Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 4: On perseverance, industry, resilience, self-confidence, self-reliance, resourcefulness, daring, fortitude, and invulnerability

W

Wàhálà ló bí ìrọra; òṣì ló bí wàhálà.

Wèrè èèyàn ní ńru ẹrù wòran; ẹní ru ẹrù wòran ni wèrè èèyàn ńwò.

Wèrèpè ò níbìkan àgbámú; gbogbo ara ní ńfi-í jóni.

Wíwẹ̀ là ńwẹ̀ ká tó jàre ọyẹ́.

Wọ́n ní, “Àparò aṣọ ẹẹ́ ṣe pọ́n báyìí?” Ó ní ìgbà wo laṣọ òun ò níí pọ́n? Kóun tó kọ igba láàárọ̀, kóun tó họ ilẹ̀ kùrẹ̀-kùrẹ̀ lábùsùndájí. Ìgbà wo lòun ó ràáàyè fọṣọ?

.
PreviousContents