Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 2: On perspicaciousness (good judgment, perceptiveness), reasonableness, sagacity, savoir-faire, wisdom, and worldly wisdomB
Baba-ìsìnkú ò fọmọ-ọ rẹ̀ sọfà; alábàáṣe ńfọmọ-ọ rẹ̀ kówó.
Baálé àìlọ́wọ̀ ni àlejò àìlọ́wọ̀.
Baálẹ̀ àgbẹ̀-ẹ́ ní òun ò ní nǹkan-án tà lọ́run, kí owó ọkà òún ṣáà ti pé.
“Báyìí là ńṣe” níbìkan, èèwọ̀ ibòmínìn.
Bí a bá bá aṣiwèrè gbé, a ó gba odì ọlọgbọ́n; bí a bá bá ewé iyá ṣọ̀tẹ̀, a ó ṣẹ ẹlẹ́kọ.
Bí a bá bá ẹrán wí, ká bá ẹràn wí.
Bí a bá fi ọwọ́ ọ̀tún na ọmọ, à fi ọwọ́ òsì fà á mọ́ra.
Bí a bá jẹ̀wọ́ tán ẹ̀rín là ńrín; bí a bá yó tán orun ní ńkunni.
Bí a bá kìlọ̀ fólè, ká kìlọ̀ fóníṣu ẹ̀bá ọ̀nà.
Bí a bá ní mọ̀, ọ̀mọ̀ràn a mọ̀ ọ́.
Bí a bá ńsunkún, à máa ríran.
Bí a bá ránni níṣẹ́ ẹrú, à fi jẹ́ tọmọ.
Bí a bá rántí ọjọ́ kan ìbálé, ká rántí ọjọ́ kan ìkúnlẹ̀ abiyamọ, ká rántí kan abẹ́ tí ńtani lára.
Bí a bá rí èké, à ṣebíèèyàn rere ni; à sọ̀rọ̀ ságbọ̀n a jò.
Bí a bá rí òwúrọ̀, alẹ́ ńkọ́?
Bí a bá sọ̀rọ̀ tán, ẹrín là ńrín; bí a bá yó tán orun ní ńkunni.
Bí a bá ṣe ohun ńlá, à fi èpè gba ara ẹni là.
Bí a bá ta ará ilé ẹni lọ́pọ̀, a kì í rí i rà lọ́wọ̀n-ọ́n mọ́.
Bí a kò bá gbé ọ̀pọ̀lọ́ sọ sínú omi gbígbóná, ká tún gbé e sọ sí tútù, kì í mọ èyí tó sàn.
Bí a kò bá gbọ́n ju àparò oko ẹni lọ, a kì í pa á.
Bí a kò bá rádànán, à fòòbẹ̀ ṣẹbọ.
Bí a kò bá rígún a ò gbọdọ̀ ṣebọ; bí a ò bá rí àkàlà a ò gbọdọ̀ ṣorò.
Bí a kò bá torí iṣu jẹ epo, à torí epo jẹṣu.
Bí a kò bímọ rí, a kò ha rọ́mọ lẹ́hìn adìẹ?
Bí a kò ránni sọ́jà, ọjà kì í ránni sílé.
Bí a kò ṣe ọdẹ rí, a kò lè mọ ẹsẹ̀-ẹ kò-lọ-ibẹ̀un.
Bí alẹ́ bá lẹ́, à fi ọmọ ayò fún ayò.
Bí alẹ́ bá lẹ́, bọnnọ-bọ́nnọ́ a rẹ̀wẹ̀sì.
Bí alẹ́ kò lẹ́, òòbẹ̀ kì í fò.
Bí apá ò ká àràbà, apá lè ká egbò ìdí-i rẹ̀.
Bí àrùn búburú bá wọ̀lú, oògùn búburú la fi ńwò ó.
Bí eégún ó bàá wọlẹ̀, orò ni ńṣe.
Bí eré bí eré, àlàbọrùn-ún dẹ̀wù.
Bí ẹlẹ́rẹ̀kẹ́ régérégé bá ro ẹjọ́-ọ tirẹ̀ tán, kó rántí pé ẹlẹ́rẹ̀kẹ́ mẹ́kí á rí rò.
Bí igí bá wó lu igi, tòkè là ńkọ́ gbé.
Bí ikún bá jẹ, bí ikún bá mu, ikún a wo oòrùn alẹ́.
Bí ilẹ̀-ẹ́ bá laná, ọ̀pọ̀lọ́ á fò gun igi.
Bí ilú bá dá sí méjì, tọba ọ̀rún là ńṣe.
Bí iṣẹ́ kò pẹ́ ẹni, a kì í pẹ́ iṣẹ́.
Bí kò bá tíì rẹ ìjà, a kì í là á.
Bí kókó bá dáni, a kì í jẹ orí ìmàdò; bí a bá jẹ orí ìmàdò, a kì í lọ sí àwùjọ póńpó; bí a bá lọ sí àwùjọ póńpó, ìwọ̀n ara ẹni là ńmọ̀.
Bí nǹkán bá tán nílẹ̀, ọmọ ẹbọ a bọ́ síjó, àwọn tó wà níbẹ̀ a múra àti lọ.
Bí o bá já ng ó so ọ́, kókó yó wà láàárín-in rẹ̀.
Bí o kò gbọ́ Ègùn, o kò gbọ́ wọ̀yọ̀-wọ̀yọ̀?
Bí o máa ṣe aya Olúgbọ́n ṣe aya Olúgbọ́n; bí o máa ṣe aya Arẹsà ṣe aya Arẹsà, kí o yéé pákọ̀kọ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri; ẹni tí yó ṣe aya Olúfẹ̀ a kógbá wálé.
Bí obìnrin ò bá gbé ilé tó méjì, kì í mọ èyí tó sàn.
Bí ojú bá mọ́, olówò a gbówò; ọ̀rànwú a gbé kẹ́kẹ́; ajagun a gbé apata; àgbẹ̀ a jí tòun tòrúkọ́; ọmọ ọdẹ a jí tapó tọrán; ajíwẹṣẹ a bá odò omi lọ.
Bí ojú bá rí ọ̀rọ̀, a wò ó fín.
Bí ojú ọmọdé ò tó ìtàn, a bá àwígbọ́.
Bí olósùn-ún bá lọ osùn, ara-a rẹ̀ ní ńfi dánwò.
Bí òrìṣá bá mú ẹlẹ́hìn, kí abuké máa múra sílẹ̀.
Bí òwe bí òwe là ńlùlù ògìdìgbó; olọgbọ́n ní ńjó o; ọ̀mọ̀ràn ní ńsìí mọ̀ọ́.
Bí òwe bí òwe nIfá ńsọ̀rọ̀.
Bí ọ̀bùn ò mọ èrè, a mọ ojú owó.
Bí ọkùnrín réjò, tóbìrín pa á, à ní kéjò má ṣáà lọ.
Bí Ọlọ́run-ún bá ti fọ̀tá ẹni hanni, kò lè pani mọ́.
Bí ọlọgbọ́n bá ńfi wèrè se iṣu, ọ̀mọ̀ràn a máa fi gègé yàn án.
Bí ọmọ́ bá jágbọ́n-ọn kíké, ìyá-a rẹ̀ a jágbọ́n-ọn rírẹ̀ ẹ́.
Bí ọmọ́ bá jágbọ́n-ọn kíkú, ìyá ẹ̀ a jágbọ́n-ọn sísin.
Bí ọmọ́ bá yó, a fikùn han baba.
Bí ọmọdé bá dúpẹ́ ore àná, a rí tòní gbà.
Bí ọmọdé bá ḿbẹ́ igi, àgbàlagbà a máa wo ibi tí yó wòó sí.
Bí ọmọdé bá mọ ayò, ẹyọ la ó fi pa á.
Bí ọmọdé bá ṣubú a wo iwájú; bí àgbá bá ṣubú a wo ẹ̀hìn.
Bí ọmọdé ò bá rí oko baba ẹlòmíràn, a ní kò sí oko baba ẹni tó tó ti baba òun.
Bí ọmọdé kọ iyán àná, ìtàn la ó pa fún un.
Bí ọ̀rán bá pẹ́ nílẹ̀, gbígbọ́n ní ńgbọ́n.
Bí ọwọ́ ò bá ṣeé ṣán, à ká a lérí.
Bí sòbìyà yó bàá degbò, olúgambe là á wí fún.
Bí túlàsí bá di méjì, ọ̀kan là ḿmú.
“Bùn mi níṣu kan” kì í ṣáájú “Ẹkú oko òo.”
|
|||||||