Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 1: On humility, self-control, self-knowledge, self-respect, and self-restraintK
Ká ríni lóde ò dàbí-i ká báni délé.
Ká ríni sọ̀rọ̀ fúnni ò dàbí-i ká sọ̀rọ̀ fúnni ká gbà.
Ká wí fún ẹni ká gbọ́; ká sọ̀rọ̀ fúnni ká gbà; kà bèrè ọnà lọ́wọ́ èrò tó kù lẹ́hìn kàyè baà lè yẹni.
Ká wí fúnni ká gbọ́; ká sọ̀rọ̀ fúnni ká gbà; à-wí-ìgbọ́, à-gbọ́-ìgbà ní ńfi igbá àdánù bu omi mu.
Ká wí ká gbà ló yẹ ọmọ èèyàn.
Ká wí ogún, ká wí ọgbọ̀n, “Ng ò fẹ́, ng ò gbà” laṣiwèré fi ńpẹ̀kun ọ̀ràn.
Kàkà ká dọ̀bálẹ̀ fún Gàm̀bàrí, ká rọ́jú ká kú.
Kàkà kí àgbò ké, àgbò a kú.
Kàkà kí bàbá ran ọmọ ní àdá bọ oko, oníkálukú a gbé tiẹ̀.
Kàkà kí iga akàn ó padà sẹhìn, a kán.
Kàkà kí kìnìún ṣe akápò ẹkùn, ọlọ́dẹ a mú ọdẹ ẹ̀ ṣe.
Kékeré lọ̀pọ̀lọ́ fi ga ju ilẹ̀ lọ.
Kí ẹrú mọ ara ẹ̀ lẹ́rú; kí ìwọ̀fà mọ ara ẹ̀ níwọ̀fà; kí ọmọlúwàbí mọ ara ẹ̀ lẹ́rú Ọlọ́run ọba.
Kì í dọwọ́-ọ baba kó ló di ọwọ́ ọmọ.
Kí ni àǹfàníi kẹ̀tẹ̀kẹ̀tẹ̀ lára kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ à-gùn-fẹsẹ̀-wọ́lẹ̀?
Kí ni apárí ńwá ní ìsọ̀ onígbàjámọ̀?
Kí ni Dáàró ní kó tó sọ pé olè-é kó òun?
Kí ni eléwé-e-gbégbé ńtà tí ó ńsọ pé ọjà ò tà?
Kí ni ìbá mú igún dé ọ̀dọ̀-ọ onídìrí?
Kí ni ó yá àpọ́n lórí tó fiṣu síná tó ńsúfèé pé “bí a ti ńṣe ni inú ḿbí wọn”?
Kí ni onígbá ńṣe tí aláwo ò lè ṣe?
Kí ni orí ńṣe tí èjìká ò lè ṣe? Èjìká ru ẹrù ó gba ọ̀ọ́dúnrún; orí ta tiẹ̀ ní ogúnlúgba.
Kí ni wọ́n ti ńṣe Àmọ́dù nÍlọrin? Ewúrẹ́ ńjẹ́ bẹ́ẹ̀.
Kíjìpá laṣọ ọ̀lẹ; òfì laṣọ àgbà; àgbà tí ò ní tòfì a rọ́jú ra kíjìpá.
Kò rà, kò lówó lọ́wọ́, ó ńwú tutu níwájú onítumpulu.
Kò sí ẹni tó dùn mọ́ àfi orí ẹni.
Kò sí mi lájọ àjọ ò kún: ara ẹ̀ ló tàn jẹ.
Kò sí ohun tí Ṣàngó lè ṣe kó jà lẹ́ẹ̀rùn.
Kò-sí-nílé kì í jagun ẹnu tì.
Kó-tán-kó-tán lajá ńlá omi.
|
|||||||