Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 2: On perspicaciousness (good judgment, perceptiveness), reasonableness, sagacity, savoir-faire, wisdom, and worldly wisdomA
A bímọ kò gbọ́n, a ní kó má ṣàá kú; kí ní ńpa ọmọ bí àìgbọ́n?
A dẹ́bọ fún igúnnugún, ó ní òun kò rú; a dẹ́bọ fún àkàlà, ó ní òun kò rú; a dẹ́bọ fún ẹyẹlé, ẹyẹlé gbẹ́bọ, ó rúbọ.
A fọwọ́ mú ajá o lọ, a ṣẹ̀ṣẹ̀ ńfi ìka méjì pè é.
A fún ọ lọ́bẹ̀ o tami si; o gbọ́n ju ọlọ́bẹ̀ lọ.
A kì í bọ́ sínú omi tán ká máa sá fún òtútù.
A kì í dá aró nÍṣokùń àlà là ńlò.
A kì í dá ẹrù ikùn pa orí.
A kì í du orí olórí kí àwòdì gbé tẹni lọ.
A kì í duni lóyè ká fọ̀nà ilé-e Baálẹ̀ hanni.
A kì í fá orí lẹ́hìn olórí.
A kì í fi àgbà sílẹ̀ sin àgbà.
A kì í fi àì-mọ̀-wẹ̀ mòòkùn.
A kì í fi ara ẹni ṣe oògun alọ̀kúnná.
A kì í fi aṣọ ṣèdìdí yọwó.
A kì í fi ejò sórí òrùlé sùn.
A kì í fi ẹ̀jẹ̀ ìbálé pa tírà; alákoto ò bí abo ọmọ.
A kì í fi ẹ̀tẹ̀ sílẹ̀ pa làpálàpá.
A kì í fi ẹran ikún gbọn ti àgbọ̀nrín nù.
A kì í fi idà pa ìgbín.
A kì í fi ìgbín sọ̀kò sórìṣà.
A kì í fi iná sórí òrùlé sùn.
A kì í fi ìtìjú kárùn.
A kì í fi ìyá ẹní dákú ṣeré.
A kì í fi ogun dán ẹ̀ṣọ́ wò.
A kì í fi ohun sọ́wọ́ búra.
A kì í fi ohun-olóhun tọrẹ bí kò ṣe tẹni.
A kì í fi oko sin fún ìwọ̀fà.
A kì í fi olórí ogun ṣe ìfagun.
A kì í fi oníjà sílẹ̀ ká gbájúmọ́ alápẹpẹ.
A kì í fi owó du oyè-e alágbára.
A kì í fi ọlá jẹ iyọ̀.
A kì í fi ọ̀nà ikùn han ọ̀fun.
A kì í fi ọ̀nà odò han ikún.
A kì í fi ọ̀rọ̀ sílẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀.
A kì í gbá ẹni tó yọ̀bẹ mú.
A kì í gbé ẹran erin lérí ká máa fẹsẹ̀ wa ihò ìrẹ̀.
A kì í gbé odò jiyàn-an ọṣẹ́ hó tàbí kò hó.
A kì í gbé ọ̀pọ̀lọ́ sọnù ká tún bèrè-e jàǹto.
A kì í gbẹ́ àwòrán gàgàrà ká má fi ọwọ́ ẹ ti nǹkan.
A kì í gbójú-u fífò lé adìẹ àgàgà; a kì í gbójú-u yíyan lé alágẹmọ.
A kì í gbọ́ ẹjọ́ẹnìkan dájọ́.
A kì í jẹ “Mo fẹ́rẹ̀-ẹ́” lọ́bẹ̀.
A kì í ka igún mọ́ ẹran jíjẹ.
A kì í ka ilé òrìṣà kún ìlú.
A kì í ka oyún inú kún ọmọ ilẹ̀.
A kì í ka ọmọ fún òbí.
A kì í kọ ọmọ-ọ́ bí ká sọ ọ́ ní Èwolódé?
A kì í léku méjì ká má pòfo.
A kì í lọ́mọ lẹ́hin kọ oúnjẹ.
A kì í mọ ọkọ ọmọ ká tún mọàlè-e rẹ̀.
A kì í mú ìbọn tetere.
A kì í mú oko mú ẹjọ́ kí ọ̀kan má yẹ̀.
A kì í mú ọmọ oǹdọ́pọ̀ dè.
A kì í mú ọmọ òṣì lọ sí Ìlọ́rọ̀.
A kì í múlé móko kọ́kan má yẹ̀.
A kì í ní ẹgbàá nílé wá ẹgbàá ròde.
A kì í pa asínwín ilé, nítorí ọjọ́ tí tòde yó bàá wá sílé.
A kì í pa igún, a kì í jẹ igún, a kì í fi igún bọrí.
A kì í pé kí òṣìkà ṣe é ká wò ó.
A kì í peni lólè ká máa gbé ọmọ ẹran jó.
A kì í rán ọ̀lẹ wo ojú ọjọ́ àárọ̀.
A kì í re nísun lọ dà síbú.
A kì í rí adìẹ nílẹ̀ ká da àgbàdo fún ajá.
A kì í rí àjẹkù orò.
A kì í rí bàtá nílẹ̀ ká fẹnu sín in jẹ.
A kì í rí ewé nílẹ̀ ká fọwọ́ fámí.
A kì í rí ẹ́ni ranni lẹ́rù ká yọké.
A kì í rí ojú ẹkùn ká tọ́ ẹkùn.
A kì í sá fún àjíà ká dìgbò lu eégún.
A kì í sin àlè kọjá odò; ohun tí ńṣe ọṣẹ́ ò tó ǹkan.
A kì í sọ pé abẹ Ọ̀yọ́ mú; nígbà náà ni yó sọ pé bẹ́ẹ̀ ni òun ò tíì pọn.
A kì í sọrọ ìkọ̀kọ̀ lójú olófòófó.
A kì í sùn jẹ́rìí ìdí.
A kì í ṣe fáàárí ẹ̀ṣẹ́ dídì sọ́mọ adẹ́tẹ̀.
A kì í ṣe fáàárí itọ́ dídà sọ́mọ a-kú-wárápá.
A kì í ṣoore tán ká lóṣòó tì í.
A kì í ṣòwò méjì kẹ́ran má jẹ ọ̀kan.
A kì í ti ojú ogun wẹ́fọ́n.
A kì í ti ojú on-íka-mẹ́sàn-án kà á.
A kì í tijú bá baálé ilé jẹ akátá; bó bá mú, ìwọ náà a mú tìẹ.
A kì í wá aláṣọ-àlà nísọ̀ elépo.
A kì í wà nínú ìṣẹ́ ká perin tọrẹ.
A kì í wíjọ́ọ wíwò ká jàre.
A kì í yin ọmọdé lójú ara ẹ̀; ìfàsẹ́hìn ní ńkángun ẹ̀.
A kúnlẹ̀ a pàgbò, alubàtá ní “ojú ò fẹ́rakù”; o fẹ́ bá wọn ṣúpó ni?
A lé tẹ̀m̀bẹ̀lẹ̀kun jìnnà bí ẹnipé kó bọ́ jù sígbó.
À nfọ̀tún tẹ́ní, à ńfòsì tú ṣòkòtò, obìnrín ní a kò bá òun gbọ́ tọmọ.
À ńgba òròmọ adìẹ lọ́wọ́ ikú, ó ní wọn ò jẹ́ kí òun jẹ̀ láàtàn.
À ńgbèjà Ọ̀jà, Ọ̀já ní ta ní ńjà lẹ́hìnkùlé òun?
A ní ìrókò ni yó pa ọmọdé, ó bojú-wẹ̀hìn; òòjọ́ ní ńjà?
A ní kí olókùnrùn ṣe tó, ó ní òun ò lè ṣe tó, tò, tó.
A ní kọ́mọ má kùú, o ní kò jọ bàbá kò jọ ìyá.
“À ńjùwọ́n” ò ṣéé wí lẹ́jọ́; ìjà ìlara ò tán bọ̀rọ̀.
À ńkì í, à ńsà á, ó ní òun ò mọ ẹni tó kú; a ní, “Alákàá ẹgbàá, a-biṣu-wọ̀rọ̀-wọ̀rọ̀-lóko, a-bàgbàdo-tàkì-tàkì-lẹ́gàn”; ó ní, “Ọlọ́dẹ ló kú, tàbí ìnájà?”
À ńkì í, à ńsà á, ó ní òun ò mọ ẹni tó kú; ó ńgbọ́, “Ikú mẹ́rù, Ọ̀pàgá, a-biṣu-ú-ta-bí-òdòdó, a-lábà-ọkà, a-roko-fẹ́yẹ-jẹ”; ó ní, “Àgbẹ̀ ló kú, tàbí ọ̀nájà?”
À ńsọ̀rọ̀ elégédé, obìnrín ḿbèrè ohun tí à ńsọ, a ní ọ̀rọ̀ ọkùnrin ni; bí a bá kó elégédé jọ, ta ni yó sè é?
À ńsọ̀rọ̀ obìnrin, a ní ká sọ́ bàrà ká lọ gbin bàrà sódò; ta ní máa báni pa á?
A rí i lójú, a mọ̀ ọ́ lẹ́nu; òṣòwò oṣẹ kì í pọ́n-wọ́-lá.
A ta bàbà, a fowó-o bàbà ra baba.
A ta bàbà a fowó-o bàbà ra bàbà.
Àbá alágẹmọ lòrìṣà ńgbà.
Àbá kì í di òtítọ́; ojo ni kì í jẹ́ ká dá a.
Àbá ní ńdi òtítọ́; ojo ni kì í jẹ́ ká da.
Àbàtì àlàpà; a bà á tì, a bá a rẹ́.
A-bayé-jẹ́ kò ṣéé fìdí ọ̀ràn hàn.
Abẹ́rẹ́ ò ṣéé gúnyán.
Abẹ́rẹ́ tó wọnú òkun ò ṣéé wá.
Abiyamọ, kàgbo wàrà; ọjọ́ ńlọ.
Abiyamọ kì í rìn kó ṣánwọ́ ahá.
Abiyamọ́ purọ́ mọ́mọ-ọ rẹ̀ jẹun.
Abiyamọ́ ṣọwọ́ kòtò lu ọmọ-ọ rẹ̀.
Àbọ̀ṣẹ́ kì í ṣe iṣẹ́ òòjọ́; iṣẹ́-ẹ baba ẹni ní ńgbani lọ́jọ́ gan-an.
Àbùkún layé gbà.
Adánilóró fagbára kọ́ni.
Adẹ́tẹ̀ ò gbọdọ̀ dúró de eléépín.
Adẹ́tẹ̀-ẹ́ ní òún sẹ́ ọ̀ràn kan de àwọn ará ilé òun; ó ní bí òún bá lọ sídàálẹ̀, wọn ò jẹ́ fi kàn-ìn-kàn-ìn òun wẹ̀.
Adìẹ ìrànà ní ńṣíwájú òkú.
Adìẹ ò lè ti ìwòyí sunkún ehín.
Adìẹ ò lórúnkún ẹjọ́.
Adìẹ́ rí aláásáà, ó pa ìyẹ́ mọ́.
Adìẹ-odò ò ṣéé bọ ìpọ̀nrí.
Àdó gba ara ẹ̀ tẹ́lẹ̀, ká tó fi oògùn sí?
A-fàtẹ́lẹwọ́-fanná kì í dúró.
A-fasẹ́-gbèjò ńtan ara-a rẹ̀ jẹ.
Afẹ́fẹ́ ńda ológìì láàmú; oníyẹ̀fun rọra.
Àfẹ́ẹ̀rí kan ò ju ká rí igbó ńlá bọ́ sí lọ; ẹbọ kan ò ju ọ̀pọ̀ èèyàn lọ; “Òrìṣá gbé mi lé àtète” kan ò ju orí ẹṣin lọ.
A-fi-tiẹ̀-sílẹ̀-gbọ́-tẹni-ẹlẹ́ni, ọ̀gànjọ́ ni wọ́n ńsìnkú-u rẹ̀.
Àfòmọ́ ńṣe ara-a rẹ̀, ó ní òún ńṣe igi.
Àgádágodo ò finú han ara-a wọn.
Àgùntàn ò jí ní kùtùkùyù ṣe ẹnu bọbọ.
Àgbà òṣìkà ńgbin ìyà sílẹ̀ de ọmọọ rẹ̀.
Àgbà ṣoore má wo bẹ̀.
À-gbà-bọ́ ò di tẹni.
Àgbàdo kì í ṣe èèyàn;ta ní ńrí ọmọ lẹ́hìn eèsún?
Àgbàká labiyamọ ńgbàjá mọ́ ọmọ-ọ rẹ̀.
337. Àgbàlagbàá ṣenú kẹrẹndẹn; èyí tó máa ṣe ḿbẹ níkùn-un rẹ̀.
A-gbé-ọ̀ọ̀dẹ̀ bí òfé, a-mọ-ara-í-ré bí oódẹ;a dẹ́bọ fún òfé, òfé ò rú, agánrán gbẹ́bọ, ó rúbọ; àsẹ̀hìnwá àsẹ̀hìnbọ̀ òfé di ará Ọ̀yọ́, agánrán di ará oko; wọ́n rò pé òfé ò gbọ́n.
Àgbẹ̀jẹ ò korò nílé ńlá.
Àgbìgbò, rọra fò, ọdẹ́ ti dé sóko; àgbìgbò tí ò bá rọra fò á bọ́ sápò ọdẹ.
Àgbò dúdú kọjá odò ó di funfun.
Àgbókan là ńrọ́ Ifá adití.
Àgbọn kì í ṣe oúnjẹ ẹyẹ.
Ahún dùn;kò tóó jẹ fúnni.
Ahún ńre àjò, ó gbé ilé-e rẹ̀ dání.
Ahun-ún wọnú orù, ó ku àtiyọ.
Àìgbọ́n ni yó pa Iṣikan; a ní ìyáa rẹ̀-ẹ́ kú, ó ní nígbàtí òún gbọ́, ṣe ni òún ńdárò; bíyàá ẹní bá kú àárò là ńdá?
Àì-gbọ́n-léwe ni à-dàgbà-di-wèrè.
Àì-mọ̀-ọ́-gbé-kalẹ̀ leégún fi ńgba ọtí.
Àì-mọwọ́-ọ́-wẹ̀ ni àì-bágbà-jẹ; ọmọ tó mọwọ́-ọ́ wẹ̀ á bágbà jẹ.
Àìpé, “Tìrẹ nìyí” ní ḿbí ayé nínú.
Àì-roko, àì-rodò tí ńṣápẹ́ fún eégún jó.
Àì-sọ̀rọ̀ ní ńmú ẹnu rùn.
Ajá èṣín ò mọdẹ.
Ajá là bá kí; èse ò pẹran fúnni jẹ.
Ajá tí ò létí ò ṣé-é dẹ̀gbẹ́.
Ajá ti eré-e rẹ̀ẹ́ bá dánilójú là ńdẹ sí ehoro.
Ajá tó gbé iyọ̀, kí ni yó fi ṣe?
Ajá tó lè sáré là ńdẹ sí egbin.
Ajàkàṣù ò mọ̀ bí ìyàn-án mú.
A-jí-má-bọ̀ọ́jú, tí ńfi ojú àná wòran.
Àjànàkú kúrò lẹ́ran à ńgọ dé.
Àjànàkú ò ṣéé rù.
Àjàpá ní kò sí oun tó dà bí oun tí a mọ̀ ọ́ṣe; ó ní bí òún bá ńrìn lóko ẹ̀pà, ọ̀kọ̀ọ̀kan a máa bọ́ sóun lẹ́nu.
Àjàpá ní ọjọ́ tí òún ti jágbọ́n-ọn òo lọrùn ò ti wọ òun mọ́.
Àjàpá ńyan lóko, aláìlóye-é ní ó jọ pẹ́pẹ́yẹ.
Àjẹ́gbà ni ti kọ̀ǹkọ̀.
Àjẹ́kù là ńmayo.
Àjẹkù làgbẹ̀ ńtà.
Àjẹsílẹ̀-ẹ gbèsè tí ò jẹ́ kí ẹgbẹ̀fà tóó ná.
Àjímú kì í tí.
Àjò kì í dùn kódídẹ má rèWó.
Àjò kì í dùn kónílé má relé.
Àjòjí lójú, ṣùgbọ́n kò fi ríran.
À-jókòó-àì-fẹ̀hìntì, bí ẹní nàró ni.
Àkámọ́ ẹkùn-ún níyọnu.
Àkísà aṣọ la fi ńṣe òṣùká.
Àkó balẹ̀, ó fi gbogbo ara kígbe.
A-ká-ìgbá-tà-á náwó ikú.
Akọ̀pẹ Ìjàyè ò gbọ́ tiẹ̀, ó ní ogún kó Agboroode.
Aláàjàá gbé e sókè, o ní, “Kó ṣẹ!”; o mọ̀ bí ibi lówí tàbí ire?
Alágbàfọ̀ kì í bá odò ṣọ̀tá.
Alákatam̀pòó ṣe bí ọ̀bọ ò gbọ́n; ọ̀bọ́ gbọ́n; tinú ọ̀bọ lọ̀bọ́ ńṣe.
Alákìísà ní ńtọ́jú abẹ́rẹ́ tòun tòwú.
Aláǹtakùn, bí yóò bá ọ jà, a ta ká ọ lára.
Aláǹtakùnún takùn sí ìṣasùn, ṣíbí gbọludé.
Aláàárù kì í ru ẹṣin.
Aláṣedànù tí ńfajá ṣọdẹ ẹja.
Àlejò bí òkété là ńfi èkùrọ́ lọ̀.
Àlejò tó bèèrè ọ̀nà kò níí sọnù.
Àlùkò ò ní ohùn méjì; “Ó dilé” lagbe ńké.
Àlùsì ẹsẹ̀ tí ńfa koríko wọ̀lú.
Amọ̀nà èṣí kì í ṣe amọ̀nà ọdúnnìí.
Amọ̀rànbini Ọ̀yọ́, bí o bá gbé kete lérí, wọn a ní oko lò ńlọ tàbí odò.
Amùṣùà àgbẹ̀ tí ńgbin kókò.
Àpà èèyàn ò mọ̀ pé ohun tó pọ̀-ọ́ lè tán.
Àpà-á fi ọwọ́ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá bọ ẹnu; àpà, a-bìjẹun-wọ̀mù-wọ̀mù.
Apajájẹẹ́ ní ẹ̀rù adìẹ ḿba òun.
Àpàkòmọ̀rà, tí ńgẹṣin lórí àpáta.
A-pẹ́-ẹ́-jẹ kì í jẹ ìbàjẹ́.
Àpèmọ́ra là ńpe Tèmídire.
Àpọ́n dògí ó ṣàrò.
Ara ẹ̀ lara ẹ̀: ṣòkòtò ọlọ́pàá.
Ara kì í rọni ká ṣẹ́gi ta.
Ara kì í tu ẹni káká, kí ara ó roni koko, ká má leè jíkàkà dÍfá.
Ará ọ̀run ò ṣẹ́tí aṣọ.
Ààrẹ ńpè ọ́ ò ńdÍfá; bÍfá bá fọọre tí Ààrẹ́ fọbi ńkọ́?
A-rìn-fàà-lójú-akẹ́gàn, a-yan-kàṣà-lojú-abúni, abúni ò lówó nílé ju ẹnu-u rẹ̀ lọ.
Arìngbẹ̀rẹ̀ ni yó mùú oyè délé; asárétete ò róyè jẹ.
À-ró-kanlẹ̀ laṣọ ayaba; à-wà-kanlẹ̀ ni ti yàrà.
Arúgbó oǹdágbèsè, ó ní mélòó ni òun óò dúró san níbẹ̀?
A-sáré-lówó ḿbẹ lọ́nà ogun; A-pọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ḿbẹ lọ́nà èrò; Bó-pẹ́-títí-ng-ó-là ḿbẹ lábà, ó ńjẹ ẹ̀sun iṣu.
À-sìnkú-àì-jogún, òṣì ní ńtani.
Asínwín ní òun ó ti iná bọlé; wọ́n ní kó má ti iná bọlé; ó ní òun ó sáà ti iná bọlé; wọ́n ní bó bá tiná bọlé àwọn ó sọ ọ́ si; ó ní ìyẹn kẹ̀ ìkan.
A-sọ̀kò-sádìẹ-igba, òkò ní ńsọ tí ilẹ̀-ẹ́ fi ńṣú.
A-sọ-aré-dìjà ní ńjẹ̀bi ẹjọ́.
Àṣàyá kì í jẹ́ kí ọmọ ọ̀yà ó gbọ́n.
A-ṣe-kó-súni, ẹrú-u Ségbá; ó fọ́ akèrègbè tán ó lọ sóde Ọ̀yọ́ lọ gba onísé wá; bẹ́ẹ̀ni ẹgbàá lowó onísé.
À-ṣe-sílẹ̀ làbọ̀wábá; ẹni tó ṣu sílẹ̀ á bọ̀ wá bá eṣinṣin.
À-ṣẹ̀ṣẹ̀-tọ́-ọtí-wò okùn-un bàǹtẹ́ já; bí a bá mu àmuyó ńkọ́?
Aṣiwèrè èèyàn lòjò ìgboro ńpa.
Aṣiwèrè èèyàn ní ńgbèjà ìlú-u rẹ̀.
Aṣòroójà bí ìjà ọjà; onítìjú ò níí sá; ẹni tí ńnà án ò níí dáwọ́ dúró.
A-ṣòwò-ọṣẹ kì í pa owó ńla.
A-ṣoore-jókòó-tì-í, bí aláìṣe ni.
Aṣọ funfun òun àbàwọ́n kì í rẹ́.
Aṣọ ìrókò ò ṣéé fi bora.
Aṣọ tá a bá rí lára igún, ti igún ni.
A-sọ́-ẹ̀hìnkùlé ba araa rẹ̀ nínú jẹ́; ohun tó wuni là ńṣe nílé ẹni.
Àtàrí ìbá ṣe ìkòkò ká gbé e fún ọ̀tá yẹ̀wò; a ní ó ti fọ́ yányán.
Atẹ́gùn ò ṣéé gbé.
Àtẹ́lẹwọ́ ò ṣéé fi rúná.
Atipo ò mọ erèé; ó ní, “Bàbá, mo réwé funfun lóko.”
Àtònímòní ò tó àtànọ́mànọ́.
A-tọrọ-ohun-gbogbo-lọ́wọ́-Ọlọ́run kì í kánjú.
A-wí-fúnni-kó-tó-dáni, àgbà òmùjà ni.
À-wí-ìgbọ́, àfọ̀-ọ̀-gbọ́ tí ńfi àjèjé ọwọ́ mumi.
Àwítẹ́lẹ̀ ní ńjẹ́ ọmọ́ gbẹ́nà; ọmọ kì í gbẹ́nà lásán.
Awo aláwo la kì í dá lẹ́ẹ̀mejì.
Àwòdì òkè tí ńwo ìkaraun kọ̀rọ̀, kí ni yó fìgbín ṣe?
Awọ erin ò ṣéé ṣe gángan.
Awọ ẹlẹ́dẹ̀ ò ṣéé ṣe gbẹ̀du.
Awọ ẹnu ò ṣéé ṣe ìlù.
Ààyá bọ́ sílẹ̀, ó bọ́ sílé.
Àáyá gbọ́n, Ògúngbẹ̀-ẹ́ sì gbọ́n; bí Ògúngbẹ̀-ẹ́ ti ḿbẹ̀rẹ̀ ni àáyá ńtiro.
Àyàn ò gbẹdùn.
Àyangbẹ ẹjá dùn; ṣùgbọ́n kí la ó jẹ kẹ́já tó yan?
Ayé ńlọ, à ńtọ̀ ọ́.
Ayé ò ṣé-é bá lérí; wọ́n lè ṣeni léṣe.
Ayé ò ṣé-é finú hàn; bí o lọ́gbọ́n, fi síkùn ara-à rẹ.
|
|||||||