Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 4: On perseverance, industry, resilience, self-confidence, self-reliance, resourcefulness, daring, fortitude, and invulnerability

T

Tàkúté tí yó pa Aláginjù á pẹ́ lóko kí wọ́n tó gbé e wálé.

Tàpò-tàpò là ńyọ jìgá; tewé-tewé là ńyán ẹ̀kọ.

Tẹ̀tẹ̀ ẹ̀gún ti lómi tẹ́lẹ̀ kójò tó rọ̀ sí i.

Títa ríro là ńkọlà, bó bá jinná a di tẹni.

Tojú tìyẹ́ làparò-ó fi ńríran.

Tọ̀sán tòru, imú ò gbélẹ̀; bó ba dákẹ́, a jẹ́ pé ó pin.

.
PreviousContentsNext