Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 3: On cageyness, caution, moderation, patience, and prudenceGb
“Gbà sókè” ni “Gbà sọ́kọ̀”; ohun tá a bá sọ síwájú là ḿbá.
Gbéjò-gbéjò ò gbé ọká.
Gbẹ́ran-gbẹ́ran ò gbé ẹkùn.
Gbígbòòrò là ńṣe ọ̀nà igi.
Gbogbo ajá ní ńjẹ imí: èyí tó bá jẹ tiẹ̀ mẹ́nu laráyé ńpè ní dìgbòlugi.
Gbogbo ìjà nìjà; bóo gbémi lulẹ̀ mà mọ́ ẹ lójú lákọ lákọ.
Gbogbo obìnrin ló ńgbéṣẹ́, èyí tó bá ṣe tiẹ̀ láṣejù laráyé ńpè láṣẹ́wó.
Gbólóhùn kan Agán tó awo-ó ṣe.
Gbólóhùn kan-án ba ọ̀rọ̀ jẹ́; gbólóhùn kan-án tún ọ̀rọ̀ ṣe.
Gbólóhùn kan la bi elépo; elépo ńṣe ìrànrán.
|
|||||||