Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 2: On perspicaciousness (good judgment, perceptiveness), reasonableness, sagacity, savoir-faire, wisdom, and worldly wisdom

O

Ó di kan-nu-rin kan-nu-rin, agogo Ògúntólú.

O fẹ́ joyè o ní o-ò ní-í jà.

O fi awọ ẹkùn ṣẹbọ àìkú; ẹkùn ìbá má kùú ìwọ ìbá rawọ ẹ̀ ṣoògùn?

O jó nÍfọ́n Ifọ́n tú, o jó lÓÉjìgbò Èjìgbó fàya bí aṣọ, o wá dé Ìlá Ọ̀ràngún ò ńkàndí; gbogbo ìlú òrìṣà ni wọ́n ní kí o máa bàjẹ́ kiri?

O kò bá ìṣín máwo, o ò bá ìrókò mulẹ̀; abẹ́rẹ́ ẹ-ẹ́ bọ́ sómi o ní o ó yọ ọ́.

O kò bá òkun máwo, o ò bá ọ̀sà mulẹ̀; abẹ́rẹ́ ẹ-ẹ́ bọ́ sódò o ní o ó yọ ọ́.

O kò bá Ọya máwo, o ò bá Ògún mulẹ̀; abẹ́rẹ́ ẹ-ẹ́ bọ́ sódò o ní o ó yọ ọ́.

O kò lu òmìrán lóru, ò ńlù ú lọ́sàn-án.

O kò wọ bàtà nínù ẹ̀gún ò ńsáré; o lágbára màlúù?

O kò-ì mú ẹrú, o ní Àdó ni ò ó tà á fún.

O ló-o fẹ́ jọba o ní o-ò nìí ṣÒgbóni, o-ò níí pẹ́ lóyè.

Ò ḿbẹ oníṣègùn, o ò bẹ asínwín; bí oníṣègùn-ún ṣe tí asínwín ò gbà ńkọ́?

“Ó ḿbọ̀, ó ḿbọ̀!” la fi ńdẹ́rù ba ọmọdé; bó bá dé tán ẹ̀rù a tán.

O ní kí ará ọ̀run ṣe oore fún ọ; bẹ́ẹ̀ni o rí ẹni tí eégún ńlé, tó fá lọ́bẹ̀ lá.

Ó ńti ilé bọ̀ kò ra ẹ̀gbẹ; ó dé oko tán ó ní ẹ̀gbẹ ni oníkú ẹ̀kọ.

O rí etí adẹ́tẹ̀ o fi san okòó; kò nípọn tó ni, tàbí kò rẹ̀ dẹ̀dẹ̀ tọ́?

O rí ẹsẹ̀-ẹ wèrè o ò bù ú ṣoògùn; níbo lo ti máa rí tọlọgbọ́n?

O rojọ́ láàárọ̀ o ò jàre, ó dalẹ́ o ní kọ́ba dúró gbọ́ tẹnu ẹ; ohun tó o wí láàárọ̀ náà kọ́ lo máa wí lálẹ́?

O sá fún ikú, o bọ́ sí àkọ̀ idà.

“Ó ṣe mí rí”; ògbó adìẹ-ẹ́ rí àwòdì sá.

Ó ti ojú orun wá ó ńfọ ẹnà; ó ní “ẹ jẹ́ ká máa ji ní mẹ́mu-mẹ́mu.”

O wà láyé, mo wà láàyè, ò ḿbi mí bí ọ̀rún ṣe rí.

Ó yẹ kí eégún mọ ẹni tó mú àgbò so.

Obìnrin ò gbé ibi tó máa rọ̀ ọ́ lọ́rùn.

Òbò ò ṣé ṣe àlejò.

Odídẹrẹ́ dawo, ìkó ìdí ẹ̀-ẹ́ dọ̀gbẹ̀rì.

Odó iyán ò jẹ́ gún ẹ̀lú; odó ẹ̀lú ò jẹ́ gúnyán; àtẹ tá-a fi ńpàtẹ ìlẹ̀kẹ̀, a ò jẹ́ fi pàtẹ ọ̀rúnlá.

Òdú kì í ṣe àìmọ̀ olóko.

Ogún kì í pọ̀ ká pín fún aládùúgbò.

Ogún mbókòó? Òwe aṣiwèrè.

Ohùn àgbà: bí kò ta ìgún, a ta èbù.

Ohun tí a bá pàdé ò jọ ohun tí a rí tẹ́lẹ̀.

Ohun tí a ni la fi ńkẹ́ ọmọ ẹni.

Ohun tí a ò rí rí lèèwọ̀ ojú.

Ohun tí a ṣe nílé àna ẹni, “Ojú ńtì mí” kúrò níbẹ̀.

Ohun tí kò jẹ́ káṣọ pé méjì ni ò jẹ́ kó dú.

Ohun tí kò jẹ́ kí oko pọ̀ ni ò jẹ́ kó mọ́.

Ohun tó fọ́ni lójú ló ńjúwe ọ̀nà fúnni.

Ohun tó jọ oun la fi ńwé ohun; èpo ẹ̀pà ló jọ ìtẹ́ ẹ̀lírí.

Ohun tó ní òun óò bẹ́ni lórí, bó bá ṣíni ní fìlà, ká dúpẹ́.

Ohun tó ní òun óò ṣeni lẹ́rú, tó wá ṣeni níwọ̀fà, ká gbà á.

Ohun-a-lè-ṣe, tó forí sọ àpò òwú; wọ́n ní ṣe bó rí yangí nílẹ̀, ó ní “Ohun a bá lè ṣe là ńlérí sí.”

Òjò òì dá a ní kò tó tàná.

Òjòwú ò já gèlè; kooro ló lè já.

Òjòwú ò lẹ́ran láyà.

Ojú àwo làwó fi ńgba ọbẹ̀.

Ojú kan làdá ńní.

Ojú kì í pọ́nni ká fi pọ́nlẹ̀.

Ojú kì í pọ́nni ká mu ìṣápá; òùngbẹ kì í gbẹni ká mu ẹ̀jẹ̀.

Ojú kì í ti àgbà lóru; jagun a lóṣòó góńgó.

Ojú kì í ti eégún kó má mọ̀nà ìgbàlẹ̀.

Ojú la fi ḿmọ àísí epo; ẹnu la fi ḿmọ àìsíyọ̀; ọbẹ̀ tí ò bá lépo nínú òkèèrè la ti ḿmọ̀ ọ́.

Ojú tó rọ̀ nirorẹ́ ńsọ.

“Òkè ìhín ò jẹ́ ká rí tọ̀ún” ò ṣéé pa lówe nílé àna ẹni.

Okó ilé kì í jọ obìnrin lójú, àfi bó bá dó tìta.

Oko kì í jẹ́ ti baba àti tọmọ kó má nìí àlà.

Oko mímọ́ ṣe-é ro; ọ̀nà mímọ́ dùn-ún tọ̀; gbogbo ìyàwó dùn-ún gbàbálé; aṣọ ìgbà-á ṣe-é yọ.

Okotorobo-ó tùyẹ́ sílẹ̀ ọmọ titún ńgbe jó; ó ní ó rọ òun lọ́rùn lòún tu ú?

Okotorobo-ó yé ẹyin sílẹ̀, àdàbà ńgarùn wo ẹyin ẹlẹ́yin.

Òkú ẹran kì í ti ajá lójú.

Olè tó gbé fèrè ọba ò róhun gbé.

Olé tó jí kàkàkí, níbo ni yó ti fọn ọ́n?

Olóògùn ní ńṣe bí a-láigbọ́-mọ̀ràn; bí ogun ó bàá wọ̀lú ọlọgbọ́n là ńfọ̀rọ̀ lọ̀.

Olóhun-ún dolè; “Gbà bù jẹ́” dolóhun.

Olóhun kì í rí ohun ẹ̀ kó pè é lórò.

Olórìṣà tó da kiriyó: ọjọ́ tó gbọ́ dùrù orí ijó lẹsẹ̀-ẹ́ kán sí.

Olòṣì ọmọ ní ńfọwọ́ òṣì júwe ilé-e baba-a ẹ̀.

Olóúnjẹ-ẹ́ tó-ó bá kú.

Olówe laláṣẹ̀ ọ̀rọ̀.

Olówó á wá; aláwìn á wá; ìlú tí à ńgbé la gbé ńgbàwìn; à-rà-àì-san ni ò súnwọ̀n.

Olówó pèlù o ò jó; ọjọ́ wo lo máa rówó pe tìẹ?

Òmùgọ̀ èèyàn ní ḿbóbìnrin mulẹ̀: ọjọ́ tóbìnrín bá mawo lawó bàjẹ́.

Òmùgọ̀ ní ńgbé ígunnu; ọlọgbọ́n ní ńgbowó.

Onígi ní ńfigi ẹ̀ dọ́pọ̀.

Onígbá ní ńpe igbá ẹ̀ ní àíkàrágbá káyé tó fi kólẹ̀.

Onígbèsè tí ńpa àpatà ẹyẹ́lé.

Onígẹ̀gẹ́ fìlẹ̀kẹ̀ dọ́pọ̀; adámú fi sàárà san ẹgbẹ̀ta.

Oníṣègùn tó sọ pé díẹ̀ ò tó òun, òfo ni yó fọwọ́ mú.

Ooré pẹ́, aṣiwèrè-é gbàgbé.

Orí ọ̀kẹ́rẹ́ popo láwo; bí a wí fọ́mọ ẹni a gbọ́ràn.

Orí tí yó jẹ igún kì í gbọ́; bí wọ́n fun ládìẹ kò níí gbà.

Orí tó kọ ẹrù, owó ní ńnáni.

Orin tí ò ṣoro-ó dá kì í ṣòro-ó gbè; bí ó bá ní “héééé,” à ní “háááá.”

Orín yí, ìlù-ú yí padà.

Òrìṣà tó ní tÒgún kì í ṣe ọ̀nà ò ní rí nńkan jẹ lásìkò tó fẹ́.

Oòrùn kì í jẹ iṣu àgbà kó má mọbẹ̀.

Oòrùn kì í là kínú bí olóko.

Òṣùpá lé a ní kò gún; ẹni tọ́wọ́ ẹ̀-ẹ́ bá to kó tún un ṣe.

Òtòṣì ò gbọ́ tìṣẹ́ ẹ̀ ó ní ogún kó àparò; ọdẹ́ rorò.

Owó kì í lóye kọ́mọ kú sẹ́rú.

Owó kì í yéye kọ́mọ ó kú.

Owó la fi ńfíná owó; bí ẹgbẹ̀rún bá so lókè, igbió la fi ńká a.

Owó la fi ńlògbà; ọgbọ́n la fi ńgbélé ayé.

Owó ní ńpa ọjà ọ̀mọ̀ràn.

Owó tọ́mọdé bá kọ́kọ́ ní, àkàrà ní ńfi-í rà.

Òwú kì í là kínú bí olóko.

Owú pani ju kùm̀mọ̀.

Òyìnbó Òkè Eléérú, ó ṣubú sóde Alọ́ba; kùmmọ ni yó gbe dìde.

.
PreviousContentsNext