Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 1: On humility, self-control, self-knowledge, self-respect, and self-restraintA
A di gàárì sílẹ̀ ewúrẹ́ ńyọjú; ẹrù ìran rẹ̀ ni?
A fi ọ́ jọba ò ńṣàwúre o fẹ́ jẹ Ọlọ́run ni?
A fijó gba Awà; a fìjà gba Awà; bí a ò bá jó, bí a ò bá jà, bí a bá ti gba Awà, kò tán bí?
A gbé gàárì ọmọ ewurẹ ńrojú; kì í ṣe ẹrù àgùntàn.
A kì í bá ọba pàlà kí ọkọ́ ọba má ṣàn-ánni lẹ́sẹ̀.
A kì í bínú ààtàn ká dalẹ̀ sígbẹ̀ẹ́.
A kì í bínú orí ká fi fìlà dé ìbàdí.
A kì í bẹ̀rù ikú bẹ̀rù àrùn ká ní kí ọmọ ó kú sinni.
A kì í bọ òrìṣà lójú ọ̀fọ́n-ọ̀n; bó bá dalẹ́ a máa tú pẹpẹ.
A kì í dàgbà má làáyà; ibi ayé bá báni là ńjẹ ẹ́.
A kì í dá ọwọ́ lé ohun tí a ò lè gbé.
A kì í dájọ́ orò ká yẹ̀ ẹ́.
A kì í dákẹ́ ká ṣìwí; a kì í wò sùn-ùn ká dáràn.
A kì í dé Màrọ́kọ́ sin ẹlẹ́jọ́.
A kì í fi gbèsè sọ́rùn ṣọ̀ṣọ́.
A kì í fi ìka ro etí, ká fi ro imú, ká wá tún fi ta ehín.
A kì í fi orí wé oríi Mokúṣiré; bí Mokú kú láàárọ̀ a jí lálẹ́.
A kì í fi pàtàkì bẹ́ èlùbọ́; ẹní bá níṣu ló ḿbẹ́ ẹ.
A kì í fini joyè àwòdì ká má lè gbádìẹ.
A kì í gbé sàráà kọjá-a mọ́ṣáláṣí.
A kì í gbọ́ “Lù ú” lẹ́nu àgbà.
A kì í gbọ́n ju ẹni tí a máa dÍfá fún.
A kì í gbọ́n tó “Èmi-lóni-í.”
A kì í gbọ́n tó ẹni tí ńtannijẹ.
A kì í gbọ́n tó Báyìí-ni-ngó-ṣe-ǹkan-àn-mi.
A kì í jayé ọba ká ṣu sára.
A kì í jẹ oyè ẹnu ọ̀nà kalẹ́.
A kì í kó èlé ṣẹ̀ṣọ́.
A kì í kórira ọ̀fọ́n-ọ̀n ká finá bọ ahéré.
A kì í kọ́ àgbàlagbà pé bó bá rún kó rún.
A kì í kọ ẹlẹ́ṣin ká tún lọ fẹ́ ẹlẹ́sẹ̀.
A kì í lé èkúté ilé ẹni ká fọwọ́ ṣẹ́.
A kì í mọ́ egbò fúnra ẹni ká sunkún.
A kì í mọ ìyá Òjó ju Òjó lọ.
A kì í mọ ọ̀nà ọgbà ju ọlọ́gbà lọ; ẹní múni wá là ńtẹ̀lé.
A kì í mọ̀-ọ́ rò bí ẹlẹ́jọ́.
A kì í mú oko lọ́nà ká ṣèmẹ́lẹ́; tajá tẹran ní ḿbúni.
A kì í ní agbára kékeré ṣe èkejì.
A kì í ní ọ̀kánjúwà ká mọ̀; ará ilé ẹni ní ńsọ fúnni.
A kì í pe ìyàwó kó kan alárẹnà.
A kì í peni lákọ ẹran ká ṣorí bòró.
A kì í pẹ̀lú ọ̀bọ jáko.
A kì í ṣíwájú ẹlẹ́èẹ́dẹ́.
A kì í yàgò fún “Mo gun ẹṣin rí o!”
A kì í yàgò fún ẹlẹ́ṣin àná.
A léṣu sílẹ̀ páńdọ̀rọ̀-ọ́ já lù ú; èlé mbénì?
À ḿbáni mú adìẹ à ńforúnkún bó; bọ́wọ́ bá ba òkókó, a ò ní fún aládìẹ?
À ḿbẹ̀rù alájá, ajá ṣebí òun là ḿbẹ̀rù.
À ńgé e lọ́wọ́, ó ḿbọ òrùka.
A ní ká wá ẹni tó lẹ́hìn ká fọmọ fún, abuké ní òun rèé; ti gànnàkù ẹ̀hìn-in rẹ̀ là ńwí?
A ní Tanlúkú ò mọ̀-ọ́ jó, Tàǹlukú wá gbè é lẹ́sẹ̀.
À ńjá ìbàǹtẹ́ ẹ̀ lẹ́hìn, ó ńjá tará iwájú.
À ńsọ̀rọ̀ olè, aboyún ńdáhùń; odiidi èèyàn ló gbé pamọ́.
À ńsunkún Awúgbó, Awúgbó ò sunkún ara-a ẹ̀.
À ńwá ẹni tí a ó fọmọ fún, olòṣì ńyọjú.
À ńwọ́nà àti fi aṣiwèrè sílẹ̀, ó ní bí a bá dé òkè odò ká dúró de òun.
A ò lóbìnrin à ńdá oóyọ́ sí; bí a bá dá oóyọ́ sí ewúrẹ́ ni yó jẹ ẹ́.
A ò mọ ohun tí eléwé-e gbégbé ńtà kó tó sọ pé ọjà ò tà.
A ò mọ ohun tí Dárò-ó ní kó tó wí pé olè-é kó òun.
A pè ọ́ lọ́mọ erín-màgbọn ò ńyọ̀; ìwọ pàápàá ló mì í?
A rí èyí rí ni tonílé; a ò rí èyí rí ni tàlejò; bónílé bá ní ká jẹ ẹ́ tán, àlejò a ní ká jẹ ẹ́ kù.
A rígi lóko ká tó fi ọ̀mọ̀ gbẹ́ ìlù.
A sìnkú tán, alugbá ò lọ́ ó fẹ́ ṣúpó ni?
Àbá ni ikán ńdá; ikán ò lè mu òkúta.
A-báni-gbé kì í yáná; a-bọ̀rìṣà kì í sun òtútù; ẹyin gẹ́gẹ́ kì í gbé àwùjọ́; ilé kannáà ni wọ́n kọ́ fún àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.
A-bánijẹun-bí-aláìmọra, ó bu òkèlè bí ẹ̀gbọ́n ìyá ẹ̀.
A-bèèrè kì í ṣìnà.
À-bí-ì-kọ́; à-kọ́-ì-gbà; òde ló ti ńkọ́gbọ́n wálé.
A-binú-fùfù ní ńwá oúnjẹ fún a-binú-wẹ́rẹ́-wẹ́rẹ́.
Aboyún kì í jó bẹ̀m̀bẹ́; a-bodò-ikùn-kẹ̀rẹ̀bẹ̀tẹ̀.
Àbọ̀ ejò kì í gbé isà.
Abùlàǹgà kì í ṣasán; bíyàá ò lọ́rọ̀, baba a lówó lọ́wọ́.
Abùléra ọ̀fọ́n-ọ̀n; ó ní ọjọ́ tí ológbò-ó ti bí òun ò ìtí-ì dá a ní báríkà.
Àbúrò kì í pa ẹ̀gbọ́n nítàn.
Àbúrò rẹ ńdáṣọ fún ọ, o ní o ò lo elékuru; ta ní ńlo alákàrà?
A-dá-má-lè-ṣe àdàbà tí ńdún bẹ̀m̀bẹ̀.
Adìẹ funfun ò mọ ara ẹ̀ lágbà.
Adìẹ ò bí yọyọ kú yọ̀.
Adìẹ́ tó ṣu tí kò tọ̀, ara-a rẹ̀ ló kù sí.;
A-dìtan-mọ́ èsúó; ó ní èkùlù ló bí ìyá òun.
Adígbọ́nránkú ńfikú ṣeré.
Adẹ́tẹ̀ẹ́ ní òun ò lè fún wàrà, ṣùgbọ́n òún lè yí i dànù.
Adẹ́tẹ̀-ẹ́ rí wèrè, ó kán lùgbẹ́.
Adẹ́tẹ̀-ẹ́ sọ̀rọ̀ méjì, ọ́ fìkan purọ́; ó ní nígbàtí òún lu ọmọ òun lábàrá, òún já a léèékánná pàtì.
Adití ò gbọ́, “Yàgò!”
À-fà-tiiri ni tìyàwó; bí a bá fà á tí kò tiiri, ó ní ohun tó ńṣe é.
Àfi ohun tí a kì í tà lọ́jà lẹrú kì í jẹ.
Afínjúu Ààré; ó fi àkísà dí orùbà; ó ńwá ẹniire-é bá sú epo.
Afínjú ní ńjẹ iwọ; ọ̀mọ̀ràn ní ńjẹ obì; màrí-màjẹ ní ńjẹ awùsá.
Afínjú-u póńpólà, ogé kun osùn láìwẹ.
Afínjú wọ ọjà ó rìn gbẹndẹ́kẹ ọ̀bún wọ ọjà ó rìn ṣùẹ̀ṣùẹ̀; ọ̀bùn ní ó ru ẹrù afínjú relé.
Àfòpiná tó fẹ́ paná-a súyà: ẹrán pọ̀ sí i.
Àfòpiná tó ní òun ó pa fìtílà, ara ẹ̀ ni yó pa.
Afọ́jú tó dijú, tó ní òún sùn, ìgbàtí kò sùn ta ló rí?
A-fọ́nú-fọ́ra ní ńfi òṣì jó bàtá.
Àgó tó gbó ṣáṣá, ẹ̀bìtí pa á, áḿbọ̀sì olóósè a-bara-kùọ̀kùọ̀.
Àgùnbánirọ̀ ní ńfojúdini.
Àgbà ajá kì í bàwọ̀jẹ́.
Àgbà ìmàle kì í káṣọ kọ́rùn.
Àgbà kán ṣe bẹ́ẹ̀ lÓgùn; Yemaja ló gbé e lọ.
Àgbà kì í fàárọ̀ họ ìdí kó má kan funfun.
Àgbà kì í ṣerée kí-ló-bá-yìí-wá?
Àgbà kì í ṣorò bí èwe.
Àgbà kì í wà lọ́jà kórí ọmọ titun wọ́.
Àgbá òfìfo ní ńpariwo; àpò tó kún fówó kì í dún.
Àgbà tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ a lọ́gbọ́n nínú.
Àgbà tí kò mọ ìwọ̀n ara-a rẹ̀ lodò ńgbé lọ́.
Àgbà tí kò nítìjú, ojú kan ni ìbá ní; ojú kan náà a wà lọ́gangan iwájú-u rẹ̀.
Àgbà tí yó tẹ̀ẹ́, bó fárí tán, a ní ó ku járá ẹnu.
Àgbà tó bú ọmọdé fi èébú-u rẹ̀ tọrọ.
Àgbà tó fi ara-a rẹ̀ féwe lèwe ḿbú.
Àgbà tó mọ ìtìjú kì í folè ṣeré.
Àgbà tó torí ogójì wọ ìyẹ̀wù; igbawó ò tó ohun à-mú-ṣèyẹ.
À-gbàbọ̀-ọ ṣòkòtò, bí kò fúnni lẹ́sẹ̀ a ṣoni; rẹ́múrẹ́mú ni ohun ẹni ḿbani mu.
Àgbààgbà ìlú ò lè péjọ kí wọn ó jẹ ìfun òkété, àfi iyán àná.
Àgbà-ìyà tí ńmùkọ ọ̀níní, ó ní nítorí omi gbígbóná orí-i rẹ̀ ni.
Àgbàlagbà akàn tó kó sí garawa yègèdè, ojú tì í.
Àgbàlagbà kì í ṣe lágbalàgba.
Àgbàlagbà kì í wẹwọ́ tán kó ní òun ó jẹ si.
Àgbàlagbà kì í yọ ayọ̀-ọ kí-ló-báyìí-wá?
Àgbàlagbà tí ò kí Ààrẹ ńfi okùn sin ara-a rẹ̀.
Àgbàlagbà tó ńgun ọ̀pẹ, bó bá já lulẹ̀ ó dọ̀run.
Àgbàlagbà tó wẹ̀wù àṣejù, ẹ̀tẹ́ ni yó fi rí.
Àgbàrá ba ọ̀nà jẹ́, ó rò pé òún tún ọ̀nà ṣe.
Agbára wo ló wà lọ́wọ́ igbá tó fẹ́ fi gbọ́n omi òkun?
Àgbéré àwòdì ní ńní òun ó jẹ ìgbín.
Àgbéré laáyán gbé tó ní òun ó jòó láàárín adìẹ.
Àgbéré lẹyẹ ńgbé; kò lè mu omi inú àgbọn
Àgbéré-e ṣìgìdì tó ní ká gbé òun sójò; bí apá ti ńya nitan ńya; kidiri orí ò lè dá dúró.
Ahọ́n ni ìpínnlẹ̀ ẹnu.
Àì-jọnilójú lọ́sàn-án ní ḿmúni jarunpá luni lóru.
Àì-kúkú-joye, ó sàn ju, “Ẹnuù mi ò ká ìlú” lọ.
Àì-lápá làdá ò mú; bí a bá lápá, ọmọ owú to-o gégi.
Àì-lè-jà ni à ńsọ pé “Ojúde baba-à mi ò dé ìhín.”
Àì-mọ̀-kan, àì-mọ̀-kàn ní ḿmú èkúté-ilé pe ológbò níjà.
Àìsí èèyàn lóko là ḿbá ajá sọ̀rọ̀.
Àìsí-ńlé ẹkùn, ajá ńgbó.
Àìsí-ńlé ológbò, ilé dilé èkúté.
Àìso àbà ló mẹ́yẹ wá jẹ̀gbá; ẹyẹ kì í jẹ̀gbá.
Ajá kì í gbó níbojì ẹkùn.
Ajá kì í lọ ságinjù lọ ṣọdẹ ẹkùn.
Ajá kì í rorò kó ṣọ́ ojúlé méjì.
Ajá mọ ìgbẹ́; ẹlẹ́dẹ̀-ẹ́ mọ àfọ̀; tòlótòló mọ ẹni tí yó yìnbọn ìdí sí.
Ajá ò gbọdọ̀ dé mọ́ṣáláṣí ìkókò ṣàlùwàlá.
Ajá rí epo kò lá; ìyá-a rẹ̀ẹ́ ṣu ihá bí.?
Ajá tó ńlépa ẹkùn, ìyọnu ló ńwá.
Ajá tún padà sí èébì-i rẹ̀.
Àjàjà ṣoge àparò, abàyà kelú.
Àjànàkú ò tu lójú alájá; o-nígba-ajá ò gbọdọ̀ tọ́pa erin.
Àjàpá ní kò sí oun tó dà bí oun tí a mọ̀ ọ́ṣe; ó ní bí òún bá ju ẹyìn sẹ́nu, òun a tu èkùrọ́ sílẹ̀.
Àjàpá ní òun tí ìbá só ló sùn yí, bẹ́ẹ̀ni ẹní bá sùn kì í só.
Àjàpá ńlọ sájò, wọ́n ní ìgbà wo ni yó dèé, ó ní ó dìgbàtí òún bá tẹ́.
Àjátì àwọ̀n ní ńkọ́ òrofó lọ́gbọ́n.
À-jẹ-ì-kúrò ní ńpa ẹmọ́n; à-jẹ-ì-kúrò ní ńpa àfè; à-jẹ-ì-kúrò ní ńpa máláàjú.
À-jẹ-pọ̀ ni tàdán.
À-jẹ-tán, à-jẹ-ì-mọra, ká fi ọwọ́ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá jẹun ò yẹ ọmọ èèyàn.
À-jókòó-àì-dìde, à-sọ̀rọ̀-àì-gbèsì, ká sinni títí ká má padà sílé, àì-sunwọ̀n ní ńgbẹ̀hìn-in rẹ̀.
Aaka ò gbé ọ̀dàn; igbó ní ńgbé.
Àkàtàm̀pò ò tó ìjà-á jà; ta ní tó mú igi wá kò ó lójú?
Àkíìjẹ́ mú òrìṣà níyì.
Àkísà-á mọ ìwọ̀n ara-a rẹ̀, ó gbé párá jẹ́.
Àkókó inú igbó ní àwọ́n lè gbẹ́ odó; ọ̀pọ̀lọ́ lódòó ní àwọ́n lè lọ́ ìlẹ̀kẹ̀; awúrebé ní àwọ́n lè hun aṣọ.
Akórira ò ní ǹkan; ọ̀dùn ò sunwọ̀ fún ṣòkòtò.
Akú, nkò ní omitooro-o rẹ̀ ẹ́ lá; àìkú, nkò níí pè é rán níṣẹ́.
Àkùkọ̀ adìẹ́ fi dídájí ṣàgbà; ó fi ṣíṣu-sílẹ̀ ṣèwe.
Aládàá lo làṣẹ àro.
Aláìnítìjú lọ kú sílé àna-a rẹ̀.
Alákòró kì í sá fógun.
Aláǹgbá kì í lérí àti pa ejò.
Aláàńtètè: ó jí ní kùtùkùtù ó ní òun ó dàá yànpọ̀n-yànpọ̀n sílẹ̀.
Aláṣejù ajá ní ńlépa ẹkùn.
Aláṣejù, baba ojo.
Aláṣejù ní ńgbẹ́bọ kọjá ìdí èṣù; a-gbé-sàráà-kọjá-a-mọ́ṣáláṣí.
Aláṣejù, pẹ̀rẹ̀ ní ńtẹ́; àṣéjù, baba àṣetẹ́.
Aláṣejù tí ńpọkọ ní baba.
Aláṣọ àlà kì í jókòó sísọ̀ elépo.
Aláṣọ-kan kì í ná ànárẹ.
Aláṣọ-kan kì í ṣeré òjò.
Alátiṣe ní ḿmọ àtiṣe ara-a rẹ̀.
Àlejò kì í lọ kó mú onílé dání.
Àlejò kì í pìtàn ìlú fónílé.
Àlémú ò yẹ àgbà; àgbà kì í ṣe ohun àlémú.
A-lu-dùndún kì í dárin.
Àmọ̀tẹ́kùn-ún fara jọ ẹkùn, kò lè ṣe bí ẹkùn.
Amùrín ò sunwọ̀n, ó yí sáró.
Ànán-mánàán ẹtú jìnfìn; oní-mónìí ẹtú jìnfìn; ẹran mìíràn ò sí nígbó lẹ́hìn ẹtu?
Apá èkúté-ilé ò ká awùsá; kìkìi yíyíkiri ló mọ.
Àpárá ńlá, ìjà ní ńdà.
Àpárá ńlá ni iná ńdá; iná ò lè rí omi gbéṣe.
Àpárá ńlá nikán ńdá; ikán ò lè mu òkúta.
Àpọ́nlé ni “İyá-a Káà”; ìyá kan ò sí ní káà tí kò lórúkọ.
Àpọ́nlé ni “Fọ́maàn”; ẹnìkan ò lè ṣe èèyàn mẹ́rin.
Ara okó ní òún gbọ́ fínrín fínrín; ta ló sọ fun bí kò ṣe ará ile?
Ara-àìbalẹ̀, olórí àrùn.
À-rí-ì-gbọdọ̀-wí, baálé ilé ṣu sápẹ.
Àrí-ì-gbọdọ̀-wí, baálé ilé yọkun lémú.
Àrífín ilé ò jẹ́ ká jẹ òròmọ adìẹ.
Arọ̀lẹ̀kẹ̀ ò rọ bàtà; gbẹ́dó-gbẹ́dó ò rọ ojúgun.
Àṣá kì í rà kádìẹ gbé kòkòrò dání.
A-ṣe-bọ̀rọ̀kìnní-má-kìíyè-sábíyá, gbogbo abíyá dọ́ṣẹ.
Àṣejù baba àṣetẹ́; ẹ̀tẹ́ ní ńgbẹ̀hìn àṣejù; àgbàlagbà tó wẹ̀wù àṣejù ẹ̀tẹ́ ni yó fi rí.
À-sẹ́-kú làgbàlagbà ńsẹ́ ọ̀ràn.
Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ màrìwò, ó ní òun ó kan ọ̀run; àwọn aṣáájúu rẹ̀-ẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ rí?
Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ọ̀gọmọ̀ ó ní òun ó kan ọ̀run; àwọn aṣáájú ẹ̀-ẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ rí?
Aṣiwèrè èèyàn ní ńsọ pé irú òun ò sí; irúu rẹ̀-ẹ́ pọ̀ ó ju ẹgbàágbèje lọ.
Aṣọ à-fọ̀-fún ò jẹ́ ká mọ olówó.
Aṣọ tó kuni kù ní ńjẹ́ gọgọwú.
A-ṣúra-mú ò tẹ́ bọ̀rọ̀.
À-tẹ́-ẹ̀-ká ni iyì ọlọ́lá; sálúbàtà ni iyì ọlọ̀tọ̀; bá a bá gbéra lágbèéjù ọba ni wọ́n ńfini íṣe
À-wín-ná-wó ò yẹni; à-gbà-bọ̀-ọ ṣòkòtò ò yẹ ọmọ èèyàn; bí kò fúnni lẹ́sẹ̀ a dòrògí; ohun ẹni ní ńyẹni.
Àwòrò tí a ò bá lù kì í luni.
A-wọ̀lú-má-tẹ̀ẹ́, ìwọ̀n ara-a rẹ̀ ló mọ̀.
Àwúrèbeé ní òún lè yẹ̀nà; ta ní jẹ́ tọ ọ̀nà àwúrèbe?
Àáyá yó níjọ́ kan, ó ní ká ká òun léhín ọ̀kánkán.
Aáyán ati eèràá ṣígun, wọ́n ní àwọ́n ńlọ mú adìẹ àlọ la rí, a ò rábọ̀.
Aáyán fẹ gẹṣin; adìẹ ni ò gbà fún un.
Aáyán fẹ́ jó; adìẹ ni ò jẹ́.
Aáyán kì í yán ẹsẹ̀ erin; èèyàn kì í yán ẹsẹ̀ irò.
Ayọ̀ àyọ̀jù làkèré fi ńṣẹ́ nítan.
Àyọ̀-yó ni bàtá à-jó-fẹ-ehín.
|
|||||||