Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 2: On perspicaciousness (good judgment, perceptiveness), reasonableness, sagacity, savoir-faire, wisdom, and worldly wisdomOdot
Ọ̀bẹ ńwólé ara ẹ̀ ó ní òún ḿba àkọ̀ jẹ́.
Ọbẹ̀ tí baálé kì í jẹ, ìyálé ilé kì í sè é.
Ọ̀dẹ̀ ọmọ ńfi ìdò ṣeré.
Ọ̀dẹ̀dẹ̀ ò gba òró, àfi abẹ́ ọdán.
Ọ̀fàfà fohùn ṣakin.
Ọgbọ́n a-dákọ-kéré ò tó ti a-yọwó-má-rà.
Ọgbọ́n dùn-ún gbọ́n; ìmọ́ dùn-ún mọ̀.
Ọgbọ́n ju agbára.
Ọgbọ́n kì í tán.
Ọgbọn la fi ńgbé ayé.
Ọgbọ́n lajá fi ńpa ìkokò bọ Ifá.
Ọgbọ́n ní ńṣẹgun; ìmọ̀ràn ní ńṣẹ́ ẹ̀tẹ̀.
Ọgbọ́n ọlọgbọ́n la fi ńṣọgbọ́n, ìmọ̀ràn ẹnìkan ò tọ́ bọ̀rọ̀.
Ọgbọ́n ọlọgbọ́n ò jẹ́ ká pe àgbà ní wèrè.
Ọgbọ́n tí ahún gbọ́n, ẹ̀hìn ni yó máa tọ ti ìgbín.
Ọgbọ́n tí ọ̀pọ̀lọ́ fi pa ẹfọ̀n ló fi ńjẹ ẹ́.
Ọgbọọgbọ́n làgbàlagbà-á fi ńsá fún ẹranlá.
Ọjọ́ eré là ńjiyàn ohun.
Ọjọ́ tíìlù-ú bá ńlu onílù, iṣẹ́ mìíràn-án yá.
Ọjọ́ tí olówó ńṣẹbọ ni à-wà-jẹ-wà-mu ìwọ̀fà.
Ọ̀kẹ́rẹ́ ńsunkún agbádá; èyí tí àjàò-ó dá léṣìí kí ló fi ṣe?Ṣebí igi ló fi ngùn.
Ọkọ́ ọlọ́kọ́ la fi ńgbọ́n èkìtì.
Ọ̀kọ̀ọ̀kan là ńyọ ẹsẹ̀ lábàtà.
Ọ̀kọ̀ọ̀kan là ńyọ ẹsẹ̀ lẹ́kù.
Ọkùnrin jẹ́jẹ́ a-bìwà-kunkun.
Ọlọ ò lọ ló dé Ìbarà?Ìbarà a máa ṣe ilé ọlọ?
Ọlọ́gbọ́n dorí ẹja mú; òmùgọ́ dìrù-u ẹ̀ mú.
Ọlọ́gbọ́n jẹni bí ẹmùrẹ́n; aṣiwèré jẹni bí ìgbọ̀ngbọ̀n.
Ọlọgbọ́n ló lè mọ àdììtú èdè.
Ọlọgbọ́n ńdẹ ihò, ọ̀mọ̀rànán dúró tì í; ọlọgbọ́n ní “Háà, ó jáde!”Ọ̀mọ̀rán ní “Háà, mo kì í!”Ọlọgbọ́n ní “Kí lo kì?” Ọ̀mọ̀rán ní “Kí nìwọ náà-á ló jáde?”
Ọlọgbọ́n ni yó jogún ògo; aṣiwèrè ni yó ru ìtìjú wálé.
Ọlọgbọ́n ọmọ ní ḿmú inú-u bàbá ẹ̀ dùn; aṣiwèrè ọmọ ní ḿba inú ìyá ẹ̀ jẹ́.
Ọlọ́jà kì í wípé kọ́jà ó tú.
Ọlọ́tí kì í mọ ọmọ ẹ̀ lólè
Ọlọ́tọ̀ọ́ ní tòun ọ̀tọ̀; ìyá ẹ̀-ẹ́ kú nílé, o gbé e lọ sin sóko.
Ọmọ atiro tó ra bàtà fún bàbá ẹ̀, ọ̀rọ̀ ló fẹ́ gbọ́.
Ọmọ ẹní dàra, bí-i ká fi ṣaya kọ́.
Ọmọ ẹni ẹlẹni ò jọ ọmọ ẹni; ọmọ eni ì-bá jiyán, ọmọ ẹni ẹlẹ́ni a jẹ̀kọ.
Ọmọ ẹni kì í gbọnsẹ̀ ká fi eèsún nù ú nídìí.
Ọmọ iná là ńrán síná.
“Ọmọ-ọ̀ mi ò yó” la mọ̀; “ọmọ-ọ̀ mí yó, ṣùgbọ́n kò rí sáárá fẹ́,” a ò mọ ìyẹn.
Ọmọ tí ò ní baba kì í jìjà ẹ̀bi.
Ọmọdé kékeré ò mọ ogun, ó ní kógun ó wá, ó ní bógún bá dé òun a kó síyàrá ìyá òun.
Ọmọdé kì í mọ àkókò tí kúrò-kúròó fi ńkúrò.
Ọmọde kì í mọ ìtàn, kó mọ à-gbọ́-wí, kó mọ ọjọ́ tí a ṣe ẹ̀dá òun.
Ọmọdé kì í mọ ori-í jẹ kó má rá a lẹ́nu.
Ọmọdé kì í ní ina níle kí tòde má jòó o.
Ọmọdé mọ sáárá, ṣùgbọ́n kò mọ àlọ̀yí.
Ọmọdé ní wọ́n ńjẹ igún, bàbá ẹ̀-ẹ́ ní wọn kì í jẹ ẹ́; ó ní ẹnìkán jẹ ẹ́ rí lójú òun; bàbá ẹ̀-ẹ́ ní ta ni? Ó ní ẹni náà ò sí.
Ọmọdé ò mẹ̀fọ́, ó ńpè é légbògi.
Ọmọdé ò mọ oògùn, ó ńpè é lẹ́fọ̀o?; kò mọ̀ pé ikú tó pa baba òun ni.
Ọmọdé ò moògùn ó ńpè é lẹ́gùn-ún.
Ọmọdé yìí, máa wò mí lójú, ẹni (tí) a bá lọ sóde là ńwò lójú.
Ọ̀mọ̀ràn ní ḿmọ oyún ìgbín.
Ọ̀pá gbóńgbó ní nṣíwájú agbọ́ọni.
Ọpẹ́ ló yẹ ẹrú.
Ọ̀pẹ̀lẹ̀ èèyàn, bí a ò bá gbé e lulẹ̀, kò níí lè fọhùn ire.
Ọ̀pọ̀lọ́ ní kéjò máa kálọ; ìjà òún di ojú ọ̀nà.
Ọ̀pọ̀lọ́ ní òún lè sín ìlẹ̀kẹ̀; ta ní jẹ́ fi ìlẹ̀kẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́ sídìí ọmọ-ọ ẹ̀?
Ọ̀pọ̀lọ̀ ńyan káńdú-kàǹdù-káńdú lóju ẹlẹ́gùúsí; ẹlẹ́gùúsí ò gbọdọ̀ yí i lata.
Ọ̀pọ̀lọ́ ò mọ̀nà odò, ó dà á sí àwàdà.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò ní ńlé eégún wọlé kẹri-kẹri.
Ọ̀ràn kan la fi ńṣòfin ọ̀kan.
Ọ̀ràn ọlọ́ràn la fi ńkọ́gbọ́n.
Ọ̀ràn tí ò sunwọ̀n, konko ǹṣojú.
Ọ̀rọ̀ kì í gbórín ká fi ọ̀bẹ bù ú, ẹnu la fi ńwí i.
Ọ̀rọ̀ la fi ńjẹ omitooro ọ̀rọ̀.
Ọ̀rọ̀-ọ́ ni òun ò nílé; ibi tí wọ́n bá rí ni wọ́n ti ńsọ òun.
Ọ̀rọ̀ rere ní ńyọ obì lápò; ọ̀rọ̀ búburú ní ńyọ ọfà lápó.
Ọ̀rọ̀ tí ọlọgbọ́n bá sọ, ẹnu aṣiwèrè la ti ńgbọ́ ọ.
Ọ̀rọ̀ tó dojú rú di ti ọlọ́rọ̀, ayé á dẹ̀hìn.
Ọsán gbé ojú ọrun le kókó; bó bá wọ odò, a di ọ̀-rọ̀-pọ̀jọ̀-pọ̀jọ̀.
Ọ̀sán ọ̀run ò pọ́n; ẹni tó bá yá kó máa bá tiẹ̀ lọ.
Ọwọ́ aṣiwèrè ni a gbé ḿbá apá yíya.
Ọ̀wọ̀-ọ kókó la fi ńwọ igi; ọ̀wọ̀ òrìṣà la fi ńwọ àfín.
|
|||||||