Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 1: On humility, self-control, self-knowledge, self-respect, and self-restraint

P

Pamí-nkú obìnrín ṣorí bẹmbẹ sọ́kọ.

Pátápátá alágbẹ̀dẹ ò ju ilé àrọ lọ.

Pẹ̀lẹ́ larẹwà ńrìn; jẹ́jẹ́ lọmọ ọlọ́jà ńyan. [88]

Pẹ̀lẹ́-pẹ̀lẹ́ nijó àgbà; ara gbogbo ló di àkísà tán.

Pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ Ìjèṣà, ó ta sẹ́ni lára kò wọ́n.

.
PreviousContentsNext