![]() |
|||||||
Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 6: On consideration, kindness, and thoughtfulnessO
O jẹbẹ, o mubẹ, o babẹ jẹ́.
“O kú iṣẹ́” ò lè bí aráyé nínú.
“Ó kún mi lójú,” ẹ̀kọ Arogun; ọ̀kan ṣoṣo ni mo rà, igba ènì ló fi sí i.
Obì kékeré kọjá òkúta ńlá.
Obìnrin tó bímọ tó bí olómitútù, wàhálà ọkọ ẹ̀-ẹ́ dínkù; kò ní já ewé mọ́, bẹ́ẹ̀ni kò ní wa egbò.
Obínrin-ín bímo fún ọ o ní o ò rínú ẹ̀; o fẹ́ kó o nífun ni?
Ògún ò rọ ike; àgbẹ̀dẹ ò rọ bàtà; oko ò ṣòro-ó ro, àgbẹ̀dẹ ò pa ọkọ́ tà.
Ohun tí ḿbá ahun náwó ẹ̀ ḿbẹ lápò-o ẹ̀.
Òjò pa ewé-e kòkò; bó lè ya kó ya.
Ojú la rí là ńkọrin òkú, òkú ò forin sáyé kó tó lọ.
Ojú ní ńrójú ṣàánú.
Ojú ọba ayé ló fọ́; tọ̀rún là kedere, ó ńwo aṣebi.
Òkulú ní ta ni òun ó ro tòun fún? Ta ní wá ro tiẹ̀ fun Òkulu?
Onígẹ̀gẹ̀ ìṣájú ba tìkẹhìn jẹ́.
Oore kì í gbé; ìkà kì í dànù; à-ṣoore-jindò ní mmúni pàdánù oore.
Oore tí a ṣe fádìẹ ò gbé; bó pẹ́ títí a ṣomi tooro síni lẹ́nu.
Òrẹ́hìn ní ńṣe ọmọ òkù pẹ̀lẹ́; ta ní jẹ́ ṣe ọmọ Ègùn lóore?
Òṣónú ò bí èjìrẹ́; onínúure ní ḿbí ẹdun.
Owó ló ńpe ìná owó.
|
|||||||
![]() |