Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 5: On consistency; honesty, openness, plain speaking, reliability

E

“Ebí ńpa mí” ò ṣéé fìfé wí.

Eegun tí a bá so mọ́ ajá lọ́rùn, kì í ṣán an.

Èké Ìbídùn, tí ńkí eégún “Kú àtijọ́.”

Èké lojú ó tì bó dọ̀la.

Èké mọ ilé-e rẹ̀ ó wó; ọ̀dàlẹ́ mọ tirẹ̀ ó bì dànù.

Elékèé lèké ńyè; oun a bá ṣe ní ńyéni.

Eléwe-é ní iyènú; àìní mọ ìwà-á hù.

Èlùbọ́ lo wáá rà; ọmọ ẹrán ṣe dénú igbá?

Èrò ò kí baálẹ̀, baálé ló ńkí.

Eṣinṣín ńjẹ Jagùnnà Àró ò gbọ́, Ọ̀dọ̀fin ò mọ̀; ṣùgbọ́n nígbàtí Jàgùnnà ńjẹ eṣinṣin Àró gbọ́, Ọ̀dọ̀fin-ín mọ̀. [13]

Etí, gbọ́ èkejì kí o tó dájọ́.

Etí tó gbọ́ àlọ ni yó gbọ̀ọ́ àbọ̀.

Ewúrẹ́ ní òun ò mọlé odì; ẹni òún bá ṣẹ̀ kó bi òun.

.
PreviousContentsNext