Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 1: On humility, self-control, self-knowledge, self-respect, and self-restraint

Edot

“Ẹ fà á wọlé” ló yẹ ẹlẹ́ṣin.

Ẹ jẹ́ ká mí, ẹ jẹ́ ká simi; èèyàn ní ńfìdí èèyàn jókòó; èèyàn ìbá ṣe bí Ọlọ́run kò níí jẹ́ ká mí.

“Ẹ kú-ulé” ò yẹ ará ilé; “Ẹ kú atìbà” ò yẹni tí ńtàjò bọ̀; ẹni tí ò kí ẹni, “Kú atìbà”-á pàdánù “Ẹ kú-ulé.”

Ẹ̀bìtì ẹnu ò tàsé.

Ẹgbẹ́ ẹni là ńgúnyán ewùrà dè.

Ẹ̀gbẹ̀rì ò mọ̀ pé arẹwà kì í gbé ẹ̀kú; gbogbo ehín kin-kìn-kin lábẹ́ aṣọ.

Ẹ̀gbọ́n ṣíwájú ó so aṣọ kọ́; àbúrò-ó kẹ́hìn ó wẹ̀wù; bí a ò mọ̀lẹ, ọ̀lẹ ò mọ araa rẹ̀?

Ẹlẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́ ńlọ ẹ̀ẹ́dẹ́, o ní “Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ni àbí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà?”; èwo lo gbé níbẹ̀?

Ẹlẹ́dẹ̀ ńpàfọ̀, ó rò pé òún ńṣoge.

Ẹlẹ́dẹ̀ ò mẹ̀yẹ.

Ẹlẹ́ẹ́fà kì í lọ ẹẹ́fàa rẹ̀ ká sọ pé o di ìjẹfà tí a ti jẹun.

Ẹni à bá fi sóko kó dàparò, ó ní òun ẹni ilé.

Ẹni à bá tà ká fowó-o rẹ̀ ra àdá: ó ní ìyà àdá ńjẹ òun.

Ẹni à bá tà ká fowó-o rẹ̀ ra àtùpà: ó ní òun à-jí-tanná-wò-lóru.

Ẹni à bá tà ká fowó-o rẹ̀ ra èbù: ó ní èlé òún kó ọ̀ọ́dúnrún.

Ẹni à ńgbé gẹ̀gẹ̀ ni yó ba ara-a rẹ̀ jẹ́.

Ẹní bá dẹ ojú-u rẹ̀ sílẹ̀ á rímú-u rẹ̀.

Ẹní dádé ti kúrò lọ́mọdé.

Ẹni tí a bá ńdáṣọ fún kì í ka èèwọ̀.

Ẹni tí a fẹ́ yàtọ̀ sí ẹni tó ní kò sí irú òun.

Ẹni tí a gbé gun ẹlẹ́dẹ̀, ìwọ̀n ni kó yọ̀ mọ; ẹni tó gẹṣin, ilẹ̀ ló ḿbọ̀.

Ẹni tí a lè gbé kì í dawọ́.

Ẹni tí à ńwò láwò-sunkún ńwo ara-a rẹ̀ láwò-rẹ́rìnín.

Ẹni tí a ò fẹ́, àlọ́ ò kàn án.

Ẹni tí a ò fẹ́ nílùú kì í jó lójú agbo.

Ẹni tí ìbá hùwà ipá ò hùwà ipá; ẹni tí ìbá hùwà ẹ̀lẹ̀ ò hu ẹ̀lẹ̀; ọ̀kùn tó nígba ọwọ́, tó nígba ẹsẹ̀ ńhùwà pẹ̀lẹ́.

Ẹni tí kò lè gbé eèrà, tí ńkùsà sí erin, títẹ́ ní ńtẹ́.

Ẹni tí kò rí ayé rí ní ńsọ pé kò sẹ́ni tó gbọ́n bí òun.

Ẹni tó tan ara-a rẹ̀ lòrìṣà òkè ńtàn: àpọń tí ò láya nílé, tó ní kí òrìṣà ó bùn un lọ́mọ.

Ẹni tí kò tó gèlètè kì í mí fìn-ìn.

Ẹni tó tijú tì í fún ara-a rẹ̀.

Ẹnìkan kì í jẹ́ “Àwá dé.”

Ẹran kí la ò jẹ rí? Ọ̀pọ̀lọ́ báni lábàtà ó ba búrúbúrú.

Ẹ̀rúkọ́ ńṣe bí ọkọ́.

Ẹ̀ṣọ́ kì í gba ọfà lẹ́hìn; iwájú gangan ní ńfi-í gba ọgbẹ́.

Ẹ̀wọ̀n tó tó ọ̀pẹ ò tó-ó dá erin dúró; ìtàkùn tó ní kí erin má ròkè ọ̀dàn, tòun terin ní ńlọ.

Ẹ̀yá ló bí mi, ẹkùn ló wò mí dàgbà, ológìnní gbà mí tọ́; bí kò sẹ́ran lọ́bẹ̀ nkò jẹ.

Ẹyẹ akòko-ó ní òún le gbẹ́ odó; ta ní jẹ́ fi odó akòko gúnyán jẹ?

Ẹyẹ ò lè rí omi inú àgbọn bù mu.

Ẹyẹ tó fi ara wé igún, ẹ̀hìn àdìrò ní ńsùn.

.
PreviousContentsNext