Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 3: On cageyness, caution, moderation, patience, and prudenceI
Ìbẹ̀rẹ̀ òṣì bí ọmọ ọlọ́rọ̀ là ńrí.
Ibi ìṣáná la ti ńkíyè sóògùn.
Ibi rere làkàsọ̀ńgbé sọlẹ̀.
Ibi tí a gbọ́n mọ là ńṣòwò-o màlúù mọ.
Ibi tí a ti ńwo olókùnrùn la ti ńwo ara ẹni.
Ibi tí à ńlọ là ńwò, a kì í wo ibi tí a ti ṣubú.
Ibi tí akátá ba sí, adìẹ ò gbọdọ̀ débẹ̀.
Ibi tí inú ḿbí asẹ́ tó, inú ò gbọdọ̀ bí ìkòkò débẹ̀; bínú bá bí ìkòkò débẹ̀, ẹlẹ́kọ ò ní-í rí dá.
Ibi tí ó mọ là ńpè lọ́mọ.
Ìbínú baba òṣì.
Ìbínú lọbá fi ńyọ idà; ìtìjù ló fi ḿbẹ́ ẹ.
Ìbínú ò da nǹkan; sùúrù baba ìwà; àgbà tó ní sùúrù ohun gbogbo ló ní.
Ìbínú ò mọ̀ pé olúwa òun ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀
Ìbìsẹ́hín àgbò kì í ṣojo.
Ìbọn-ọ́n ní apátí kò lápátí, taní jẹ́ jẹ́ ka kọjú ìbọn kọ òun?
Ì-dún-kídùn-ún òyo ni wọ́n fi ńsọ òyo nígi; ì-fọ̀-kúfọ̀ ògbìgbì ni wọ́n fi ńta ògbìgbì lókò; ì-jẹ-kújẹ àdán ní ńfi-í tẹnu pọ̀ fẹnu ṣu.
Ìfẹ́ àfẹ́jù lewúrẹ́ fi ḿbá ọko-ọ ẹ̀ hu irùngbọ̀n.
Ìfi ohun wé ohun, ìfi ọ̀ràn wé ọ̀ràn, kò jẹ́ kí ọ̀ràn ó tán.
Ìfunra loògùn àgbà.
Igi ganganran má gùnún mi lójú, òkèèrè la ti ńwò ó wá.
Igi tó bá bá Ṣàngó lérí, gbígbẹ ní ńgbẹ.
Igúnnugún gbọ́n sínú.
Ìgbà ara ḿbẹ lára là ḿbù ú tà.
Igbá dojúdé ò jọ ti òṣónú, tinú igbá nigbá ńṣe.
Ìgbà tí a bá ní kí Ègùn má jà ní ńyọ̀bẹ.
Ìgbà tí a bá perí àparò ní ńjáko.
Igbá tó fọ́ ní ńgba kasẹ létí; ìkòkò tó fọ́ ní ńgba okùn lọ́rùn.
Ìgbín ńràjò ó filé-e ẹ̀ ṣẹrù.
Ìgbín tó ńjẹ̀ ní màfọ̀n, tí ò kúrò ní màfọ̀n, ewé àfọ̀n ni wọn ó fi dì í dele.
Ìgbẹ̀hìn ní ńyé olókùúàdá.
Ìhàlẹ̀-ẹ́ ba ọ̀ṣọ́ èèyàn jẹ́.
Ìjẹǹjẹ àná dùn méhoro; ehoro-ó rebi ìjẹ àná kò dẹ̀hìn bọ̀.
Ìjímèrè tó lóun ò ní-í sá fájá, ojú ajá ni òì tí-ì to.
Ijó àjójù ní ńmú kí okó-o eégún yọ jáde.
Ìkánjú òun pẹ̀lẹ́, ọgbọọgba.
Ìkekere ńfọ̀rọ̀ ikú ṣẹ̀rín.
Ìkóeruku èèwọ̀ Ifẹ̀; ajá kì í gbó níbòji ẹkùn.
Ìkòkò ńseṣu ẹnìkan ò gbọ́; iṣú dénú odó ariwó ta.
Ìkókó ọmọ tó tọwọ́ bọ eérú ni yó mọ bó gbóná.
Ikú ńdẹ Dẹ̀dẹ̀, Dẹ̀dẹ̀ ńdẹ ikú.
Ikún ńjọ̀gẹ̀dẹ̀ ikún ńrèdí; ikún ò mọ̀ pé ohun tó dùn ní ńpani.
Ìlara àlàjù ní ḿmúni gbàjẹ́, ní ḿmúni ṣẹ́ṣó.
Ilé nÌjèṣà-á ti ńmúná lọ sóko.
Iná kì í wọ odò kó rójú ṣayé.
Iná ò ṣé-é bò máṣọ.
Ìnàkí kì í ránṣẹ́ ìjà sẹ́kùn.
Inú ẹni lorúkọ tí a ó sọ ọmọ ẹni ńgbé.
Inúure àníjù, ìfura atèébú ní ḿmù wá báni.
Ìpàkọ́ ò gbọ́ ṣùtì, ìpẹ̀hìndà ò mọ yẹ̀gẹ̀ yíyẹ̀.
Ìpàkọ́ là ńdà sẹ́hìn ká tó da yangan sẹ́nu.
Ìṣẹ́ kì í pani; ayọ̀ ní ńpani.
Ìtọ́jú ló yẹ abẹ́rẹ́.
Ìtọsẹ̀ ló nìlú.
Ìwà òní, ẹjọ́ ọ̀la.
Ìyá là bá bú; bí a bú baba ìjà ní ńdà.
Ìyàn-án mú, ìrẹ́ yó; ìyàn-án rọ̀, ìrẹ́ rù.
Ìyàwó la bá sùn; ọkọ ló lóyún.
Ìyàwó ò fọhùn, ó fọ́jú.
Ìyẹ̀wù kan ṣoṣo ò lè gba olókùnrùn méjì.
Isà tí ò lójú Alalantorí ńdẹ ẹ́, áḿbọńtorí àgbá ikún.
Isán ni à ḿmọ olè; ìtàdógún là ḿmọ dọ́kọ-dọ́kọ.
Iṣẹ́ tí a kò ránni, òun ìyà ló jọ ńrìn.
Itọ́ tí a tu sílẹ̀ kì í tún padà re ẹnu ẹni mọ́.
Iyán àmọ́dún bá ọbẹ̀.
|
|||||||