Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 1: On humility, self-control, self-knowledge, self-respect, and self-restraintE
Eégún ju eégún; òrìṣá ju òrìṣà; Pààká lé oníṣàngó wọ̀gbẹ́.
Eégún ò na obìnrin lágọ̀; obìnrín tú kíjìpá ìdí-i rẹ̀, ó fi na eégún.
Eégún pẹ́ lóde, ó fètè òkè dáhùn; wọ́n ní, “Baba kú àbọ̀,” ó ní, “Hì ìì.”
Eégún wọlé, ó ní òun ò rí Ejonto; Ejontó ní, “Àkísà ni, àbí kíní wọlé?”
Eegun àjànàkú: ó há ìkokò lẹ́nu.
Eegbọ́n so mọ́ àyìnrín lẹ́nu, a ní kí adìẹ wá yán an jẹ; adìẹ́ mọ̀ pé òun náà oúnjẹ àyìnrín.
Ejò kì í ti ojú Ààrẹ gun ọgbà lọ.
Èmí dákọ okòó, ìwọ́ dákọ okòó, ò ńpèmí ní mùkọ-mùkọ.
Èmi ìwọ̀fà, ìwọ ìwọ̀fà, o ní babá ní ká gbowó wá; o dá tìrẹ sílẹ̀ ná?
Epo ni mo rù; oníyangí má ba tèmi jẹ́.
Erin kì í fọn kọ́mọ-ọ rẹ̀ ó fọn.
Èrò ọ̀nà ni yó ròhìn ọkà tó gbó.
Èsúrú ṣe fújà ó tẹ́ lọ́wọ́ oníyán; aláǹgbá ṣe fújà ó tẹ́ lọ́wọ́ ògiri; Ọlámọnrín àjàpá ṣe fújà ó tẹ́ lọ́wọ́-ọ̀ mi.
Etí lobìnrín fi ńgbọ́ ohùn orò.
Èwo ló tó ẹ̀kọ-ọ́ gbà nínú ewé ìrúgbàá?
Èwo ni ti Síkírá nílùú Ìwó.
Ewújù tí yóò tú ọ̀pẹ: gbogbo ehín ẹ̀ ni yóò kán tán.
Ewúrẹ́ ò wí pé òun ò ṣọmọ àgùntàn; àgùntàn ló wí pé òun ò ṣọmọ ewúrẹ́.
Ewúrẹ́ kì í bíni ká lọ sísọ̀ àgùntàn lọ jẹ̀.
Èèyàn bí ọ̀bọ lọ̀bọ ńya láṣọ.
Èèyàn ò ríbi sùn, ajá ńhanrun.
Èèyàn tí ò nítìjú ojú kan ni ìbá ní; a gbórín a tó tẹṣin.
|
|||||||