Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 5: On consistency; honesty, openness, plain speaking, reliability

A

A kì í pè é lẹ́rú, ká pè é lóbí.

A kì í pè é lẹ́rù ká pè é lọ́ṣọ̀ọ́.

A kì í rí ẹṣin ní ìso.

A kì í rí i ká tún sọ pé a ò ri mọ́.

A kì í ró aṣọ ajé sídìí ká dájọ́ òdodo lẹ́bi.

A kì í so ẹran mẹ́ran kó kàn án pa.

A kì í sọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ kó má diyàn ní gba-n-gba.

A kì í ṣe ẹlẹ́jọ́ ní “Ngbọ́?”

Àbàtá pani; àbàtá pani; ká ṣá sọ pé odò-ó gbéni lọ.

Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ńfọ́jú onídàájọ́.

Adánu tí ńjẹ ilá: ó ní “Ẹ ò rí ilẹ̀ báyìí?”

Àdàpè olè ní ńjẹ́ àfọwọ́rá.

Àdàpè olè ní ńjẹ́ “ọmọ-ọ̀ mi ńfẹ́wọ́.”

Àdàpè ọ̀rọ̀ ò jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ orúkọ.

Adẹ́tẹ̀ẹ́ sọ̀rọ̀ méjì, o fìkan purọ́; ó ní nígbàtí òún lu ọmọ òun lábàrá, òún ja léèékánná pàtì.

A-dọ́gbọ́n-pàgùntàn-jẹ Ìlárá, ó ní ojú ẹ̀ ḿba òun lẹ́rù.

Afasẹ́gbèjò ńtan ara-a rẹ̀ jẹ.

Afatarẹ́nilójú, alè-e baále.

Afẹ́nilóbìnrin ò ro ire síni.

Afìkọ̀kọ̀jalè, bí ọba ayé ò rí ọ, tọ̀rún rí ọ.

Afọ́jú àjànàkú, kò mọ igi, kò mọ èèyàn.

Àfọwọ́rá ní ńjẹ́ olè.

Agada ò morí alágbẹ̀dẹ.

Àgbàdo kì í ṣe èèyàn; ta ní ńrí ọmọ lẹ́hìn eèsún.

Àgbàká lodi ńgba ìlú.

Àgbàká nigbà ńgba ọ̀pẹ.

Àgbẹ̀ gbóko róṣù.

A-gbẹ́jọ́-ẹnìkan-dájọ́, òṣìkà èèyàn.

Àgbọ́ìgbọ́tán Ègùn, ìjà ní ńdá sílẹ̀.

Àì-fẹ́-àlejòó-ṣe là ńwí pé “Ọ̀rẹ́ ọ̀rẹ́-ẹ̀ mí dé”; ká ṣáà ti wí pé, “Ọ̀rẹ́-ẹ̀ mí dé.”

Àìfẹ̀sọ̀ké ìbòsí ni kò ṣéé gbè.

Ajá ní òun ìba má dèé oko rí òun ìbá sọ pé ọ̀run ni wọ́n ti ńkálá wá.

Ajá tí ò létí ò ṣéé dẹ̀gbẹ́.

Ajá ti erée rẹ̀ẹ́ bá dánilójú là ńdẹ sí ehoro.

Àjàlá, ta ní nà ọ́? Ìwọ náà kọ́ un?

Àjànàkú kúro ni “A rí ǹkan fìrí”; bí a bá rérin ká wí.

A-jí-má-jẹ-ǹkan, a-fàkàṣù-mẹ́fà-ṣoògùn-aràn.

Àjò àìwuniíyún là ńdÍfá sí.

A-kápò-má-ṣọdẹ, ọ̀tá ẹranko, ọ̀tá èèyàn.

Àkàsọ̀ faratilẹ̀ faratilé; bí ẹni tí a fẹ̀hìntì óò bá yẹni a wí fúnni.

Akíni ńjẹ́ akíni; afinihàn ńjẹ́ afinihàn; èwo ni “Ọ kú, ará Ìjàyè!” lójúde Ògúnmọ́lá?

Akọ asín kì í gbọ́ ohùn ọmọ-ọ rẹ̀ kó dúró; abiyamọ kì í gbọ́ ẹkún ọmọ-ọ rẹ̀ kó má tara ṣàṣà.

Alákatam̀pò ò mọ irú ẹran.

Alápatà ò mọ irú ẹran.

Amọ̀rànbini Ọ̀yọ́, bí o bá gbé kete lérí, wọn a ní oko lò ńlọ tàbí odò.

Apajájẹ-ẹ́ ní ẹ̀rù adìẹ ḿba òun.

Apani kì í jẹ́ ká mú idà kọjá nípàkọ́ òun.

Àpèjúwe lalágbẹ̀dẹ ńrọ̀.

Ará Ìbàdàn kì í ságun; à ó rìn sẹ́hìn ni wọ́n ńwí.

Arítẹnimọ̀ọ́wí, ó fi àpáàdì ràbàtà bo tirẹ̀ mọ́lẹ̀.

Àrókanlẹ̀ laṣọ ayaba; àwàkanlẹ̀ ni ti yàrà.

Arúgbó oǹdágbèsè, ó ní mélòó ni òun ó dùúró san níbẹ̀?

Asárélówó ḿbẹ lọ́nà ogun; Apọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ḿbẹ lọ́nà èrò; Bó-pẹ́-títí-ng-ó-là ḿbẹ lábà, ó ńjẹ ẹ̀sun iṣu.

Àsọ̀rọ̀àìlàdí ló pa Elempe ìṣáájú tó ní igbá wúwo ju àwo.

Àṣá ò gbádìẹ níkọ̀kọ̀; gbangba làṣá ńgbádìẹ.

Aṣeburúkú tẹsẹ̀ mọ́nà.

A-ṣọ̀tún-ṣòsì-má-ba-ibìkan-jẹ́; irọ́ la ó bàá níbẹ̀.

Àwárí lobìnrin ńwá nǹkan ọbẹ̀.

Àwíyé ní ḿmú ọ̀ràn yéni; ọ̀ọ́dúnrún okùn la fi ńsin ẹgbẹ̀ta; bí a ò bá là á, kì í yeni.

Àwíyé nIfẹ̀ ńfọ̀; gbangba lorò ńpẹran.

Àyè kì í há adìẹ kó má dèé ìdí àba-a rẹ̀.

.
ContentsNext