Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 5: On consistency; honesty, openness, plain speaking, reliabilityI
Ìbáà tínrín, okùn òtítọ́ kì í já; bí irọ́ tó ìrókò, wíwó ní ńwó.
Ibi tí a ti na ọmọ ọba là ḿbèrè, a kì í bèrè ibi tí ọmọ ọbá ti pọ́n lẹ́gbẹ̀ẹ́.
Igbó kannáà lọdẹ ńdẹ.
Ìjòkó là ḿbá eèbà.
Ìkòkò kì í ṣelé ìgbín; ṣe ló dè ìgbín mọ́lẹ̀.
Ilé ahun ò gba ahun; ọ̀dẹ̀dẹ̀ ahun ò gbàlejò; ahún kọ́lé ẹ̀ tán ó yọ ọ̀dẹ̀dẹ̀ níbàdí.
Ìlú tí a bá rè là ḿbá pé.
Ìmàlé gbààwẹ̀ ó lóun ò gbétọ́ mì; ta ní ńṣe ẹlẹ́rìí fún un?
Ìmàlé sọ̀rọ̀ òjò-ó kù, ó ní Ọlọ́runún jẹ́rì-í òun.
Ìmùlẹ̀ ò gbọdọ̀ tan ara wọn jẹ; ìmọ̀ ẹnìkan ò yàn.
Ìpẹ́pẹ́rẹ́ ìgò méje; bí kò bá pé méje ara kì í gbà á.
Ìrókò tó bá gbàbọ̀dè, bíbẹ́ ni.
Irọ́ ni “Má jẹ̀ẹ́nìkan ó gbọ́”; òótọ́ ni “Ẹni o rí o bi.”
|
|||||||