Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 5: On consistency; honesty, openness, plain speaking, reliability

W

“Wá jẹun.” “Ng ò jẹ.” Ó fọgọ́rùnún òkèlè tọ́ ọbẹ̀ wò.
“Come join me at my meal.” “Thank you, but no.” Still he eats a hundred mouthfuls, just to taste the stew.
(If you intend to decline an invitation, match your action to your words.)

Wọ́n ní,; “Àwòko, o bú ọba.” Ó ní ìgbà wo lòún ráàye bú ọba, kóun tó kọ igba lówùúrọ̀, igba lọ́sàn-án, igba lálẹ́, kóun tó fi àyìndà-yindà lù ú?
They said, “Mocking bird, you are accused of insulting the king.” It asked when would it have time to insult the king, seeing that it must sing two hundred songs in the morning, two hundred in the afternoon, and two hundred at night, mixing it all up with some frolicsome notes?
(The person in trouble will resort to ludicrous alibis to escape punishment.)
Compare Wọ́n ní àparò aṣọ ẹẹ́ ṣe pọ́n báyìí?

Wọ́n ní kárúgbó gba ọmọ pọ̀n, ó ní ṣe bí wọ́n mọ̀ pé òun ò léhín; wọ́n ní kó pa ọmọ jẹ ni?
The old woman is asked to carry a child on her back, and she says but they know she has no teeth; was she asked to eat the child.
(Said of people whose comment on a proposition is wildly irrelevant.)

.
PreviousContents