Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 5: On consistency; honesty, openness, plain speaking, reliability

K

Kí a baà lè pẹ́ níbẹ̀, abuké ní bí òún bá kú, kí wọ́n ti ẹ̀hìn tú ìfun òun.

Kí á gà, kí á gò, èdè ni ò yédè.

Kí á rí ká rà, ká rà ká má san; à-rà-àì-san èkejìolè.

Kí olówó wá, kí aláwìn wá; à-rà-àì-san ni ò sunwọ̀n.

“Kò dùn mí, kò dùn mí”; àgbàlagbà ḿbú ọpa lẹ́ẹ̀mẹfà nítorí iyán àná.

Kò jọ agbe kò jọ olè tí ńsúfèé yàgbàdo; bí kò bá bá mi a di olè; bó bá bá mi a di onílé.

Kò sí ohun tí a ò lè fi òru ṣe; ẹ̀rù ọ̀sán là ḿbà.

Kò ṣeku kò ṣẹyẹ ò jẹ́ kí àjàò sanwó òde.

.
PreviousContentsNext