Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 1: On humility, self-control, self-knowledge, self-respect, and self-restraint

M

Má tẹ̀ẹ́ lọ́wọ́ oníle, má tẹ̀ẹ́ lọ́wọ́ àlejò; lọ́wọ́ ara ẹni la ti ńtẹ́.

Màlúù ò lè lérí níwájú ẹṣin.

Mànàmáná ò ṣéé sun iṣu.

“M̀bá wà lỌ́yọ̀ọ́ mà ti so ẹṣin”; àgùntàn-an rẹ̀ á níye nílẹ̀yí.

Mélòó lÈjìgbò tí ọ̀kan ẹ̀ ńjẹ́ Ayé-gbogbo?

Mo dàgbà mo dàgó, aré ọmọdé ò tán lójúù mi.

Mo dàgbà tán èwé wù mí.

“Mo dára, mo dára,” àìdára ní ńpẹ̀kun ẹ̀.

“Mo gbọ́n tán, mo mọ̀ràn tán” kì í jẹ́ kí agbọ́n lóró bí oyin.

“Mo mọ̀-ọ́ gùn” lẹṣin ńdà.

“Mo mọ̀-ọ́ gún, mo mọ̀-ọ́ tẹ̀” niyán ewùrà-á fi ńlẹ́mọ.

“Mo mọ̀-ọ́ tán” lOrò-ó fi ńgbé ọkùnrin.

“Mo mỌ̀bàrà mo mỌ̀fún” ti kì í jẹ́ kí àwòko kọ́ ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ́ nÍfá.

“Mo mọ̀wọ̀n ara-à mi” kì í ṣẹ̀rẹ̀kẹ́ èébú.

“Mo yó” ńjẹ́ “mo yó,” “mo kọ̀” ńjẹ́ “mo kọ̀”; jẹun ǹṣó, àgbà ọ̀kánjúwà ni.

.
PreviousContentsNext