Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 5: On consistency; honesty, openness, plain speaking, reliability

B

Bí a bá ká okó mọ́ obìnrin nídìí á ní kùkú ni

Bí a bá ńyọ́lẹ̀ dà, ohun abẹ́nú a máa yọ́ni ṣe.

Bí abẹ́rẹ́ bí abẹ́rẹ́ lèèyàn ńṣèké; ọjọ́ tó bá tóbi tó ọkọ́ tí a fi ńroko ní ńpani.

Bí ẹnú bá jẹ, ojú á tì.

Bí ìgbín ńfà, ìkaraun a tẹ̀lé é.

Bí ìkà-á bá ńrojọ́, ìkà kọ́ ni yó dàá a.

Bí o finú ṣìkà tí o fòde ṣòótọ́, ọba séríkí á rín ọ rín ọ.

Bí o ní ọ̀pọ̀ oògùn, tí o ní èké, kò níí jẹ́; orí ẹní jẹ́ ó ju ewé lọ; ìpín jà ó ju oògùn lọ.

Bí o rí i, wà pé o ò rí; ọkọ́ fún ọ lówó, àlé gbà á ná.

Bí ó ti wù kó pẹ́ tó, olóòótọ́ ò níí sùn sípò ìkà.

Bí obìnrín bá máa dán èké wò, a da aṣọ dúdú bora.

Bí ojú bá sé ojú; kí ohùn má yẹ ohùn.

Bí olókùnrùn yó bàá kú, kó má purọ́ mọ́ àlapà; omitooro kì í korò.

Bí òru bí òru ní ńṣe aláṣọdúdú.

Bí ọgbọ́n bá tán nínú, a tún òmíràn dá.

Bí ọmọdé bá mọ igbá-di-ogóje, kò lè mọ èrò-kò-wájà.

Bí ọmọdé bá ri oyin, a ju àkàrà nù.

.
PreviousContentsNext