![]() |
|||||||
Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 6: On consideration, kindness, and thoughtfulnessB
Bámijókòó làbíkú ńjẹ́; ẹni tí ò bímọ rí ò gbọdọ̀ sọ Ọmọ́láriwo.
Bí a bá gé igi nígbó, ká fi ọ̀ràn ro ara ẹni wò.
Bí a bá rí òkú ìkà nílẹ̀, tí a fi ẹsẹ̀ tá; ìkà-á di méji.
Bí o ṣe rere yó yọ sí ọ lára; bí o kò ṣe rere yó yọ sílẹ̀.
Bí ó ti ńdun ọmọ ẹyẹ, bẹ́ẹ̀ ló ńdun ọmọ èèyàn
|
|||||||
![]() |