Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 6: On consideration, kindness, and thoughtfulness

A

A kì í dùbúlẹ̀ ṣubú.

A kì í fi àìmọ̀nà dá pàdé-m̀-pàdé.

Abúni ò tó abẹ̀rín; bẹ́ẹ̀ni abẹ̀rín ò mọ ẹ̀hìn ọ̀la.

Adìẹ́ yẹ̀gẹ̀, a ṣe bí ó ṣubú.

Àfẹ́ẹ̀rí kan ò ju ká rí igbó ńlá bọ́ sí lọ; ẹbọ kan ò ju ọ̀pọ̀ èèyàn lọ; “Òrìṣá gbé mi lé àtète” kan ò ju orí ẹṣin lọ.

A-fi-tirẹ̀-sílẹ̀-gbọ́-tẹniẹlẹ́ni, Ọlọ́run ní ḿba gbọ́ tirẹ̀.

Àgbà ṣoore má wo bẹ̀.

Àgbò ò ṣéé mú; ọ̀dá ò ṣéé mú; ohun gbogbo ní ńtóbi lójú ahun.

Àì-fi-ǹ-kan-pe-ǹ-kan ní ḿba ǹ-kan jẹ́.

Àìmète, àìmèrò, lọmọ ìyá mẹ́fà-á fi ńkú sóko ẹgbàafà.

Àjẹ́gbà ni ti kọ̀ǹkọ̀.

Akẹ́yinjẹ ò mọ̀ pé ìdí ńro adìẹ.

A-lágbára-má-mèrò, baba ọ̀lẹ́.

A-láì-mète-mèrò ọkọ tó fi adìẹ ìyàwó bọ orí ìyálé; bí baálé bá jẹ́ ìkà, èwo ni tòrìṣà?

Aláràjẹ ò mọ ọdún; a-biṣu-úta-bí-igi.

Arúgbó ṣoge rí; àkísà-á lògbà rí.

Àṣẹ Ọ̀yọ́ kì í ró “Gbà”, àfi “Múwá.”

Àṣírí-i náwó-náwó kì í tú lójú ahun.

Aṣiwèrè ló bí ìyá ọ̀bọ.

A-ti-ara-ẹni-roni, ajá ọdẹ.

Ayídóborí tafà sókè: ojú Olúwaá tó wọn.

.
ContentsNext