Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 1: On humility, self-control, self-knowledge, self-respect, and self-restraintB
Babaaláwo kì í bèrè ẹbọ àná.
Bẹbẹlúbẹ ò ì tíì débẹ̀; ibẹ̀ ló ḿbọ̀.
Bí a bá dàgbà à yé ogun-ún jà.
Bí a bá fi inú wénú; iwọ là ńjẹ.
Bí a bá ḿbá ọmọdé jẹun lóko, gànmùganmu imú ẹni ní ńwò.
Bí a bá ńgúnyán, kòmẹsẹ̀ á yọ.
Bí a bá ti lè ṣe là ńwí; a kì í yan àna ẹni lódì.
Bí a bá ti mọ là ńdé; a-láì-lẹ́ṣin kì í dé wọ̀nwọ̀n.
Bí a bá ti mọ là ńkú; olongo kì í kú tìyàntìyàn.
Bí a bá tọ̀ sílé, onípò a mọ ipò.
Bí a bá wí pé ó dọwọ́-ọ babaláwo, babaláwo a ló dọwọ́ Ifá; bí a bá ní ó dọwọ́ àgbà ìṣègùn, àgbà ìṣègùn a ló dọwọ́ Ọ̀sanyìn; bí a bá ní ó dọwọ́ ààfáà tó gbójú, a ní ó dọwọ́ Ọlọ́run ọ̀gá ògo.
Bí a kò bá dáṣọ lé aṣọ, a kì í pe ọ̀kan lákìísà.
Bí a kò bá lè dá Tápà, Tápà kì í dáni.
Bí a kò bá lọ sóko irọ́, a kì í pa á mọ́ni.
Bí a kò bá ṣèké, a kì í fi ẹ̀tẹ́ kú.
Bí a kò bá tíì jókòó, a kì í nasẹ̀.
Bí a kò bá tíì lè kọ́lé, àgọ́ là ńpa.
Bí a kò bá tó baba ọmọọ́ ṣe, a kì í pe alákàrà.
Bí a kò bá tó ìyà-á kọ̀ tí à ńkọ̀ ọ́, àjẹkún ìyà là ńjẹ.
Bí a ó ti tó kì í jẹ́ ká hùwà búburú; bí a ó ti mọ kì í jẹ́ ká hùwà rere.
Bí àgbà kò bá ṣe ohun ẹ̀rù, ọmọdé kì í sá.
Bí àjànàkú ò bá rí ohun gbémì, kì í ṣe inú gbẹndu sọ́dẹ.
Bí ajá rójú ẹkùn, a pa rọ́rọ́.
Bí ayá bá mojú ọkọ, alárìnnà a yẹsẹ̀.
Bí ayé bá ńyẹni, ìwà ìbàjẹ́ là ńhù.
Bí baálẹ̀-ẹ́ bá ńtàkìtì, òrógi là ḿbá ẹmẹsẹ̀.
Bí èèyán bá ní kò sí irú òun, àwọn ọlọgbọ́n a máa wòye.
Bí eegbọ́n bá so mọ́ ajá lẹ́nu, akátá là ńní kó já a?
Bí eegbọ́n bá ṣo ayínrín nímú, adìẹ kọ́ ni yó ja.
Bí ẹkùn ò bá fẹ̀, èse là ńpè é.
Bí ẹlẹ́bọ ò bá pe ẹni, àṣefín ò yẹni.
Bí ìlàrí bá fẹ́ tẹ́, a ní kí lọba ó ṣe?
Bí iná bá dun ọbẹ̀, a dá ọ̀rọ̀ sọ.
Bí kò sí àkópọ̀, kí lewúrẹ́ wá dé ìsọ̀ adìẹ?
Bí kò sí tọ̀bùn èèyàn, ta ni ìbá jí lówùúrọ̀ tí kò bọ́jú ṣáṣá?
Bí mo bá torí oko kú ng ó rò fáhéré; bí mo bá torí ọ̀gẹ̀dẹ̀ kú ng ó rò fódò; bí mo bá torí alábàjà òkíkí kú, ng ó rò fórí-ì mi.
Bí ó di ọdún mẹ́ta tí ẹkùn-ún ti ńṣe òjòjò, olugbe la ó ha rán lọ bẹ̀ ẹ́ wò?
Bí òfé ti ńfò la ti ḿmọ̀ ọ́ lákọ ẹyẹ.
Bí òkú fẹ̀, bí kò fẹ̀, ká bi ọmọ olókùú léèrè.
Bí ojú bá rí, ẹnu a dákẹ́.
Bí ojú kò bá rí, ẹnu kì í sọ nǹkan.
Bí ojú kò bá ti olè, a ti ará ilé ẹ̀.
Bí ojú onílé bá mọ tíntín, tí ojú àlejòó tó gbòǹgbò, onílé ní ńṣe ọkọ àlejò.
Bí olóde ò kú, òdee rẹ̀ kì í hu gbẹ́gi.
Bí olóúnjẹẹ́ bá rojú à fi àìjẹ tẹ́ ẹ.
Bí ọdún bá dún, bọnnọnbọ́nnọ́n a pàwọ̀ dà.
Bí ọjàá bá tú tán, a ku olórí-i pàtẹpàtẹ, a ku àgbààgbà sà-ǹkò sà-ǹkò lọ́jà; bÍfá bá pẹ̀dí tán, ìwọ̀-ǹwọ̀ a dìde.
Bí ọjọ́ ewúrẹ́ bá pé, a ní kò sí ohun tí alápatàá lè fi òun ṣe.
Bí ọ̀lẹ́ ò lè jà, a lè kú tùẹ̀.
Bí Ọlọ́run ò ṣe ẹni ní baba, à fi ìyànjú ṣe bí àgbà.
Bí ọmọdé bá fẹ́ ṣìṣe àgbà, ọjọ́ orí-i rẹ̀ ò níí jẹ́.
Bí ọmọdé bá gun òkè àgbà, ó ńláti gbọ́n.
Bí ọmọdé bá ńṣe ọmọdé, àgbà a máa ṣe àgbà.
Bí ọmọdé ńlérí bébé, tí kò ní baba, ti baba là ńṣe.
Bí Ọya ńkọ lọ́run, bí Ṣàngó ńjó láyé, kò níí burú fún baba kó ní ó dọwọ́ ọmọ òun lọ́run.
|
|||||||