Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 1: On humility, self-control, self-knowledge, self-respect, and self-restraintOdot
Ọbẹ̀ kì í gbé inú àgbà mì.
Ọ̀bún ríkú ọkọ tìrànmọ́; ó ní ọjọ́ tí ọkọ òún ti kú òun ò fi omi kan ara.
Ọ̀gà-ǹ-gà lọmọ-ọ̀ mi ńjẹ́, ẹ má pe ọmọ-ọ̀ mi ní Ògò-ǹ-gò mọ́! Èwo lorúkọ rere níbẹ̀?
Ọ̀gẹ̀gẹ́ ò lẹ́wà; lásán ló fara wéṣu.
Ọjọ́ àgbà-á kú sàn ju ọjọ́ àgbà-á tẹ́.
Ọjọ́ kan là ḿbàjẹ́, ọjọ́ gbogbo lara ńtini.
Ọjọ́ kan ṣoṣo là ńtẹ́; ojoojúmọ́ lojú ńtini.
Ọjọ́ tí alákàn-án ti ńṣepo, kò kún orùbà.
“Ọjọ́ tí mo ti ḿbọ̀ ng ò rírú ẹ̀ rí”: olúwa ẹ̀-ẹ́ mọ ìwọ̀n ara ẹ̀ ni.
Ọ̀kánjúwà àgbà ní ńsọ ara ẹ̀ dèwe.
Ọ̀kánjúwà alágbaà ní ńgarùn wo eégún.
Ọkùnrin kì í ké, akọ igi kì í ṣoje.
Ọlọgbọ́n kan ò ta kókó omi sáṣọ; ọ̀mọ̀ràn kan ò mọ oye erùpẹ̀ ilẹ̀.
Ọlọgbọ́n ò tẹ ara ẹ̀ nÍfá; ọ̀mọ̀ràn ò fi ara ẹ̀ joyè; abẹ tó mú ò lè gbẹ́ èkù ara ẹ̀.
Ọmọ àì-jọbẹ̀-rí tí ńja epo sáyà.
Ọmọ onílẹ̀ á tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́.
Ọmọ ọba Ọ̀nà Ìṣokùn ńfi ehín gé ejò, ọmọ ọba kan-án ní òun kì í jẹ ẹ́; ìlú wo lọmọ ọba náà-á ti wá?
Ọmọdé dáwọ́tilẹ̀, ó ní òún tó ọ̀bọ; bó tó ọ̀bọ, ó tó gẹ̀gẹ̀ àyàa ẹ̀?
Ọmọdé ní ẹẹ́ta lọ́wọ́, ó ní kí Èṣù wá ká ṣeré owó; ẹẹ́ta-á ha tó Èṣùú sú epo lá?
Ọ̀mùtí gbàgbé ìṣẹ́, alákọrí gbàgbé ọ̀la.
Ọ̀nà ọ̀fun ò gba egungun ẹja.
Ọ̀ràn ò dun ọmọ ẹṣin; a mú ìyá ẹ̀ so, ó ńjẹ oko kiri.
Ọ̀rọ̀ bọ̀tí-bọ̀tí ò yẹ àgbàlagbà.
Ọ̀rọ̀ ò dùn lẹ́nu ìyá olè.
Ọ̀rọ̀ wo ló wà lẹ́nu alaṣọ pípọ́n?
Ọ̀sán pọ́n o ò ṣán ẹ̀kọ; oòrún kan àtàrí o ò jẹ àmàlà; àlejò-ó wà bà ọ ní ìyẹ̀tàrí oòrùn o ò rí ǹkan fún un; o ní “Njẹ́ ng ò níí tẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ báyìí”? O ò tíì tẹ́ lọ́wọ́ ara ẹ, ká tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá wípé o ó tẹ̀ẹ́ lọ́wọ́ ẹlòmíràn tàbí o ò níí tẹ́?
Ọ̀ṣìn ò lè mú àwòdì òkè; Bámidélé lọ̀ṣín lè mú.
Ọ̀ṣọ́ ọlọ́ṣọ̀ọ́ ò yẹni; ṣòkòtò àgbàbọ̀ ò yẹ́ ọmọ èèyàn.
Ọwọ́ àìdilẹ̀ ní ńyọ koríko lójú àna ẹ̀.
Ọ̀wọ́n là ńra ògo, ọ̀pọ̀ là ńra ọ̀bùn, iyekíye là ńra ìmẹ́lẹ́.
Ọ̀yájú-u baálé ní ńpàdé ìbòsí lọ́nà.
|
|||||||