Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 1: On humility, self-control, self-knowledge, self-respect, and self-restraintL
Labalábá fi ara ẹ̀ wẹ́yẹ, kò lè ṣe ìṣe ẹyẹ.
Lábúlábú
[64]
fara wé aró, kò lè ṣe bí aró; pòpòǹdó
[65]
fara wé àgbàdo.
Lágbájá ìbá wà a di ìjímèrè; ẹni tó bá níwájú di oloyo?
Láká-ǹláká ò ṣéé fi làjà; ọmọ eégún ò ṣéé gbé ṣeré.
Lásán kọ́ là ńdé ẹtù; ó ní ẹni tórí ẹ̀ ḿbá ẹtù mu.
Lékèélékèé ò yé ẹyin dúdú; funfun ni wọ́n ńyé ẹyin wọn.
|
|||||||