Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 1: On humility, self-control, self-knowledge, self-respect, and self-restraint

O

Ó bọ́ lọ́wọ́ iyọ̀ ó dòbu.

Ó bọ́ lọ́wọ́ oṣù ó dàràn-mọ́jú.

O dájú dánu, o ò mọ ẹ̀sán mẹ́sàn-án.

Ó di àwùjọ ṣòkòtò kí ládugbó tó mọ ara rẹ̀ Lábèṣè.

Ó di ọjọ́ alẹ́ kábuké tó mọ̀ pé iké kì í ṣọmọ.

O kò mọ ẹ̀wà lóńjẹ à-jẹ-sùn.

Ò ńjàgbọ̀nrín èṣín lọ́bẹ̀, o ní o ti tó tán.

O ru ládugbó ò ńrerá; kí ni ká sọ fẹ́ni tó ru Òrìṣà-a Yemọja?
Because you are carrying a huge pot you strut; what would one say to the person carrying the divinity Yemoja?
(Never assume to be more important than you are, especially when there are really more important people around.)

Ó tọ́ kí eégún léni lóko àgbàdo, èwo ni ti Pákọ̀kọ̀ láàrin ìlú?

Ó yẹ ẹni gbogbo kó sọ pé iṣu ò jiná, kò yẹ alubàtá.

Ó yẹ ẹni gbogbo kó dínwó aró, kò yẹ atọ̀ọ́lé.

Ó yẹ ẹni gbogbo kó sọ pé “Ọlọ́run a-ṣèkan-má-kù,” kò yẹ akúkó.

Odò kékeré lalákàn-án ti lè fọ́ epo; bó bá di àgàdàm̀gbá tán, odò a gbé alákàn lọ.

Òfin ni yó sọ ara ẹ̀; ìyàwó tí ńna ọmọ ìyálé.

Ogun tí olójúméjìí rí sá ni olójúkan-án ní òún ńlọ jà.

Ohun méjì ló yẹ Ẹ̀ṣọ́: Ẹ̀ṣọ́ jà, ó lé ogun; Ẹ̀ṣọ́ jà ó kú sógun.

Ohun tí à ńtà là ńjẹ; kì í ṣe ọ̀rọ̀ oní-kẹrosíìnì.

Ohun tí eèrá bá lè gbé ní ńpè ní ìgànnìkó.

Ohun tí ìrẹ̀-ẹ́ ṣe tó fi kán lápá, aláàńtèté ní kí wọ́n jẹ́ kí òun ó ṣe è.

Ohun tí kò tó okòó kì í jẹ àgbà níyà.

Ohun tí wèré fi ńse ara ẹ̀, ó pọ̀ ju ohun tó fi ńṣẹ ọmọ ẹlòmíràn lọ.

Ohun tó ṣeé faga là ńfaga sí; èwo ni,“Ìwòyí àná mo ti na ànaà mi fága-fàga”?

Ohun tó yẹni ló yẹni; okùn ọrùn ò yẹ adìẹ.

Ojú àlejò la ti ńjẹ gbèsè; ẹ̀hìn-in ẹ̀ là ńsan án.

Ojú baba ara; awọ́n bí ojú; aṣòró dà bí àgbà.

Ojú iná kọ́ lewùrà ńhurun.

Ojú kì í pọ́n ẹdun kó dẹni ilẹ̀; ìṣẹ́ kì í ṣẹ́ igún kó di ojúgbà adìẹ.

Ojú kì í pọ́n baálé ilé kó fọwọ́ gbálẹ̀ ilé ẹ̀.

Ojú kì í pọ́n babaláwo kó bèrè ẹbọ àná.

Ojú kì í pọ́n òkú ọ̀run kó ní kí ará ayé gba òun.

Ojú kì í pọ́nni ká fàbúrò ẹni ṣaya.

Ojú kì í pọnni ká fàkísà bora.

Ojú kì í pọ́nni ká pọ́n léhín.

Ojú ò rọ́lá rí; ó bímọ ẹ̀ ó sọ ọ́ ní Ọláníyọnu.

Ojú ò ti oníṣègùn, ó ní àna òun ńkú lọ.

Ojú ti agbọ́ń agbọ́n láfà kò léro.

Òkété pẹ̀lú ọmọ ẹ̀-ẹ́ di ọgbọọgba sínú ihò; nígba tí ìyá ńfehín pàkùrọ́, ọmọ náà ńfehín pa pẹ̀lú.

Òkùnkùn ò mẹni ọ̀wọ̀; ó dÍfá fún “Ìwọ́ tá nìyẹn”?

Olóbìnrin kan kì í pagbo ìja.

Olójúkan kì í tàkìtì òró.

Olómele kì í sọ pé igi yó dàá lóde lọ́la.

Olówó jẹun jẹ́jẹ́; òtòṣì jẹun tìpà-tìjàn; òtòṣì tí ḿbá ọlọ́rọ̀ rìn, akọ ojú ló ńyá.

Olówó ní ḿbá ọlọ́rọ̀-ọ́ rìn; ẹgbẹ́ ní ḿbá ẹgbẹ́ ṣeré.

Olówó ní ńjẹ iyán ẹgbàá.

Olóyè kékeré kì í ṣe fáàárí níwájú ọba.

Òní, ẹtú jìnfìn, ọ̀la, ẹtú jìnfìn; ẹtu nìkan lẹran tó wà nígbó?

Oníbàjẹ́ ò mọra; oníbàjẹ́ ńlọ sóko olè ó mú obìnrin lọ; ọkọ́ kó akọṣu, ìyàwó kó ewùrà.

Oníbàtá kì í wọ mọ́ṣáláṣí kó ní “Lèmámù ńkọ́?”

Onífunra àlejò tí ńtètè ṣe onílé pẹ̀lẹ́.

Onígẹ̀gẹ́ fìlẹ̀kẹ̀ dọ́pọ̀; onílẹ̀kẹ̀ ìbá gbowo, ko rọ́rùn fìlẹ̀kẹ̀ so.

Onílé ńjẹ èso gbìngbindò; alèjò-ó ní kí wọ́n ṣe òun lọ́wọ́ kan ẹ̀wà.

OníṢàngó tó jó tí kò gbọn yẹ̀rì: àbùkù-u Ṣàngó kọ́; àbùkù ara ẹ̀ ni.

OníṢàngó tó jó tí kò tàpá, àbùkù ara ẹ̀.

On-íṣẹ̀ẹ́pẹ́-igí bímọ ó sọ ọ́ ní Ayọ̀-ọ́-kúnlé; ayọ̀ wo ló wà lára ìṣẹ́pẹ́ igi?

Oǹpè ní ńfa ọlá; òjípè kì í fa ọlá.

Orí àgbà-á níyì, ó sàn ju orí àgbà-á fọ́ lọ.

Orí awọ là ḿbágbà.

Orí-i kí ní ńyá àpọ́n tó ńsúfèé? Nítorí pé yó gùn-ún-yán fúnra ẹ̀ yó nìkan jẹ́?

Orogún ìyá ẹ-ẹ́ dáṣọ fún ọ o ní kò balẹ̀; mélòó nìyá ẹ-ẹ́ dá fún ọ tó fi kú?

“Òru ò molówó” nIfá tí à ńdá fún “Ìwọ ta nìyẹn?”

Oòrùn, kó tìẹ wọ̀ ká má bàá Ọlọ́jọ́ wí.

Òtòlò-ó jẹ, òtòlò-ó mu, òtòlò-ó fẹsẹ̀ wé ẹsẹ̀ erin.

Oúnjẹ ọmọ kékeré a máa wọ àgbà nínú; òrùka ọmọ kékeré ni kì í wọ ágbá lọ́wọ́.

Owó ẹ̀yẹ ò sú ẹni-í san; tọ̀ràn ni ò súnwọ̀n.

.
PreviousContentsNext