Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 5: On consistency; honesty, openness, plain speaking, reliabilityEdot
Ẹgẹ́ ò ṣákìí; ẹní bá bọ́ sábẹ-ẹ rẹ̀, a pa á kú pátá-pátá.
Ẹgbẹ̀tàlá: bí a ò bá là á, kì í yéni.
Ẹ-kòì-fẹ́-mi-kù, tó ta ajá-a rẹ̀ lókòó.
Ẹ̀là lọ̀rọ̀; bí a ò bá là á rírú ní ńrú.
Ẹ̀là lọ̀rọ̀; bóbìnrín bá jókòó a laṣọ bòbò.
Ẹlẹ́rìí ní ńyanjú ẹjọ́; ẹlẹ́rìí kì í ṣe elégbè.
Ẹ̀ẹ̀mejì letí ọlọ́jà ńgbọ́rọ̀.
Ẹni a kò fẹ́ nilé-e rẹ̀ ńjìnna lójú ẹni.
Ẹní bá sùn là ńjí, a kì í jí apirọrọ.
Ẹní gbé àrùn pamọ́ kọjá ore oníṣègùn.
Ẹni tí a nà ní kùm̀mọ̀ mẹ́fà, tó ní ọ̀kan ṣoṣo ló ba òun, níbo nìyókùú sọnù sí?
Ẹni tí ó sá là ńlé.
Ẹni tí ó bá máa jẹ́ Ọ̀ṣákálà a jẹ́ Ọṣákálá; ẹni tó bá máa jẹ́ Òṣokolo a jẹ́ Òṣokolo; èwo ni Ọ̀ṣákálá-ṣokolo?
Ẹni tí ó bá mọ ìṣe òkùnkùn, kó má dàá òṣùpá lóró; ohun a ṣe ní ńmúni-í rìnde òru; òkùnkùn ò yẹ ọmọ èèyàn.
Ẹni tí ó ṣe ojú kò da bí ẹni tó ṣe ẹ̀hìn.
Ẹni tí ó fẹ́ kúure, kó hùwà rere.
Ẹni tí ó sùn tó ní òún kú, tó bá jí, ta ni yó wìí fún?
Ẹni tí ó gbọ́n tó ńpurọ́; ẹni tó mọ̀ràn tó ńṣèké; ẹni tó mọ̀ pé nǹkan ò sí tó ńtọrọ; èwo ló sàn nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta?
Ẹni tí ó gbépo lájà ò jalè bí ẹni tó gbà á sílẹ̀ fún un.
Ẹnìkan kì í yọ̀ kí ilẹ̀ ó sẹ́.
Ẹnu òpùrọ́ kì í ṣẹ̀jẹ̀.
Ẹnu-u rẹ̀ ní ńdá igba, tí ńdá ọ̀ọ́dúnrún.
Ẹran tí a kì í jẹ, a kì í fi ehín pín in.
Ẹ̀tàn kì í ṣe ọgbọ́n.
Ẹ̀wà yí kò dùn, ẹ̀wà yí kò dùn, àáṣó ìpàkọ́ ḿmì tìtì.
Ẹyẹlé ní òun ò lè bá olúwa òun jẹ, kí òun bá a mu, kí ó di ọjọ́ ikú-u rẹ̀ kí òun yẹrí.
|
|||||||