹnu ehoro ò gba ìjánu.

Ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ilé ẹ̀rín.

Ẹ̀rù bíbà ní ḿmúni pe àjẹ́ ní ará ire.

Ẹrù-u hòo kì í wọni lọ́rùn.

Ẹ̀sín alátọ̀sí ò sí lọ́wọ́ òkóbó.

Ẹyẹ igbó kì í mọ fífò ọ̀dàn.

Ẹyẹ ńwá àtifò, wọ́ ńsọ òkò sí i.

.
PreviousContentsNext