Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 2: On perspicaciousness (good judgment, perceptiveness), reasonableness, sagacity, savoir-faire, wisdom, and worldly wisdom

N

Ní ìlú tí a ò ti fẹ́ ẹyẹlé, adìẹ yóò ṣọ̀wọ́n níbẹ̀.

Ní ìlú tí a ò ti fẹ́ ẹyẹlé, tí a ò fẹ́ adìẹ, irú ẹyẹ wo ní yóò jí wọn lójù orun?

Ní inú Ifá ni Fá-túmọ̀-ọ́ wà.

“Níbo ló gbé wà?” nìyájú ẹkùn.

Nígbàtí ọwọ́ ò tí ì gbọ́n lojú ńṣepin.

Nítorí adití lòjò fi ńṣú; nítorí afọ́jú ló ṣe ńkù.

Nítorí èèyàn la ṣe ńní ọwọ́ ọ̀tún; òsì là bá lò.

Nítorí-i ká lè ríbi gbé e la ṣe ńṣe ọyàn sódó.

.
PreviousContentsNext