![]() |
|||||||
Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 6: On consideration, kindness, and thoughtfulnessEdot
Ẹ ní ká má tafà; kí ni a ó fi lé ogun? Kànnà-kànnà la fi lé Boko.
Ẹní fowó lògbà ló káyé já.
Ẹní lówó kó ṣe bí ọba; àrà wo lahún fẹ́ fi owó dá?
Ẹní mọ owó-ó lò lowó ḿbá gbé.
Ẹni tí ó bá máa bímọ á yọ̀ fọ́lọ́mọ.
Ẹni tí ó gòkè, kó fa ọ̀rẹ́-ẹ rẹ̀ lọ́wọ́; ẹni tó rí jẹ, kó fún ọ̀rẹ́-ẹ rẹ̀ jẹ.
Ẹni tí ó bèèrè ọ̀rọ̀ ló fẹ́ ìdí-i rẹ̀ ẹ́gbọ́.
Ẹni tí a ṣe lóore tí kò dúpẹ́, bí ọlọ́ṣà-á kóni lẹ́rù ni.
Ẹni tí ó so ìlẹ̀kẹ̀-ẹ́ parí ọ̀ṣọ́; ẹni tó fúnni lọ́mọ-ọ́ parí oore.
Ẹni tí ó ṣe ìbàjẹ́ èèyàn-án ṣe ìbàjẹ́ ara-a rẹ̀.
Ẹyẹlé fi ẹ̀sín-in rẹ̀ pamọ́, ó ńṣe ẹ̀sín adìẹ.
|
|||||||
![]() |