![]() |
|||||||
Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 6: On consideration, kindness, and thoughtfulnessI
Ìbàjẹ́ iṣu nìbàjẹ́ ọ̀bẹ; ẹni tó ṣe ìbàjẹ́ èèyàn-án ṣe ìbàjẹ́ ara ẹ̀.
Igbá olóore kì í fọ́; àwo olóore kì í fàya; towó tọmọ ní ńya ilé olóore.
Igbá onípẹ̀lẹ́ kì í fọ́; àwo onípẹ̀lẹ́ kì í fàya.
Ilé olóore kì í wó tán; tìkà kì í wó kù.
Ilé ọ̀ṣọnú àyàyó; ta ní jẹ́ yalé ahun-káhun?
Inú búburú, oògùn òṣì.
Inúure kì í pani, wàhálà ní ńkó báni.
“Iyán dára, ọbẹ̀-ẹ́ dùn” ló pa Akíndélé lóko Ìgbájọ; “Òrìṣà, nkò fún ọ ní èdì jẹ” ló pa abọrìṣà Ìkirè.
Ìyàwó jẹ ọkà jẹ igbá.
|
|||||||
![]() |